Émi àti ìkejí mi máa ń dáwọ́jọ lu ẹni tó bá fìyà jẹ wa- Taiwo àti Kehinde Afolabi
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin ati obinrin ni awon ibeji Taiwo ati Kehinde Afolabi ti wọn pe ẹni aadọrin ọdun (70) laye laipẹ yii, sibẹ, iṣesi wọn jọra pupọ, bẹẹ ni ifẹ to wa laaarin wọn lati igba ewe ko yingin titi di asiko yii.
Ninu ifọrọwerọ ti awọn ibeji naa ṣe pẹlu BBC News Yorubani wọn ti ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko jọ gbe pupọ nigba kekere, sibẹ, awọn jọ ka kilaasi papọ ri, awọn si maa n gbeja ara wọn bi ẹnikẹni ba fiya jẹ eyikeyi ninu awọn mejeeji.
Ninu alaye naa ni mama agba, Taiwo Afolabi ti sọ pe ounjẹ toun ba gbe lọ sile ẹkọ nigba naa ki i ṣe ohun ti oun nikan yoo jẹ.
O ni bi Kehinde ba jẹ ounjẹ tiẹ tan, yoo tun wa ba oun lati gba lọwọ oun.
Mama naa sọ pe oun yoo fun un lounjẹ naa, Kehinde yoo si tun lọ fun awọn ọrẹ rẹ jẹ.
To ba wa di pe ẹnikan fẹẹ ba oun ja, tabi to ba dena de oun lọna, Kehinde naa yoo da si i, awọn yoo si jọ koju ẹni naa.
Tayelolu sọ pe eyi ko sabaa waye ṣaa, nitori awọn tete pinya, nigba ti iku ojiji mu baba awọn lọ ninu oko niluu Owo, ipinlẹ Ondo ti wọn fi ori awon sọlẹ si.
Emi ni mo buru ju nigba ta a wa ni kekere- Pa Kehinde Afolabi

Nipa iru eeyan ti kaluku wọn jẹ, ati pe ta lo buru ju ninu wọn, Alagba Kehinde Afolabi lo dahun pe oun loun buru ju nigba tawọn n dagba, amọ, baba naa ni oun ti yi pada bayii.
O ni ti eeyan ba ti n dagba, eeyan maa n yọ ogun ja ni.
''Emi ati ekeji mi kii ja nigba ti a wa ni kekere, koda, kilaasi kan naa ni a jọ wa.
"Ọdun 1978 ni Taye mi ṣe igbeyawo, o si bimọ lọdun 1979.
"Inu mi ko dun si igbeyawo rẹ tori o da bi ẹni pe wọn gba iyawo mi ni. Mo maa n beere lọwọ awọn ti wọn maa n sọ pe Tayelolu lagba, pe ṣe ọjọ kan naa kọ ni wọn bi awa mejeeji ni?''
Ọgbẹni Afolabi lo sọ bẹẹ.
Nigba to n fesi si eyi, Taiwo sọ pe nigbakugba ti Taye oun ba sọ pe oun lagba loun maa n sọ fun un pe oun loun kọkọ de ile aye.
"Iku baba wa pin wa niya, o mu ka lọ kọṣẹ nigba to yẹ ka wa nile ẹkọ"
End of podcast promotion
Nipa ohun ti oju wọn ri nigba ti wọn n dagba, awọn ibeji naa ṣalaye pe iku baba awọn da nnkan ru pupọ, o si mu kawọn kuro niluu Owo nipinle Ondo lọ si ipinlẹ Eko.
Arabinrin Taiwo sọ fun BBC News Yoruba pe: "Ilakọja wa ki i ṣe kekere, nitori ọdun 1970 ni baba wa ku.
"Iku yajo yajo ni baba wa ku, o si ba wa lojiji, ọrẹ lo yinbọn pa wọn ninu oko."
Kehinde naa kin ọrọ yii lẹyin pe:
"Iku baba wa lo jẹ ki emi ati ikeji mi di ẹni ti ko le lọ sile ẹkọ mọ, awa mejeeji lọ kọ iṣẹ, koda,ọjọ kan naa ni a gba iyọnda lẹnu iṣẹ."
"Iṣẹ aranṣọ ni emi kọ nigba ti Kehinde mi kọ iṣẹ fọto yiya.''
Mama Tayelolu lo sọ bẹẹ, bẹẹ ni Pa Kehinde Afolabi naa ṣọ pe iṣẹ fọto yiya toun kọ ki i ṣe nnkan toun fẹran, bi ko ṣe pe iku baba lo fa a.
O fi kun un pe oun ko pada fi iṣẹ naa jẹun, oun gba ọna iṣẹ mi-in, nnkan si pada ri bo ṣe yẹ ko ri titi dasiko yii.
Aanu Ọlọrun ni awon mejeeji sọ pe awọn ri gba lati di ẹni aadọrin ọdun laye, wọn ni awọn n foju sọna fun itẹsiwaju oore ọfẹ naa ninu alaafia ara.

























