Ta a ni yóò gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2025 láàrin Senegal ati Morocco bí CAS ṣe ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lónìí?

Igbimọ to n pẹtu si aawọ lẹka ere idaraya, Court of Arbitration for Sport (CAS) yoo gbe ipinnu rẹ kalẹ lonii lori boya wọn yoo kede orilẹede Senegal pe oun lo gba ife ẹyẹ AFCON tọdun 2025 tabi bẹẹ kọ.
Bakan naa ni wọn yoo kede boya orilẹede Morocco, to ni ami mẹta nibi asekagba ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Senegal lo jawe olubori, ti ife ẹyẹ naa si tọ si gẹgẹ bi ajọ elere idaraya nilẹ Afirika, CAF, se kede rẹ tẹlẹ.
Idajọ toni ni yoo si fopin si awuyewuye to n waye laarin awọn ikọ elere idaraya fun ọpọlọpọ osu lori ta lo yẹ ko gba ife ẹyẹ AFCON tọdun 2025 laarin Morocco ati Senegal.
Igbimọ apẹtusaawọ CAS lagbo ere idaraya naa si salaye pe oun ti kan si orilẹede Senegal ati Morocco ti wọn n se awuyewuye naa, pe oni yii ni wọn yoo mọ ibi ti igi ọrọ naa yoo wo si.
Ajọ naa wa se ikilọ lori iwa gbọyi sọyi tabi pinpin iroyin eke kiri nipa agbekalẹ idajọ naa, to si ni idajọ to ba wa lati oju opo ajọ CAS nikan ni ojulowo iroyin ati otitọ.
Ki lo ti waye sẹyin?

Oríṣun àwòrán, AFP/VIA GETTY
Igbẹjọ naa bẹrẹ nigba ti awuyewuye su yọ lori asekagba ifẹsẹwọnsẹ ere idaraya AFCON tọdun 2025 to waye ni papa isere idaraya Ọmọọba Moulay Abdellah nilu Rabat nilẹ Morroco lọjọ kẹjidinlogun osu kinni ọdun 2026.
Orilẹede Senegal si lo kọkọ fi ẹyin ilẹ Morocco to n gbalejo idije naa janlẹ pẹlu ami ayo kan si odo lasiko afikun akoko ere bọọlu naa.
Amọ wahala bẹrẹ lasiko ti adari ere bọọlu naa fun ikọ agbabọọlu Morocco ni anfaani lati gba pẹnariti tori agbeyẹwo aworan ohun to waye lori papa lẹyin to fagile ami ayo kan ti ikọ agbabọọlu Senegal gba wọle.
Eyi lo mu ki olukọni lere bọọlu fun ilẹ Senegal, Pape Thiawfa ibinu yọ, to si pasẹ fawọn agbabọọlu rẹ lati kuro lori papa ti wọn ti n gba asekagba idije AFCON 2025 naalọna ati fi ibinu wọn han si ihuwasi adari ayo ọhun.
Eyi si lo mu kawn agbabọọlu ilẹ Senegal fi papa ere bọọlu naa silẹ fun isẹju mẹrinla, ki wọn to wa pada sori papa lati tẹsiwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Amọ se ni Brahim Diaz tii se agbabọọlu fun ilẹ Morocco padanu pẹnarity naa, ti orilẹede Senegal si jawe olubori nibi idije naa lati ipasẹ afikun akoko eyi to mu fun Pape Gueye laaye.
Igbimọ to n fiyajẹni labẹ ajọ CAF kede ijiya to yẹ fun ikọ agbabọọlu Senegal ati Morocco
Amọ ajọ to n se kokari ere bọọlu nilẹ Morocco gbe ẹsun lọ siwaju ajọ elere bọọlu nilẹ Afirika ati ni agbaye, CAF ati FIFA, to si n fapa janu pe bi ikọ agbabọọlu Senegal se kuro lori papa ti wọn ti n gba bọọlu naa lo dabaru bi ifẹsẹwọnsẹ naa se yẹ ko lọ.
Igbimọ to n diyajẹni labẹ ajọ CAF kọkọ gba pe ki abajade asekagba idije AFCON naa w abo se wa, to si kede ijiya to yẹ fun ikọ agbabọọlu Senegal ati Morocco lori awọn isẹlẹ to waye lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa to jẹ asekagba idije ọhun.
Amọ inu ilẹ Morocco ko dun rara si igbesẹ naa, eyi si lo mu ko kọwe ẹsun nipa isẹlẹ ọhun.
Lọjọ Kẹtadinlogun osu kẹta, igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun labẹ ajọ CAF, fara mọ awọn ẹsun tilẹ Morocco mẹnuba, to si yi idajọ ti igbimọ adiyajẹni kọkọ gbe kalẹ.
O wa kede pe ikọ agbabọọlu Senegal ti padanu lati tẹsiwaju ninu kikopa nibi ifẹsẹwọnsẹ asekagba idije naa tori bo se tapa si ofin to de ere bọọlu AFCON ori kejilelọgọrin ati ikẹrinlelọgọrin.
Ibujoko ajọ CAF nilu Lausanne, nilẹ Switzerland, ni wọn ti gbọ ẹjọ naa lọjọ kẹjọ osu kẹwa ọdun 2026
End of podcast promotion
Idi si ree ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun naa se fun ikọ agbabọọlu Senegal ni ami ayo mẹta, to si fun Senegal ni odo eyi to mu ki ilẹ Morocco jẹ ikọ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ AFCON 2025 naa.
Ikede yii lo bi ariwisi lorisirisi jakejado ilẹ Afirika, tilẹ Senegal si se apejuwe idajọ naa bii eyi to fi sibikan, to si ki oun ko fara mọ idajọ naa rara.
Lẹyin naa ni Senegal wa kede pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun niwaju ajọ CAF lori idajọ naa.
Ọjọ Kẹẹdọgbọn osu kẹta si ni Senegal gbe ẹsun rẹ siwaju ajọ CAF, to si n fẹ ko yi idajọ ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ naa, ko si kede pe oun lo lo moke ninu ididje AFCON naa pẹlu ami ayo kan si odo.
Ibujoko ajọ CAF nilu Lausanne, nilẹ Switzerland, ni wọn ti gbọ ẹjọ naa lọjọ kẹjọ osu kẹwa nibi tawọn asoju lati inu ajọ CAF pẹlu ilẹ Senegal ati Morocco peju si, ti wọn s iwi awijare wọn nibi ipade bonkẹlẹ naa.
Bi o tilẹ jẹ pe ajọ to n gbọ ẹhonu ninu ajọ CAF ni wọn yoo gbe idajọ kalẹ lẹyin ọjọ diẹ amọ o kede nigba to ya pe oun yoo gbe ipinnu kalẹ losu kọkanla ọdun yii.
Idajọ ti yoo waye loni naa si ni yoo sọ boya idajọ ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun labẹ ajọ CAF gbe kalẹ, eyi to n kede Morocco bii ẹni to jawe olubori tọna abi bẹẹ kọ.
Idajọ naa si ni yoo fopin si awuyewuye to tii buru julọ ti yoo waye ri ninu itan ife ẹyẹ Afirika.


























