Bàbá mi yọ sí mi lojú àlá pé ń kò gbọdọ̀ fi ipò Pásítọ̀ àgbà fún ìjọ Fountain of Life sílẹ̀ - Jimmy Odukoya

Oríṣun àwòrán, Pastor Taiwo Odukoya fountain of life church
Awuyewuye to n lọ lọwọ lori ayelujara laarin Pasitọ Jimmy Odukoya ati igbimọ majẹkobajẹ ninu ijọ Fountain of Life to wa nilu Eko, ko tii jẹrodo, lọ ree mu omi.
Bi o tilẹ jẹ pe igbimọ majẹkobajẹ ijọ naa ti fi fidio sita nipa bi oludasilẹ ijọ naa to ti di oloogbe, tii tun se baba Jimmy, Pasitọ Taiwo Odukoya se kede ẹni ti yoo maa dari ijọ naa lẹyin ti oun ba papoda.
Amọ Pasitọ Jimmy Odukoya ti salaye bi fidio naa se jẹ ati idi ti oun ko se ni kuro lori ipo Pasitọ agba fun ijọ Fountain of Life.
Olusọagutan naa kede eyi lana Ọjọru lasiko to n bawọn osisẹ ijọ naa, ti wọn to irinwo sọrọ, to si salaye awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin, eyi to mu ko di Pasitọ agba fun ijọ naa.
Bakan naa lo tun salaye bi ọrọ fidio naa se waye eyi to ni ki wọn fa akoso ijọ naa le Pasitọ Kunle Areogun lọwọ lẹyin iku oludasilẹ.
"Emi ni mo ka fidio to n sọ nipa ẹni ti yoo rọpo baba mi bii adari ijọ silẹ, asise ti mo se ni pe mo saigbọran lati pa fidio naa rẹ lẹyin isẹ́ abẹ baba mi"
Pasitọ Odukoya salaye pe oun ti n ba awọn alagbara ijọ naa jagun fun igba diẹ amọ oun kan dakẹ lai sọrọ ni tori oun ro pe wọn le yanju edeaiyede aarin wọn nitubi n nubi.
Amọ o ni niwọn igba tawọn igibmọ majẹobajẹ ijọ naa ti pinnu lati kan sawọn akọrinyin, ti wọn sig be fidio le wọn lọwọ nipa ipinnu baba oun lori ẹni ti yoo maa dir nijọ naa lẹyin rẹ, o di dandan fun oun naa lati bawọn osisẹ ijọ sọrọ, ki oun si fi otitọ ọrọ han.
Gẹgẹ bi Jimmy Odukoya ti wi, ọdun 2021 ni wọn se akasilẹ fidio to wa lori ayelujara naa nigba ti baba oun fẹ lọ sisẹ abẹ nilẹ AMẹrika.
O ni baba oun lero pe o seese ki oun ba isẹ abẹ naa lọ, lo se ka fidio silẹ nipa ẹni ti yoo gba ipo rẹ.
"Nigba naa lo ni ki n ka fidio naa silẹ, emi ni mo ka fidio naa silẹ, koda, ẹgbọn baba mi, Alagba John Odukoya gan mọ nipa akasilẹ fidio naa."
Amọ o fikun pe "isẹ abẹ naa yọri sir ere, ti baba mi si ni ki n pa fidio naa rẹ nitori ko wulo mọ amọ dipo ki n pa rẹ, se ni mo tọju rẹ pamọ."
Jimmy Odukoya ni asise nla gbaa ni oun se pẹlu bi oun ko se gba fidio naa rẹ, amọ ẹtahoro awọn eeyan lo ni anfaani si fidio naa, to fi mọ awọn arabinrin oun, to si fẹsun kan wọn pe awọn lo ju fidio naa sori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Jimmy Odukoya/Instagram
"Oju mi ti ri ọpọ isoro lori pe mo di Pasitọ agba, Bisọọbu Mike Okonkwo ati baba Adeboye ti da si aawọ yii, koda emi ati awọn ọmọ iya mi ti kẹyin sira wa"
Nigba to n salaye siwaju si lori isẹlẹ naa, Pasitọ agba ijọ Fountain of Life naa ni ede aiyede yii bẹrẹ lẹyin ọdun kan ti oun di Pasitọ agba fun ijọ naa.
O ni ọpọ ẹsun ni wọn fi kan oun lori awọn ọna ti oun n gba dari ijọ naa, ti igbimọ majẹobajẹ ijọ naa si pinnu pe ki oun kuro nipo alaga igbimọ naa, ki oun si gbajumọ ipo pasitọ agba ti oun di mu.
Amọ eyi nira fun Jimmy lati se tori o fura pe igbimọ majẹobajẹ naa fẹ maa dari oun ni, to si kọ lati se bẹẹ.
Gẹgẹ bo se wi, awọn arabinrin rẹ mejeeji naa fọwọsowọpọ pẹlu igbimọ majẹobajẹ, lati wa eekanna mọ oun lọrun pe ki oun kuro nipo alaga igbimọ naa, ti ọkan ninu wọn, Tolu si tọ oun wa pe ki oun kọwe fipo silẹ, ki obinrin naa le di alaga igbimọ majẹobajẹ.
O ni nigba ti wọn ko ri ọrọ naa yanju, lo mu kawọn ko ẹjọ lọ siwaju Bisọọbu Mike Okonkwo, to si rọ oun lati yẹba nipo alaga igbimọ majẹobajẹ ijọ naa amọ oun ko se bẹẹ.
Odukoya fikun pe lasiko wahala yii, oniruuru irọ ni wọn hu jọ nipa oun, koda o ni wọn sọ pe oun ko owo ijọ jẹ, ti wọn si dunkooko mọ oun pe wọn yoo gbe ẹsun naa lọ siwaju EFCC.
"Wọn n fi EFCC dẹru ba mi pe mo ko N250m, ti ẹnikan bun ijọ jẹ, amọ owo naa wa nilẹ, n ko fi ọwọ kan-an"
O ni lara ẹsun ikowojẹ naa ni pe oun na milliọnu lọna igba Naira ati aabọ eyi ti ẹnikan gbe kalẹ fun ijọ naa.
Amọ Jimmy sọ fawọn osisẹ ijọ naa pe oun ko nao wo naa tori o si wa nilẹ digbi, ọrọ aje ti ko dara ati bi awọn ọja se n gbowo lori ni ojoojumọ lo se okunfa idaduro to ba isẹ ti wọn fẹ fi owo naa se.
Olusọagutan naa ni ọpọ wahala ti oun dojukọ lati ọdun diẹ ti mu ki oun atawọn ọmọ iya oun yoku, ti wọn jẹ obinrin, kọ ẹyin sira wọn.
Koda, o ni igbimọ majẹobajẹ ijọ naa wọ oun lọ siwaju baba Enoch Adeboye lori pe ki oun kuro nipo alaga igbimọ majẹobajẹ ijọ naa.
"Lori ijoko mi, ni awn ọmọ igbimọ majẹobajẹ naa ti n parọ mọ oun lojukoroju amọ oun salaye awọn nnkan ti oun mọ fun baba Adeboye nipa awọn isẹlẹ ti wọn mẹnuba.
Amọ lẹyin o rẹyin, baba Adeboye ni ka lọ yanju aawọ aarin wa, wọn si ni isẹ iwaasu ihinrere ni wọn pe mi si, kii se lati di alaga igbimọ majẹobajẹ amọ n ko da baba lohun."
"Mo gba awẹ ati adura, baba mi sọ loju ala pe n ko gbọdọ fipo Pasitọ agba silẹ́, Pasitọ kan si ni ki n juwe ọna ile fawọn igbimọ majẹobajẹ ijọ, mo si ti se bẹ́ẹ"
Jimmy ni meji lara awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ naa, Pasitọ Kunle Areogun ati Pasitọ Rotimi Okpaise tig be ibeere onikoko meje siwaju oun amọ mẹrin ninu rẹ ni oun buwọlu.
"Lasiko awọn isoro yii, mo n gba aawẹ, ti mo si n gbadura, mo si n rọ Oluwa lati ba mi sọrọ lori isẹlẹ yii.
Mo fun Ọlọrun ni ọna meji lati da mi lohun, boya ko ba mi sọrọ loju ala ni tabi ko ran eeyan ti n ko mọ si mi lati tan imọlẹ sawọn isẹlẹ yii.
Lasiko aawẹ ati adura yii ni baba mi ti yọ si mi loju ala, to si kilọ fun mi pe n ko gbọdọ juwọ silẹ lori awọn idunkooko igbimọ majẹobajẹ naa.
Baba mi sọ tẹlẹ pe awọn eeyan naa yoo fẹ ta ẹrẹ si asọ aala mi amọ emi ni maa bori wọn.
Lẹyin eyi ni mo pade Pasitọ kan to sọ fun mi pe ti n ko ba juwe ọna ile fawọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ ijọ naa, wọn yoo tubọ maa fun mi ni isoro."
Jimmy salaye pe awọn iriri mejeeji yii lo fun oun ni igboya lati tẹsiwaju, ti oun si ti sọ fawọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ naa lati kọwe fipo wọn silẹ nitori pe ijọ naa fẹ mu ilana tuntun se.


























