'Wákàtí mẹ́ta la fi dúró kí ẹ̀rọ̀ BVAS tó ṣiṣẹ́ níbi ètò ìdìbò ìdánrawò'

'Aago mọkanla owurọ ni ẹrọ BVAS to ṣiṣẹ lati aago mẹjọ aarọ ti a ti wa ni ibudo idibo'
Eyi ni iriri Arabinrin Adedayo Adedoja, ẹni to kopa nibi eto idibo idanrawo to waye kaakiri Naijiria lọjọ Abamẹta.
Ni ipinlẹ Osun, Arabinrin Adedayo Adedoja, to kopa nibi eto idibo idanrawo naa ni wọọdu Kẹfa, yuniiti kẹfa (Ward 6, Unit 6) to w ani orita Itaofa, ilu Ilesa, ijọba ibilẹ Ilesha West kọminu pe wakati mẹta gbako ni ẹrọ BVAS ko ṣiṣẹ.
O ṣalaye pe lati agogo mẹjọ owuro ni oun ti de ibudo idibo ti ẹrọ BVAS, ti wọn fi maa n ṣe iforukọsilẹ awọn oludibo, ko ṣiṣẹ titi di aago mọkanla.

Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC lanaa, ọjọ Abamẹta, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ṣe eto idibo idanrawo lati fi ṣe igbaradi fun eto idibo gbogbogboo ọdun 2027.
Kaakiri Naijiria ni eto idibo naa ti waye lawọn ibudo idibo ti INEC ya sọtọ, tawọn araalu si kopa nibẹ.
Adedoja sọ pe irufẹ iṣẹlẹ yii waye nibudo idibo kan naa nigba eto idibo sipo gomina ipinlẹ Osun to waye ninu oṣu Kẹfa to kọja.
O ni aago meji ọsan ni eto idibo to bẹrẹ ni ibudo idibo naa, nitori ẹrọ BVAS ọhun ko ṣiṣẹ titi di ọsan.
O wa rọ awọn ajọ eleto idibo INEC lati tete mojuto kudiẹkudiẹ to waye lasiko eto idibo idanrawo yii atawọn ipenija ti wọn ri lasiko eto idibo ipinlẹ Osun ki wọn ma baa tun koju rẹ lọjọ idibo gbogbogbo tọdun 2027.
Ki nidii ti INEC fi gbe eto idibo idanrawo kalẹ?
End of podcast promotion
Ni ọjọ ti alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan gbe ikede jade pe awọn eto idibo idanrawo yii maa waye lo sọ pe o maa ṣe iranwọ fun ajọ naa lati ṣayẹwo gbogbo awọn irinṣẹ ti wọn maa lo lati ṣe iforukọsilẹ awọn oludibo ati eyi ti wọn yoo maa fi fi esi idibo ṣọwọ lori ayelujara nibi eto idibo gbogbogbo loṣu Kiini ati oṣu Keji ọdun to n bọ.
Alakoso ajọ eleto idibo INEC nipinlẹ Ọsun arabinrin Oluwatoyin Babalola, ṣalaye pe awọn ṣayẹwo awọn elo ohun idibo lati mọ bi wọn ṣe ṣiṣẹ si ko to di ọjọ idibo gbogbogbo.
O sọ pe gbogbo aw.ọn kudiẹkudiẹ tawọn ri nibi eto igbaradi yii ni awọn maa gbiyanju lati ṣe atunṣe rẹ ko to di ọjọ idibo gbogbogbo.
Arabinrin Babalola kọminu lori bi ọpọlọpọ awọn oludibo ko ṣe jade sita lati kopa nibi eto naa to bẹẹ gẹ eyi to le mu ki awọn ṣawari gbogbo ibi ti ipenija le gbawa lori eto idibo to n bọ.
O wa rọ awọn oludibo lati gbaradi, ki wọn si maa murasilẹ lati kopa nibi eto idibo gangan, ki wọn ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere ati pe ajọ naa ti ṣetan lati ṣeto idibo ti ko ni lẹja n bakan ninu.
Ki ni ayipada to ti ba BVAS ati IReV?
Amupitan fi kun pe idanrawo naa yoo ṣeranwọ lati fi mu igbooro ba ẹrọ Bimodal Voter Accreditation, BVAS atawọn ẹrọ ti wọn maa n lo lati fi ṣe amojuto esi idibo latari awọn kudiẹkudiẹ to waye nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2023.
O tẹsiwaju pe INEC ti mu amugbooro ba awọn ẹrọ to ṣe kumọkumọ lasiko eto idibo 2023 paapaa awọn ti ooru ati ibi ti wọn ko wọn pamọ si ṣokunfa dipo rira awọn ẹrọ tuntun.
O sọ pe ajọ naa ti n kọ ibudo ti wọn yoo maa ko awọn ohun elo idibo pamọ si eyi ti yoo wa ni ibamu pẹlu bi ayipada oju ọjọ ṣe n waye ni gbogbo ipinlẹ kaakiri to wa ni orilẹ ede Naijiria ati pe awọn ti ra afikun BVAS lati lo lasiko eto idibo.
Alaga INEC tun fi kun pe awọn ti mu adinku ba iye orukọ oludibo to le wa lori BVAS lati 1,250 si 850.
Nibi eto idibo gbogbogbo to kọja, oniruuru awuyewuye lo waye lori fifi esi ibo ranṣẹ lati ori ori ayelujara nipasẹ lilo imọ ẹrọ IReV eyi to mu ki ọpọ eeyan ma ni igbagbọ lori lilo imọ ẹrọ naa.
Amupitan naa sọrọ lori eyi to si ni ọpọ awọn eeyan ni ko i tii ni igbagbọ ninu INEC lori lilo imọ ẹrọ naa lati ọdun 2023.
O sọ pe INEC tun ṣawari rẹ pe awọn ibudo ti wọn ti n ko esi idibo ni kudiẹkudiẹ ti maa n waye dipo ibudo idibo gangan, to si ni iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣe atunṣe eyi.
O ni igbagbọ wa pe gbogbo igbesẹ ati ilana ti awọn ti gbe maa mu ayipada ba bi esi idibo ti wọn maa n kede ni ibudo idibo ṣe maa n yatọ si eyi to maa n jade lati ibudo ti wọn ti n ko esi idibo jọ.
O fi kun pe igbesẹ ti awọn gbe yii yoo mu kawọn oludibo ni igboya ninu esi idibo ni kete to ba ti jade.
Afojusun awọn oludibo bii Adedoja ni pe nigba to ba fi maa di asiko eto idibo gbogbogbo to maa waye loṣu Kiini ọdun to n bọ, wọn ko ni maa to fun ọpọ wakati nitori ẹrọ BVAS.




























