Ta ni Balogun Agba ilu Ilorin, Alhaji Aliyu Adebayo Balogun tó dágbéré fáyé?

Oríṣun àwòrán, @Balogun Adebayo
Balogun Agba ilu Ilorin, Alhaji Aliyu Adebayo Balogun ti dagbere faye.
Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ni Balogun agba naa dagbere faye lẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun-un ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ.
Atẹjade ti agbẹnuso Emir Ilorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari, Abdulraheem Muritala fi lede ni wọn ti kede iku oloye agba naa.
Atẹjade naa juwe iku Balogun agba naa bii adanu nla fun ilu Ilorin ati ipinlẹ Kwara lapapọ.
Emir Ilorin ni iku Balogun naa kii ṣe adanu fun awọn ebi rẹ nikan tabi agbegbe Gambari, o jẹ ọfọ nla fun gbogbo ilu Ilorin ati agbegbe rẹ paapaa fun awọn ipa ti wọn n ko ni awọn agbegbe naa.
O wa gbadura ki Ọlọrun pa gbogbo aṣiṣe rẹ mọ ki o si Alujana onidẹra ṣe ikẹ rẹ.
Aago mẹrin irọlẹ ọjọru ni ikede naa sọ pe eto isinku maa waye ni agboole Balogun Gambari niluu Ilorin.
Ta ni Alhaji Aliyu Adebayo Balogun?
Ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila ọdun 1940 ni wọn bi Alhaji Aliyu Adebayo Balogun si idile Balogun Gambari ni ilu Ilorin.
Laaarin odun 1945 si 1951 lo lọ si ile ẹkọ alakọọbẹrẹ Okesuna Primary School.
Lẹyin naa lo tẹsiwaju lọ si College of Administration, Zaria nibi to ti gboye Diploma.
Bakan naa lo tun lọ si Cambridge University ilu London nibi to tun kẹkọọ gboye Diploma lori imọ iṣakoso.
Ni ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 2005 ni Aljahi Adebayo Balogun gori ipo awọn baba rẹ, to di Balogun Gambari ilu Ilorin.
Ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2016 ni wọn di Balogun agba lẹyin ti Balogun Fulani to wa nipo naa, Alhaji Abubakar Atiku Fulani jade laye.
Ipo yii lo sọ wọn di igbakeji Ọba ilu Ilorin gẹgẹ bi aṣa ati iṣe ilu Ilorin pe Balogun to ba ti wa nipo fun igba to pipẹ julọ lo maa di Balogun agba, ti yoo si maa jẹ igbakeji Emir.
Gẹgẹ bi Balogun agba, o jẹ ọkan lara awọn lẹnulọrọ lori eto iṣelu ilu Ilorin bi ofin igbimọ lọbalọba ilu Ilorin ṣe la a kalẹ.
Ṣaaju ko to gboye Balogun Gambari lo ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani ati ijọba to fi mọ ajọ to n ri si eto idibo, INEC.
Ni ọdun 1995 lo jẹ oye Daudu ilu Elemere, ipo to wa fun ọdun titi to fi di Balogun Gambari lọdun 2005.


























