Kílódé tó fi jẹ́ àwọn arúgbó ló ń darí Naijiria nígbà tó jẹ́ ọ̀dọ́ ló pọ̀ jú?

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Mansur Abubakar
- Reporting from, Abuja
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Iru eeyan bii Abdulhadi Dalhatu, to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogoji ṣọwọn ninu oṣelu Naijiria.
O wa lara awọn to n du ipo adari lorilẹeede ti ida 80% wọn jẹ ẹni ti ko tii pe ni ogoji ọdun.
O gbagbọ pe ọjọ ori oun yoo fun oun lanfani bo ṣe n dije du ipo nile igbimọ aṣofin ipinlẹ rẹ, Kano.
Nigba to n ba BBC sọrọ, o ni "Awọn ọdọ lo pọ ju awọn arugbo lọ lorilẹede yii, awọn lo si yẹ ko maa sọ bi ọjọ iwaju wọn yoo ṣe ri.
Lati igba ti Naijiria ti pada si ijọba awarawa lọdun 1999, Goodluck Jonathan ni Aarẹ to kere julọ lọjọ ori lẹni ọdun mẹtelelaadọta.
Ẹni ọdun 74 ni Bola Tinubu to wa nipo Aarẹ lọwọ yii, yoo si pe ẹni ọdun 79 nigba ti yoo fi pari saa keji ti wọn ba yan an sipo lọdun to n bọ.
Awọn to n gbena woju rẹ ninu ibo naa ni agbalagba mii, Atiku Abubakar to n du ipo Aarẹ fun igba keje, to jẹ ẹni 79 ati Peter Obi to jẹ ẹni ọdun 65.
Ninu gbogbo awọn mejidinlogun to n du ipo Aarẹ ọdun 2027, ẹnikan ṣoṣo lo wa labẹ ogoji ọdun ninu wọn, iyẹn Moses Olusoji Adebisi, to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ninu ẹgbẹ oṣelu Democratic Leadership Alliance (DLA).
Bo tilẹ jẹ pe ọdọkunrin naa ni o da oun loju pe oun yoo bori, iwọnba eeyan kereje lo mọ ọ, bẹẹ ni ko si tii ṣe ọpọ ipolongo.
Ni eto idibo to kọja, ọpọ eeyan lo ṣatilẹyin fun Peter Obi lori ayelujara ti wọn si n pe ara wọn ni "Obedients".
Pupọ awọn ti wọn n tẹle Obi lọdun naa lọhun ni wọn jẹ ọdọ, to si ṣeleri fun wọn pe ayipada yoo de ba igbeaye wọn ninu ijọba oun.
Amọ pupọ ninu awọn alatilẹyin rẹ naa ni ọkan wọn bajẹ lẹyin to lulẹ ninu eto idibo ọhun.
Obedient nigba kan ri, Nonso Chukwudi sọ fun BBC pe "A ni ireti nigba naa, amọ esi ibo to jade kii ṣe ohun ti a n reti, eyii to mu ki ọpọ sọ ireti nu."
Ọpọ eeyan lo wa lẹyin awọn Obedient naa lẹyin iwọde EndSARS to milẹ titi lọdun 2020, eyii ti ọpọ ọdọ fọwọ ti wọn si gbagbọ pe yoo yọri si ijijagbara Naijiria lọwọ awọn alagbara.
Iwọde EndSARS ati bi awọn Obidient ṣe milẹ titi n tumọ si pe awọn ọdọ le gba Naijiria lọwọ awọn alagbara ti wọn ba ṣetan.

Oríṣun àwòrán, Abdulhadi Dalhatu
Amọ o ṣoro fun wọn lati lo okun kan naa fun ayipada oṣelu.
Hajara Musa, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn wa ninu awọn ti wọn ti sọ ireti ninu oṣelu Naijiria.
Musa ni oun ko ni ipinnu lati forukọ silẹ tabi dibo lọdun to n bọ.
Ọrọ Musa yii ti n Farahan ninu iye awọn to n dibo.
Bo tilẹ jẹ pe iye awọn to n forukọsilẹ lati dibo n pọ, iye ọdọ to n kopa ninu eto idibo n dikun si ni.
Ida 29% ni awọn ọdọ ni wọn forukọsilẹ lati dibo, eyii to jẹ adinku 40% si ti ọdun 2023.
Ajọ INEC ni oun n sa ipa oun lati rọ awọn ọdọ ki wọn lọ forukọ silẹ.
Dalhatu sọ pe awọn ọdọ to n kọ lati kopa ko ṣẹyin pe wọn ko gbagbọ pe ayipada yoo wa.
O ni "O pe wọn ki wọn maa sọrọ loju opo ayelujara ju ki wọn lọ dibo lọ."
Fun awọn ti wọn nifẹ si a ti du ipo, iṣoro to n koju wọn ni ọrọ owo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ala Dalhatu ni lati di Aarẹ Naijiria lọjọ kan, amọ o ni oun ko ṣe ipolongo nitori obitibiti owo ti oun nilo
Owo gọbọi ni eeyan nilo lati du ipo oṣelu ni Naijiria.
Labẹ ofin eto idibo Naijiria, ẹni to n du ipo Aarẹ le na owo ti iye rẹ to biliọnu marun un naira lọdun 2023, amọ wọn le na ilọpo meji rẹ bayii.
Ọpọ ọmọ Naijiria ni ko tilẹ le ra fọọmu oludije ninu ẹgbẹ oṣelu paapaa.
Ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP nikan lo ti n tukọ Naijiria lati ọdun 1999 ti oloṣelu ti gbajọba.
Awọn to si kun inu ẹgbẹ naa lawọn ti wọn ti ṣe oṣelu fun ọpọ ọdun ti wọn si ti lọrọ ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Fatima Zahra Umar, toun naa ti fẹ du ipo aṣojuṣofin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ri naa gba bẹẹ.
O ni "Ọpọ awọn ọdọ Naijiria ko rọwọ họri, owo gọbọi si ni eeyan nilo lati ṣe oṣleu ni Naijiria."
Amọ onimọ nipa oṣelu, Seun Ajayi sọ pe ọrọ naa ju ọrọ owo lọ.
Ninu ọrọ Seun, o ni ọlọpọlọ pipe ni awọn ọdọ Naijiria amọ pupọ ninu wọn ni ko nifẹ si eto oṣelu rara tabi ti ipo kekere ti wọn ba fun wọn maa n tẹ wọn lọrun.
Seun sọ pe "Awọn arugbo yẹn ko ni joko tẹtẹrẹ ki a yẹ aga nidi wọn, a ni lati ja fun awọn ipo naa ni."
O wa rọ awọn ọdọ ki wọn bi awọn adari wọn leere boya wọn ti mu awọn ileri ti wọn ṣe fun lẹyin ti wọn de ipo tan ṣẹ.
O ni ijọba kii ṣe ohun ti eeyan yoo joko si ẹgbẹ kan lati maa wo ohun to n lọ, amọ wọn gbọdọ bọ sori papa funra wọn lati kopa ninu rẹ.
























