Ademola Adeleke tú ìgbìmọ̀ ìjọba rẹ̀ ká, fi àwọn mẹ́ta sílẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ lọ

Oríṣun àwòrán, Ademola Adelek
Ṣaaju iburawọle rẹ fun saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Osun, gomina Ademola Adeleke ti tu igbimọ iṣejọba rẹ ka.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa, Adeleke ranti irinajorẹ lori oye lati ọdun 2023 titi di asiko yii, o ni fun odidi ọdun mẹrin loun atawọn eeyan naa ti n ṣiṣẹ ti wọn si ti ṣe ọpọ aṣeyọri lori oye.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi lede, o ni lọpọ igba lawọn ti fi ara awọn jin lọna ati sin araalu.
Adeleke sọ pe ijọba oun ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri ni ẹka eto ẹkọ, eto ilera, ere idaraya, awọn ohun amayedẹrun, imọ sayẹnsi, ayipada oju ọjọ, atawọn nnkan mii.
Koda, o ni ijọba naa gba ọpọ ami ẹyẹ lori awọn aṣẹyọri naa.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ igbimọ ọhun fun ifọwọsowọpọ wọn fun ilọsiwaju ipinlẹ Osun.
Awọn ọmọ igbimọ naa si dupẹ lọwọ rẹ fun anfani to fun wọn lati sin ipinlẹ naa.
Awọn ọmọ igbimọ ti Adeleke ko da duro

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Wayi o, kii ṣe gbogbo awọn to n ba a ṣiṣẹ ilu lo ni ki wọn maa lọ, Adeleke ṣi fi awọn mii silẹ lati maa ba iṣẹ wọn lọ.
Lara awọn ti ko ni ki wọn maa lọ ni akọwe ijọba, Teslim Igbalaiye, olori oṣiṣẹ ijọba, Kazeem Akinteye ati agbẹnusọ rẹ, Olawale Racheed.
Adeleke sọ pe oniruru iṣoro ni igbimọ naa koju ni saa akọkọ amọ awọn bori rẹ.
Ikede isinimi lẹnu iṣẹ fawọn oṣiṣẹ
Ẹwẹ, ijọba ti kede isinmi lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ lọla ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu, Kọkanla, ọdun 2026 yii.
Ijọba ni eredi isinmi naa ko ṣẹyin ki awọn araalu le ba a ṣajọyọ iburawọle saa keji gomina Adeleke.
Ikede isinmi naa lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle fi lede, ti olori gbogbo oṣiṣẹ ipinlẹ naa, Ayanleye Aina buwọlu niluu Osogbo.
Lẹyin naa lo dari gbogbo oṣiṣẹ ijọba ki wọn tẹle aṣẹ naa lati sinmi fun iburawọle ọhun.
O ni ki gbogbo ọọfisi ijọba ati gbogbo ile ẹkọ wa ni titi pa ki awọn oṣiṣẹ le ri aye ati ṣajọyọ naa.
Adeleke kede eto iṣuna ₦927bn fun ọdun 2027

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Ṣaaju iburawọle rẹ fun saa keji, Adeleke ti gbe eto iṣuna ₦927.37 biliọnu siwaju ile igbimọ aṣofi ipinlẹ naa fun ọdun 2027.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, Adeleke sọ pe eto iṣuna ọhun ni wọn yoo na lori awọn ohun idagbasoke fun ipinlẹ Osun.
O ni ijọba oun yoo na owo ọhun lori awọn ohun amayedẹrun, eto ọgbin, eto aabo, igbayegbadun awọn oṣiṣe ati ipese iṣẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, eto iṣina naa lo wa ni ilana isọdọtun ipinlẹ Osun, iyẹn Osun State Development Plans (2023–2050), ti afojusun rẹ jẹ mimu ọrọ aje ipinlẹ naa gboro si ni gbogbo ẹka.
Adeleke ni ₦400.93b lawọn n reti lati ọwọ ijọba apapọ nigba ti ipinlẹ naa yoo pa ₦250.17b wọle labẹle.
O ni ₦559.31b ni wọn yoo na fun awọn idagbasoke laarin ilu.
Gomina naa dupẹ lọwọ ile igbimọ aṣofi ipinlẹ naa fun atilẹyin wọn fun ijọba oun ni gbogbo igba.

























