Àwọn ẹ̀kọ́ tó jẹyo níbi ìbò ìgbaradì tí INEC ṣe ṣáájú ètò ìdìbò ọdún 2027

Ẹni to n ya aworan oludibo kan ati oludibo naa nibi eto igbaradi de 2027 ti INEC gbe kalẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii ni ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria; INEC, ṣe eto idibo igbaradi kaakiri orilẹ-ede yii.

‎Igbaradi yii ki ṣe eto idibo gangan,INEC ṣe e lati dan awọn ẹrọ ti wọn yoo lo ninu eto idibo ọdun to n bọ wo ni, ati lati ri awọn isoro to le dide ninu eto idibo apapọ ti ọdun 2027.

Koda, awọn ẹgbẹ oṣelu to wa ninu awọn iwe idibo ti wọn lo fun igbaradi yii ko si ninu awọn ẹgbẹ oṣelu gan-an ti yoo kopa ninu eto idibo apapọ ọdun 2027.

‎Bi idibo igbaradi naa ṣe lọ nipinlẹ Oyo

Awọn oludibo to wa lori ila ni ibudo idibo

Agogo mẹjọ aabọ aarọ ni eto naa bẹrẹ, ṣugbọn ni agbegbe ijọba ibilẹ Ido, ni wọọdu kẹrin, yuniiti akọkọ to wa ninu Ile ẹkọ St. Peters Anglican, Apete niluu Ibadan, eto naa ko bẹẹrẹ ni aago mẹjọ aabọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ ile iṣẹ ọlọpaa ti wa nikalẹ lati bii aago meje aarọ, aago mẹsan-an kọja ki eto idibo naa too bẹẹr, o si pari ni agogo meji aabọ ọsan.

‎Ni ipinlẹ Oyo nikan, INEC yan ẹka idibo 702 fun eto idibo naa, ti woodu kọkan ni yuniiti meji, ìyẹn wọọduu 351 lapapọ, ti yuniiiti si 702 kopa.

‎Eyi mu ki ipinlẹ Oyo jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ti o ni ẹka idibo julọ ni Naijiria, lẹyin ipinlẹ Kano ati Katsina.

‎Eto igbaradi fun idibo ọdun 2027 yii waye ni gbogbo agbegbe ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ Oyo.

Eto igbaradi fun idibo ọdun 2027 naa tun waye ni Iseyin, Ogbomosho, Ilu Oyo, Oke Ogun ati agbegbe Ibarapa.

‎Awọn agbegbe igberiko yii ṣe pataki fun INEC nitori pe netiwọọki ko daa lawọn agbegbe miran nibẹ.

Eyi lo mu ajọ INEC fẹẹ mo bi ẹrọ BVAS ṣe maa ṣiṣẹ nibi ti netiwọọki ko ti lagbara.

Bawo ni awọn oludibo ṣe kopa?

Osise eleto idibo to n reti awon oludibo.

‎Ọpọ awọn oludibo ko jade lati ko pa ninu eto igbaradi fun eto idibo ọdun 2027 naa, nitori ko si ipolongo to.

‎Eeyan perete lo jade lawọn wọọdu ati yuniiti ti akoroyin BBC News Yoruba de, nitori wọn ko mo pe ẹka idibo wọn wa ninu awọn woodu ti aayan lati kopa ninu eto idibo naa kan.

‎Eyi to fi han pe INEC nilo lati ṣe ipolongo ki eto idibo gan-an too waye lọdun 2027.

‎Kí ni eyi tumọ sí fun 2027?.

Eto idibo gan-an yoo waye lọjọ kerindinlogun oṣu kin-in-ni ọdun 2027 fun ti ipo aarẹ ati tawọn aṣofin orilẹ-ede yii, ti ọjọ kẹfa oṣu Keji ọdun 2027 si wa fun ti ipo gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ.

‎Ohun ti ajọ INEC kọ ni Oyo yoo ran lọwọ lati ni oye bi eto idibo ọdun 2027 yoo ṣe ri, ti awọn ẹrọ BVAS ba ṣiṣẹ daradara yoo tumọ si wi pe laarin awọn ilu ati igberiko nipinlẹ Oyo, ajọ INEC ti mura tan.

Igbesẹ yii yoo ran INEC lọwọ lati ṣe atunṣe awọn ibi kudiẹkudiẹ ba wa lori awọn ohun elo ti wọn maa lo fun eto idibo ọdun 2027.