Ilé ejọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi òfin gbé Jimmy Odukoya wá sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn fi ofin gbe Pasitọ Pasitọ Jimmy Odukoya, alufaa ijọ Fountain of Life, wa sile ẹjọ.
Nibi igbẹjọ rẹ to waye lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ni adajọ ti paṣẹ.
Eyi ko ṣẹyin bi Odukoya ṣe kọ̀ lati yọju sile ẹjọ lẹyin ti adajọ kọkọ paṣẹ fun pe ki o yọju.
Bakanna ni adajọ na, O. O. Adewunmi-Oshin sọ wipe ki wọn gbe iwe ẹjọ naa fun adari ile-ẹjọ Osborne, lati yan adajọ miran ti yoo maa mojuto ẹjọ Ile ijọsin fountain of life.
Ni ọjọ Aje ni Onidajọ Adewunmi-Oshin ni ki Jimmy Odukoya yọju sile ẹjọ nitori o fi ara rẹ han gẹgẹ bi Pasitọ Agba ile ijọsin Fountain of Life, lọjọ ìsinmi to kọja.
Ile ẹjọ pàṣẹ yii lẹyin ti igbimọ alaṣẹ ile ijọsin Fountain of Life Church, rọ ile ẹjọ lati fun ni iwe ipẹjọọ.
Ninu iwe aṣẹ ile ẹjọ, Onidajo sọ pe
oun fun ile ijọsin naa ni aaye lati gba fun Odukoya ni iwe ipẹjọọ nipa ikede ninu iwe iroyin, ati li lẹ ẹ mọ adirẹsi rẹ to wa ni agbegbe Ilupeju, nipinlẹ Eko, ati lori ayelujara.
Awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ìjọ naa lo rọ ile ẹjọ lati paṣẹ fun Jimmy Odukoya pe ko dẹkun lati maa pe ara rẹ ni Pasitọ Agba ijọ naa.
Eyi jẹ ara nnkan to ti sẹlẹ lati igba ti ija ti n waye lori ẹni ti yoo jẹ olori ijọ naa, lẹyin ti ikede jade pe, wọn ti yọ Odukoya kuro gẹgẹ bi Pasitọ Agba, ati Alaga igbimọ oludari.
Ṣugbọn nigba to n ba awọn ọmọ ijọ sọrọ lọjọ Aiku to kọja, Odukoya sọ pe oun ko ri iwe ipẹjọọ kankan gba.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Oríṣun àwòrán, Jimmy Odukoya
End of podcast promotion
Lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii ni ẹnu ti bẹrẹ si n kun ijọ Fountain of Life Church, to wa niluu Eko lẹyin ti awọn alaṣẹ ijọ naa yọ adari rẹ, Jimmy Odukoya, bii jiga.
Awọn alaṣẹ to yọ pastiọ naa sọ pe awọn gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti fidio kan lu sita, ninu eyii ti oludasilẹ ijọ naa Taiwo Odukoya ṣe ko to dagbere faye, nibi to ti darukọ ẹni ti yoo gba ọpa aṣẹ ijọ naa lẹyin oun, ti eni naa kii sii ṣe Jimmy.
Gẹgẹ bi wọn ṣe ọ, wọn ni iyansipo Jimmy gẹgẹ bii adari ijọ naa kii ṣe ohun ti oludasilẹ ijọ ọhun n fẹ ko ṣẹlẹ lẹyin iku rẹ.
Amọ Pasitọ Jimmy Odukoya ti salaye bi fidio naa se jẹ ati idi ti oun ko se ni kuro lori ipo Pasitọ agba fun ijọ Fountain of Life.
Gẹgẹ bi Jimmy Odukoya ti wi, ọdun 2021 ni wọn se akasilẹ fidio to wa lori ayelujara naa nigba ti baba oun fẹ lọ sisẹ abẹ nilẹ Amẹrika.
O ni baba oun lero pe o seese ki oun ba isẹ abẹ naa lọ, lo se ka fidio silẹ nipa ẹni ti yoo gba ipo rẹ.
Amọ o fikun pe "isẹ abẹ naa yọri sirere, ti baba mi si ni ki n pa fidio naa rẹ nitori ko wulo mọ amọ dipo ki n pa rẹ, se ni mo tọju rẹ pamọ."
Jimmy Odukoya ni asise nla gbaa ni oun se pẹlu bi oun ko se pa fidio naa rẹ, amọ awọn eeyan diẹ lo ni anfaani si fidio naa, to fi mọ awọn arabinrin oun, to si fẹsun kan wọn pe awọn lo ju fidio naa sori ayelujara.
























