Àyájọ́ ọjọ́ aṣọ Òfì, láìsí ìrànlọ́wọ́ ìjọba; aṣọ òfì lè parun láìpẹ́

Oba to joko to wọ aṣọ oke
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Asẹyin ti ilu Iseyin Ọba Sefiu Olawale Oyebola Adeyeri III ti pe fun akitiyan ijọba Apapọ ati Ijọba ipinlẹ lati fọwọsowọpọ gbe Asọ Ofi laruge.

‎‎‎Asẹyin ti ilu Iseyin nibi ayẹyẹ asekagba ayajọ ọdun ofi ti ọdun 2026 ni akoko ti to fun ijọba lati nawo si ẹka ti yoo pese ohun elo ti yoo mu ki iṣẹ hihun Aṣọ Ofi gboro si ju akoko yii lọ.

Awon agba ọkunrin to jokoo ti wọn wọ aṣọ oke

‎Ijọba gbọdọ ṣe igbe laruge fun ẹka ile iṣẹ aṣọ ni Naijiria.....

‎

‎‎Asẹyin ti ilu Iseyin ni, iyatọ gbọdọ de ba bii wọn ṣe nṣe Aṣọ Ofi papajulọ bi wọn ṣe nhu,bi wọn ṣe n paa laro ati bi wọn ṣe n ta sita fun lilo.

‎

‎Ọba Sefiu Olawale Oyebola Adeyeri III tẹnu mo si wi pe ohun to daa ju ni ki Aṣọ Ofi jẹ itẹwọgba, ko din wo, ki gbogbo eniyan si ni agbara lati raa, oni bi ijọba ko ba pese iranwọ owo fun awọn to n hu aṣọ, o ṣẹṣẹ ki iye ti wọn n ra awọn Asọ ofi ko gbowo lori sii ju bayii lọ.

‎

‎O gba ijọba apapọ ni moran lati pon ni dandan ki awọn oṣiṣẹ ijọba jakejado orilẹ ede yii maa fi aṣọ ofi kun awọn asọ wọn papajulọ, ki wọn yan ọjọ kan laayo lati ma ṣe igbelaruge fun aṣọ ofi kaakiri orilẹ-ede yii.

‎‎Asẹyin pe fun kiko ilana aṣọ hihun ni ọna igba lode papajulọ ni awọn ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa iṣẹ ọwọ ati iṣẹ ọna.

agba ọkunrin meji ti wọn jokoo ti wọn wọ aso oke
ọkunrin kan to jokoo ni aso oke

‎Ijọba ipinlẹ Oyo yoo bẹẹrẹ iṣẹ lori kikọ Ibudo aṣọ ofi ni Iseyin.

‎

‎Igba keji gomina ipinlẹ Oyo,Amofin ‎Bayo Lawal kede pe ijọba Oyo yoo gunle kiko ibudo aṣọ ofi laipe yii.

‎‎Bayo Lawal pe awọn aladari aṣọ ofi ni ilu Iseyin lati pese aworan ti yoo ṣapejuwe ilana ti wọn fẹ fi ko ibudo aṣọ ofi naa.

‎‎‎Bayo Lawal tẹsiwaju pe, ijọba ipinlẹ Oyo eleyi ti Seyi Makinde le waju rẹ fẹẹ ki idagbasoke to kanri ba ilu Iseyin, papajulọ pẹlu bi o ti fẹ le iwaju lati sọ ilu naa di ilu akọkọ ti wọn ba ti ni sọrọ nipa aṣọ ofi lagbaye.

‎‎Oni ti wọn ba ti fi aworan bi wọn ti fẹ ki Ibudo ti a ti nṣe Aṣọ ofi ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Oyo, kiakia ni kiko ibudo naa yoo bẹrẹ ni waran ṣẹda.

awon okunrin meji to jokoo ti wọn n rerin ti wọn wọ asọ oke

‎Laisi igbaruku ti ijọba, aṣọ ofi le paarun.

‎

‎Alaga ẹgbẹ awọn to n hu aṣọ ofi nilu Iseyin, ọgbẹni Sulimon Onimama ti rawọ ẹbẹ si ijọba ibilẹ ati ijọba ipinlẹ lati se koriya fun awọn to n hun aṣọ Oke.

‎

‎Onimama ṣapejuwe ọkan lara iṣoro ti ẹgbẹ na nkoju, eleyii ti ṣe, airi owo sowo, aisi ibi ipatẹ aṣọ ofi papajulọ eyi ti wọn nhun nilu Iseyin.

‎

‎O pe fún ifọwọsowọpọ laarin awọn to n sowo aṣọ ofi, ki igbelarugẹ le ba ipese ojulowo aṣọ ofi nilu Iseyin.

awon agba okunrin to wọ aso oke
awọn agba ọkunrin ninu asọ oke