Ìjọba ológun yí àdéhùn padà ní Guinea-Bissau, wọ́n ló di 2028 káwọn tóó gbé ìjọba fún alágbádá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ ologun to n dari orilẹede Guinea-Bissau ti sun idibo to yẹ ko waye lọsẹ to n bọ siwaju pẹlu ọdun meji, to tumọ si pe o di 2028 ki idibo too waye, ki ologun si too fa akoso ilu naa le ijọba awaarawa ti I ṣe alagbada lọwọ.
Ninu ikede ti Gen Horta N'Tam, aarẹ ologun to n dari orilẹede naa ṣe lo ti ni ibo to yẹ ko waye lọjọ kẹfa oṣu Kejila yii ko ni I waye mọ.
Ọga ologun naa sọ pe o tun di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2028.
Ọdun gan-an geerege lo pe bayii ti ologun gbajọba Guinea-Bissau, adehun ti wọn ṣe nigba ti wọn si gba a ni pe awọn yoo ṣe ilu fun ọdun kan, awọn yoo si da a pada fun oloṣelu.
Idi ti ologun fi sun ọjọ idibo siwaju
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ẹka ologun to n ṣejọba naa sọ pe iwadii awọn fi han, pe eto ko ti I to labala imọ ẹrọ lati dibo yii.
Wọn fi kun un pe awọn nnkan eelo naa ko ti I to, bẹẹ ni owo paapaa ko pọ nilẹ lati ṣeto idibo tawọn fojusun.
Awọn ologun naa tẹsiwaju pe bawọn ṣe sun idibo siwaju naa yoo jẹ ki idibo ti yoo ba waye kun fun otitọ, gbogbo oludije ni yoo si ni ẹtọ kan naa lai si magomago kankan.
Bakan naa ni wọn lawọn ko gbagbe idibo ijọba ibilẹ to jẹ alakọkọ iru rẹ lorilẹede naa, ṣugbọn wọn ko sọ ọjọ pato ti idibo naa waye.
Olori ologun to n dari Guinea-Bissau; Gen N'Tam, gbakoso orilẹede naa lẹyin ọjọ kan ti ologun gbajọba lọwọ Aarẹ Umaro Sissoco Embaló, loṣu Kọkanla ọdun 2025.
Iditẹgbajọba to gbe e depo naa si waye lẹyin ọjọ kẹta ti wọn dibo apapọ, ati nigba to ku ọjọ kan ki wọn kede esi idibo.
Awọn oludije to kopa ninu ibo naa lasiko ọhun, Embaló ati Fernando Dias ni ẹnikọọkan wọn ti kọkọ n sọ pe awọn lawọn yege idibo naa.
Embaló ni tié ko gbe ni Guinea-Bissau fun igba pipẹ mọ, ile ajẹji ti i ṣe Morocco lo wa, wọn si fofin de e loṣu to kọja lati ma ṣe pada si Guinea-Bissau mọ, bo tilẹ jẹ pe o fifẹ han lati kopa ninu idibo ti wọn sun siwaju yii.
Orilẹede ti a mọ si Guinea-Bissau yii ko ṣẹṣẹ maa koju iditẹgbajọba, latigba ti wọn ti gba ominira lọwọ Portugal ni 1974 ni wọn ti n koju iditẹgbajọba atawọn igbiyanju rẹ.

























