Ẹ gba àlàáfíà láàyè, máà fún ẹbí olóògbé kọ̀ọ̀kan ní mílíọ̀nù méjì Náírà - Gómìnà Bago ti Niger

Oríṣun àwòrán, Mohammed Umaru Bago/Facebook
Ijọba ipinlẹ Niger ti sọ pe awọn ti bẹrẹ isẹ iwadii lati mọ bi ikọlu kan ti waye agbegbe Ba'are, ijọba ibilẹ Borgu, nibi ti eeyan ti ko din ni mẹrinlelaadọrin ti ku ṣe waye.
Nibi ikọlu naa ni wọn ti pa Baale abule naa, Malam Bawa Muhammad, to fi mọ iyawo atawọn ọmọ rẹ meta.
Awọn ẹṣọ aabo ibilẹ ti a mọ si fijilante ati awọn Fulani darandaran la gbọ pe wọn koju ija sira wọn lopin ọsẹ to kọja.
Yatọ si wi pe wọn pa Baalẹ Muhammad atawọn ẹbi re, awọn eeyan naa tun dana sun aafin rẹ, leyi to mu kawọn ti ori ko yọ sa asala fun ẹmi ara wọn.
Gomina Bago sọrọ
Lasiko abẹwo to ṣe lọ si aafin Emir ilu Borgu, Alaaji Halilu Sani Dantoro, Gomina Mohammed Umaru Bago menuba iṣẹlẹ naa, to si ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.
Bago ba awọn mọlẹbi Baalẹ naa, awọn ara abule, to fi mọ awọn ololufẹ rẹ.
Gomina jẹ ko di mimọ pe kete ti wọn ti fi iroyin naa to oun leti, loun ti paṣẹ pe ki awọn eleto aabo bẹrẹ iṣẹ iwadii.
O wa rọ awọn araalu lati gba alaafia laaye, ki wọn si jẹ ki ọrọ ara wọn ye ara wọn.
Bago wa ṣeleri lati fun mọlẹbi oloogbe kọọkan ni miliọnu meji Naira, iyen gbogbo mọlẹbi awọn mẹrinlelaadọrin naa.
Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ pe ijọba yoo fun awọn mọlebi naa ni ounje, ohun elo ile kikọ lati ran awọn ti dana sun ile wọn lọwọ.
Nigba to n sọrọ, Emir Borgu, Muhammad Haliru -Dantoro fi imọriri rẹ han si abẹwo gomina naa, to si je ko di mimọ pe asiko to dara ni gomina wa.



























