Wo gbogbo ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ètò ìbúra sípò gomina Ademola Adeleke nipinlẹ Osun

Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, o wọ agbada alawọ aro pẹlu fila alawọ kan naa. O n rẹrin-in bẹẹ lo fi ika ọwọ rẹ meji sibi oju rẹ osi, o fi ilẹkẹ meji si ọrun ọwọ rẹ osi.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ètò ìbúra wọlé fún Gómìnà Ademola Adeleke fún sáà kejì yóò wáyé lónìí, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, osù Kọkànlá ọdún 2026

Lẹyin to jawe olubori ninu idibo sipo gomina ipinlẹ Osun ninu eto idibo to waye lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2026 ni wọn yoo ṣeto ibura wọle fun saa keji fun Gomina Ademola Adeleke, niluu Osogbo, ipinlẹ Osun.

Ori papa iṣere to wa ni agbegbe Ọmọ West, niluu Osogbo ni eto iburawọle naa yoo ti waye.

Koda, ‎Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shetima, ti de si ipinlẹ Osun bayii fun ayẹyẹ ibura wọle naa.

‎Diẹ ninu irin-ajo Gomina Ademola Adeleke sinu oṣelu

Gomina Ademola Adeleke n sọrọ lọwọ ninu aworan yii, o mu ẹrọ gbohun-gbohun dani. Aṣọ alawọ aro lo wọ, o si de fila ẹgbẹ Accord ti wọn kọ imọlẹ si, awọ ofeefe ni fila naa.

‎Ọdun 2017 ni Ọmọọba Ademola Adeleke kọkọ gbegba ibo ninu oṣelu, iyẹn nigba to dije fun ipo Sẹnetọ loṣu Keje ọdun 2017, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, o si yege.

‎Eleyi ko ṣẹyin iku ti Isiaka Adetunji Adeleke to jẹ ẹgbọn fun Gomina Ademola Adeleke ku nigba naa. Bo tilẹ jẹ pe inu ẹgbẹ oṣelu APC ni Isiaka Adetunji Adeleke ti du ipo Sẹnetọ lakoko igba naa ki ọlọjọ too de.

‎Gomina Adeleke lo osu diẹ ni ile ìgbìmọ̀ asofin agba ni ilu Abuja gẹgẹ bi Sẹnetọ to n ṣoju Iwọ-Oorun Osun ( Osun West), ko too wa dije du ipo gomina ni ipinlẹ Osun ni 2018.

‎‎Eto idibo si ipo gomina ni 2018 naa kun fun orisirisi ipenija, eyi to mu ki Adeleke tawọn eeyan mọ si Sẹnetọ Onijo, fidi rẹmi ninu ibo naa.

‎Ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori lọdun naa lọhun-un, ibo naa lo gbe gomina ana; Gboyega Oyetola wọle nipinlẹ naa bii gomina kẹsan-an nipinlẹ Osun.

‎‎Ṣugbọn Adeleke ko jẹ ki aarẹ mu oun lati ma dije mọ, o tun du ipo gomina ni 2022, o si pada yege ninu ẹgbẹ oṣelu PDP to ti dije.

Wọn bura wọle fun un gẹgẹ bii gomina Osun ni saa akọkọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, osu Kọkanla ọdun 2022, oun si ni Gomina Kẹwaa nipinlẹ Osun.

Gomina Ademola Adeleke n ba ijọba rẹ lọ l'Osun ni saa naa, amọ rogbodiyan wa ninu ẹgbẹ PDP to gbe e depo.

Nigba to ya lo kuro ninu PDP latari wahala ẹgbẹ, o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord.

Rogbodiyan tun bẹrẹ si i ṣẹlẹ l'Osun latari ibo to n bọ ati ẹgbẹ Accord ti gomina wọ. Ipaniyan pọ kaakiri Osun,ipaya ati ibẹrubojo si gba gbogbo ilu naa ṣaaju idibo.

‎Amọ pẹlu gbogbo ẹ naa, Ademola Adeleke tun jawe olubori ninu ibo gomina to waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.

‎Abajade ijawe olubori naa ni wọn yoo fi bura fun Ademola Nurudeen Jackson Adeleke lonii, fun saa ọdun mẹrin miran titi di 2031.