Iyabo Ojo ń bọ àwọn ọba alayé lọ́wọ́ lóde àríyá, Ọba kan kọ̀ láti bọ ọwọ́, ariwo bá sọ lórí ayélujára

Iyabo Ojo n bọ oriade kan lọwọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awuyewuye kan ti n waye lori ayelujara eyi to kan agbega asa ilẹ Yoruba ati ohun ti gbajumọ osere tiata, Iyabo Ojo se.

Isẹlẹ naa lo waye nibi ayẹyẹ ọdun kẹwa igbeyawo amuludun kan, Mummy Glee ati ati ọkọ rẹ, Mr Still, nibi ti ọpọ awọn gbajumọ peju si, to fi mọ Iyabo Ojo, tii se ilumọọka osere tiata.

Fidio kan lo jade sori ayelujara eyi to se afihan Iyabo Ojo to duro siwaju tabili tawọn oriade ti wọn pe sibi ayẹyẹ naa wa.

Fidio naa si se afihan gbajumọ osere tiata naa to n bọ ọba alaye meji lọwọ amọ ti ọkan ninu awọn ọba alaye naa, Olu ti Orile Kemta, Ọba Adetokunbo Tejuosho si kọ lati bọ ọ lọwọ.

Eyi si lo mu ki Iyabo Ojo kuro niwaju ọba alaye naa, lọ bọ ọba miran to joko si ẹgbẹ ọba Tejuosho lọwọ.

Fidio naa lo di awuyewuye lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si n bu ẹnu atẹ lu Iyabo Ojo pe bo bọwọ fun awn oriade nitori o yẹ ko kunlẹ fun wọn gẹgẹ bii ọmọ Yoruba atata ni.

"Mo tọrọ aforijin pupọ to ba jẹ pe mo sẹ, n ko ni lọkan lati se afojudi rara si oriade tabi ori itẹ wọn"

Amọ gbajumọ osere tiata naa, Iyabo Ojo ti wa bọ soju opo ayelujara Instagram rẹ, lati salaye bi ọrọ fidio naa se jẹ.

Ninu ọrọ to sọ soju opo naa, Iyabo oun ti n ri ọpọ ikunsinu to n lọ lori ayelujara nipa oun, ti oun si fẹ se atunse si awọn nkankan kan.

"Ni akọkọ, n ko tiẹ mọ pe Ọba ni ẹni to joko naa. Ọba Oloto jẹ ẹnikan t imo mọ daadaa tori o jẹ bii arakunrin mi, a si dijọ maa n bọ ọwọ lọpọ igba ti a ba fẹ kir awa ni.

Jẹjẹ ni mo joko mi, nigba ti ẹnikan tọ mi wa pe awọn kan n ki mi lori tabili naa, nigba t imo si wo ibẹ, mo ri Ọba Oloto, mo si dide lati lọ ki wọn.

Mo ki gbogbo wọn bii ẹni pe ọrẹ ni wọn, n ko si mọ pe onitọhun naa jẹ Ọba.

Mo tọrọ aforijin pupọ to ba jẹ pe mo sẹ, n ko ni lọkan lati se afojudi rara si oriade tabi ori itẹ wọn, amọ lati akoko yii lọ, maa maa mọ iwọn ara mi."

Iyabo Ojo wa salaye pe asa ki oun maa bọ awọn eeyan lọwọ tabi di mọ wọn lara ti mọ oun lara pupọ, ti oun si n tiraka lati maa din lilo asa yii ku.

O wa seleri pe oun yoo din iwa ki oun maa bọ awọn eeyan ku tori ojoojumọ ni eeyan maa n kọ ọgbọn si.

Ọrọ ti Iyabo Ojo sọ nipa isẹlẹ to waye

Ta ni Iyabo Ojo?