Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdìbò ìgbáradì tí INEC fẹ́ ṣé lọ́jọ́ Sátidé

Oríṣun àwòrán, STEFAN HEUNIS / AFP) (Photo by STEFAN HEUNIS/AFP via Getty Images)
Ajọ INEC ti kede ibudo idibo to le ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun, 17,656, jakejado ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, to fi mọ ilu Abuja, lati kopa nibi idibo igbaradi ti yoo waye ni ọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla.
Eto ọhun ti yoo waye laaarin aago mẹjọ aabọ owurọ si aago meji ọsan, jẹ ọkan lara awọn ọna ti INEC fi n mura silẹ fun idibo gbogboogbo ọdun 2027.
Ninu ikede kan ti ajọ ọhun fi sita loju opo X rẹ, lo ti sọ pe eto idibo naa yoo ṣe ayẹwo bi ẹrọ to n ṣe ayẹwo oludibo, BVAS, ṣe n ṣiṣẹ si, ati awọn ipenija to ṣe e ṣe ko waye ṣaaju idibo.
Gẹgẹ bi INEC ṣe sọ, ibudo idibo meji ní ọkọọkan ibudo ìforúkọsílẹ 8,838, ni eto ọhun yoo ti waye.
Igbesẹ yii n waye ni bo ṣe ku diẹ ki eto idibo gbogboogbo waye, ti awọn eeyan lagbo oṣelu si ti n kọminu lori asiko igbaradi fun idibo.
Ṣaaju ni ikọ ipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, sọ pe ki Inec sun eto ayẹwo yii siwaju "ki awọn ẹgbẹ oṣelu le mura silẹ, ki wọn si le kopa bo ṣe yẹ". Wọn ni asiko ti Inec fun awọn ti kere ju.
Atupalẹ awọn ibudo ti idibo igbaradi ọhun yoo ti waye ni ipinlẹ kọọkan
Ibudo idibo 17,656, ni Inec kede pe yoo ti waye:
Abia: 368
Adamawa: 453
Akwa Ibom: 658
Anambra: 652
Bauchi: 424
Bayelsa: 210
Benue: 511
Borno: 622
Cross River: 370
Delta: 598
Ebonyi: 324
Edo: 389
Enugu: 520
FCT: 124
Gombe: 228
Kogi: 478
Niger: 548
Oyo: 702
Osun: 664
Kano: 968
Katsina: 718
Rivers: 638
























