Ta ni Idiat Adebule, aṣòfin Eko tó jáde láyé?

Oríṣun àwòrán, Others
Egbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti kede iku aṣofin to n ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko, Dokita Idiat Adebule.
Ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni Adebule jade laye.
Adebule, ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina jade laye lonii lẹyin to ṣe ọjọ ibi ọdun mẹrindinlọgọta lọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2026.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ APC ipinlẹ Eko, Seye Oladejo fi lede kede iku Adebule bii adanu nla ati ohun ijaya.
Aṣòfin tó ń ṣojú ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Eko nílé aṣòfin àgbà, Idiat Adebule jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
O juwe iku Adebule bii adanu nla fun ipinlẹ Eko ati orilẹ ede Naijiria lapapọ.
Bakan naa lo juwe oloogbe naa bii ọmọwe to poju owo, oloṣelu to dantọ ati oṣiṣẹ ijọba to ni ifarajin si sinsin awọn eeyan agbegbe rẹ.
Iroyin ni ile iwosan kan to wa ni agbegbe GRA, Ikeja, ipinlẹ Eko ni wọn ti kede iku agba oloṣelu naa leyin aisan ranpẹ.
Ọjọ Aje, ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla ni Adebule fẹ ṣe ifilọlẹ ipolongo idibo rẹ fun saa keji lọ sile aṣofin nibi eto idibo ọdun 2027 ki ọlọjọ to de.
Aarẹ Tinubu kọrin aro lẹyin iku Adebule
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti ni iku Sẹnetọ, ẹni to figba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Eko bii adanu nla.
Tinubu ni Adebule jade laye leyin aisan ranpẹ.
Tinubu ni iku eekan oloṣelu naa kii adanu fun ipinlẹ Eko nikan bikoṣe fun gbogbo Naijiria lapapọ.
Atẹjade ti agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga fi lede ṣalaye pe Adebule jade laye lasiko ti wọn nilo iriri rẹ ninu oṣelu.
Bakan lo kan saara si ipa rẹ ninu oṣelu atawọn ohun to gbe ile aye ṣe.
Ta ni Idiat Adebule?
End of podcast promotion
Ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 1970 ni wọn bi Idiat Oluranti Adebule.
O bẹrẹ ikẹkọọ ni ile ekọ Awori College, Ojo ipinlẹ Eko ko to tẹsiwaju lọ sile ẹkọ giga fasiti ti ijọba ipinlẹ Eko nibi to ti kẹkọọ gboye onipo kiini nipa imọ ẹsin Islam lọdun 1992.
Ọdun 1997 lo kẹkọọ gboye onipo keji, to si gboye ọmọwe nile ẹkọ kan naa lọdun 2012 ninu imọ lori aato ikẹkọọ.
Adebule gbajumọ gẹgẹ bi ọmọwe, onkọwe ati oloṣelu to gbajumọ.
Lẹyin to pari sinsin ilẹ baba rẹ gẹgẹ bi agunbanirọ ni ipinlẹ Bauchi, o bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi olukọ ni ile ẹkọ olukọni ti ijọba ipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State College of Primary Education, Noforija, to wa niluu Epe lọdun 1995.
O bẹrẹ si ni di ipo oṣelu mu lọdun 2000 nigba ti wọn yan an ni Kọmiṣanna fun eto ẹkọ Lagos State Post-Primary Teaching Service Commission (PP-TESCOM).
Lẹyin naa lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọmọ igbimọ Lagos State Scholarship Board laaarin oṣu Keji si oṣu Kọkanla, ọdun 2005.
Ni oṣu Keje, ọdun 2011 ni Gomina Babatune Raji Fashola yan Adebule gẹge bi akọwe ijọba ipinlẹ Eko.
Ọdun 2015 ni wọn yan an lati ṣe igbakeji fun gomina Akinwunmi Ambode labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC to si di ipo naa mu titi ti wọn fi pari saa wọn lọdun 2019.
Nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2023 lo dije dupo sẹnetọ Lagos West to si wọle, ipo to dimu titi to fi jẹ Ọlọrun nipe.
Bakan lo tun n dije sipo aṣofin kan naa nibi eto idibo gbogbogbo to n bọ lọna lọdun 2027.

























