Wo awọn ọmọ Naijiria 157 ti ijọba Amẹrika fẹẹ da pada sile lori ẹsun iwa ọdaran

Diẹ lara awọn ti wọn n pada si Naijiria lati Amẹrika
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn alakoso ilẹ Amẹrika ti fọwọ osi juwe ile fun awọn ọmọ Naijiria metadinlaadọjọ lori oniruuru ẹsun iwa odaran.

Ṣaaju ni ileeṣẹ Department of Homeland Security nilẹ Amẹrika ti kọkọ fi orukọ awọn metalelaadoje sita wi pe wọn yoo pada si orileede ti wọn ti wa.

Awọn ohun to nii ṣe pelu iwa jibiti owo, gbigbe owo rin lọn aitọ, gbigbe egboogi oloro, ilọnilọwọgba, ati iwa ipa si ọmọde ni wọn fi kan gbogbo awọn eeyan naa.

Oju opo ayelujara ni US DHS gbe orukọ awọn eeyan naa ti wọn fẹẹ da pada sile wọn si, fun gbogbo eeyan lati mọ.

Ẹka ICE lo rọwọ to gbogbo awọn eeyan naa, lasiko iwadii ti wọn ṣe lati gbogun ti iwa ọdaran nilẹ Amẹrika, ti wọn si fi wọn ni abala to buru julọ loju opo wọn.

US DHS fi orukọ wọn, ilu ti wọn ti wa, ati awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, to nii ṣe pẹlu jibiti ori meeli, jibiti ori ayelujara, lilo orukọ olorukọ, yiyi iwe, fifi iya jẹni ati lilo ohun ija oloro fun iwa ọdaran, soju opo ayelujara pẹlu.

Awọn wo lọwọ tẹ

Lara awọn tọwọ tẹ naa ni Emmanuel Omowaiye, ti wọn mu ni Richmond, Texas,lori ẹsun jibiti ori meeli; Laurene Onwuka, ti wọn mu ni Chantilly, Virginia, lori ẹsun lilo orukọ ẹlomiran fun jibiti; ati Olusegun Shonekan, ti wọn mu ni Newark, New Jersey, lori ẹsun jbiiti ori ayelujara.

Awọn miran ni Olusegun Olaseni ti wọn mu ni Greencastle, Indiana, lori tita egboogi oloro amphetamine; Peter Ude, tọwọ tẹ ni Atlanta, Georgia, lori jibiti ori ayelujara; ati Newton Jemide, tọwọ tẹ ni Fort Dix, New Jersey, lori ẹsun jibiti ori ayelujara, igbimọ papọ ati jibiti ori ayelujara.

Lara awọn to tun wa lori akọsilẹ naa ni: Shedrack Umukoro tọwọ tẹ ni Yazoo City, Mississippi; Olasoji Akinbode tọwọ tẹ ni Kearny, New Jersey; ati Oluwatosin Afolabi tọwọ tẹ oun naa ni Conroe, Texas.

DHS sọ pe igbesẹ naa wa lara iṣejọba Aarẹ Donald Trump lati mu gbogbo awọn oniṣẹ jibiti ati iwa ọdaran kuro nilẹ Amẹrika.

Atẹjade ti wọn fi sita sọ pe, "Ileeṣẹ U.S. Department of Homeland Security n ṣe ojuṣe rẹ lati yọ awọn oniwa ọdaran to buru kuro nilẹ Amẹrika.

"Oju opo yii tọka si awọn oniwa ọdaran lati orileede miran tọwọ ileṣẹ aṣọbode tẹ, ti wọn si ti mu kuro lori ẹsun oniruuru iwa ọdaran bii gbigbe egboogi oloro, lilo ohun ija oloro, iwa ipa bii ifipabanilopọ ati ipaniyan, jibiti ati lilo ohun ini ijọba lọna aitọ."