Ohun tó fa ìjà tí ayé ń pariwo láàrin èmi àti Ogogo rèé àti bí a ṣe yanjú rẹ̀ - Yinka Quadri

Yinka Quadri wọ buba, Taiwo Hassan to doloogbe wọ agbada pẹlu fila
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agbaọjẹ osẹre tiata Yoruba n ni, Yinka Quadri, ti ọpọ eeyan mọ si Kura ti tan imọlẹ si ede-ai-yede to waye laarin rẹ ati ọrẹ Taiwo Hassan to doloogbe.

Ọgbẹni Quadri to sọrọ ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu FeelRight TV eyi to wa lori itakun ayelujara Instagram ṣalaye pe ''Taiwo Hassan ti di ero ọrun lonii, amọ, ahọn ati ẹnu gan an maa n ja bi wọn ṣe sun mọ ara wọn to.

Tori pe a jẹ ọrẹ timọ timọ, ọrẹ kori ko sun, mo wa fẹ beere lọwọ gbogbo eeyan to n sọ pe awa mejeeji n ja, njẹ ẹ gbọ ọ ri i lẹnu Ogogo ko sọ nnkan to dija silẹ laarin wa?

Bakan naa, njẹ ẹ gbọ lẹnu emi ti mo si wa laaye wi pe nnkan to fa ija emi ati Ogogo ree?

Nnkan tawọn eeyan gbagbọ pe o maa n da ija silẹ laarin ọrẹ meji ni owo ati obinrin.

Mo n sọ fun yin pe owo tabi obinrin ko da ija silẹ laarin emi ati Taiwo Hassan.''

Ilumọọka oṣere naa sọ pe awọn eeyan lo maa n fẹ da ija silẹ laarin ọrẹ meji.

Ọgbẹni Quadri ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe loootọ ede-ai-yede diẹ wa lori iwọ o ju mi emi o ju ọ laarin awọn mejeeji, amọ, o ni ko si a gbe ma ja laye.

''Niwaju Ọlọrun ti eeyan kii pe jẹrii irọ, mi o le sọ pato wi pe nnkan to fa ija laarin wa ree''

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Niwaju Ọlọrun ti eeyan kii pe jẹrii irọ, mi o le sọ pato wi pe nnkan to fa ija laarin wa ree.

Ṣugbọn awọn eeyan kan wa to jẹ wi pe wọn maa n da aarin ọrẹ meji ru ni.

O ṣee ṣe kawọn eeyan kan maa ṣe gbọyii sọ yii fun Taiwo Hassan nigba aye rẹ nipa mi.

Amọ, awa mejeeji ko mọ idi ti a fi n huwa iwọ o ju mi emi o ju ọ si ara wa.

Ogogo dero ọrun lonii o si ti wa ni ipo ootọ, ti wọn ba ni ka wa ro ẹjọ, awa mejeeji ko le ro ẹjọ nnkan to fa ija laarin wa.

Ṣugbọn nnkan to ṣẹlẹ laarin emi ati Ogogo kii ṣe nnkan to lagbara rara,'' Ogbẹni Quadri ṣalaye.

Ọgbẹni Quadri ni nnkan toun ri nibi ọrọ naa ni pe tawọn eeyan ko ba ti ri aarin ọrẹ meji wọ, o ṣee ṣe ki wọn da aarin wọn ru.

O tun wa fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji ti pari ọrọ naa ṣaaju ki Ogogo to jade laye lati bii ọdun mẹta sẹyin.

Quadri tun ṣalaye wi pe oun wa lara awọn ti dokita kọkọ pe lori ọrọ aisan to ṣe Ogogo ko to o dagbere faye.

O ni nigba to ku ọjọ mẹrin ti yoo jade laye ni Ogogo boun sọrọ nile iwosan ti oun si bu sẹkun nile iwosan naa.

Agbaọjẹ oṣere naa tun da si ọrọ to n lọ eyi tawọn kan n beere bo ya Yoruba lo da ere ori itage silẹ tabi awọn ẹya Igbo.

Kura ni ko si ani-ani wi pe agbaọjẹ oṣere tiata Hubert Ogunde to ti doloogbe lo da ere ori itage silẹ ni Naijiria.

Ilumọokan oṣere naa sọ pe ''lati igba ti emi bẹrẹ ere tiata, mi o tii ri ẹya mii to n ṣere ori itage.''