Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Fountain of Life láàárọ̀ òní rèé

Isin ọjọ Isinmi ti waye nile ijọsin Fountain of Life, Ilupeju, niluu Eko lẹyin ti awọn adari ijọ naa yọ olori rẹ to jẹ ọmo oludasilẹ, pasitọ Jimmy Odukoya bbi jiga.
Ṣaaju aago mẹjọ aarọ oni lawọn ọmọ ijọ naa ti bẹrẹ si n wọle si gbagede ile ijọsin lati bẹrẹ isin.
Nigba ti yoo fi di aago mẹsan an aarọ, ile ijosin naa ti kun fọfọ fun ọpọ ero ti ijosin si bẹrẹ pẹlu adura ati orin ọpe.

Akọroyin wa to lọ sibẹ jabọ pe pasitọ Jimmy Odukoya ti wọn yọ nipo naa wa ninu ile ijọsin ọhun to si ji joko si aye rẹ gẹgẹ bii bi ipo adari to wa.
Niwaju ita, wamuwamu lawọn agbofinro duro digbi lati pese aabo to peye fun awọn olujọsin.
Biṣọọbu Mike Okonkwo lo waasu nibi isin ọhun to jẹ isin idupẹ.

Nigba to n sọrọ, Okonkwo sọ pe ko si ẹni to le ya oun ati ijọ naa ati pe isa oku kankan ko ni bori ijọ naa lailai.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹmi mimọ lo pa oun laṣẹ lati wa bunkun awọn ọmọ ijọ naa lo mu ki oun wa laarọ ọjọ Isinmi.
Kí ni ilé-ẹjọ̀ sọ ṣaaju?
Nigba to n gbe aṣẹ naa kalẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, Onidajọ O.O Adewunmi-Oshin sọ pe ki Jimmy Odukoya dẹkun lati maa pe ara rẹ ni pasitọ agba ijọ naa.
Ati pe, ki Odukoya dẹkun lati maa da si gbogbo ohun to n lọ ninu ijọ ọhun, to fi mọ igbesẹ awọn alakoso.
Awọn alakoso naa lọ sile ẹjọ lati fopin si gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ijọ ọhun lori ọrọ olori.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn igbimọ alakoso kede pe Jimmy kii ṣe pasitọ agba ijọ naa mọ, ti wọn si tọka si fidio ti oludasilẹ tẹlẹ, Pasitọ Taiwo Odukoya ṣe.
Ninu fidio naa ni Pasito Taiwo Odukoya ti kede pe Pasitọ Kunle Areogun ni ko gba ipo oun, lẹyin toun ba ti ku tan.
Kete ti awọn alakoso kede eyi, ni wọn tun ti jẹ ko di mimọ pe Pasitọ Rotimi Okpaise ni yoo jẹ adele pasitọ agba ijọ naa, titi digba ti gbogbo eto yoo fi pari.
























