Èèyàn mílíọ́nù 103 ti forúkọ sílẹ̀ fún ìdìbò 2027, Eko, Kano, Kaduna ló pọ̀jù-INEC

Awọn ero to pọ ninu ọgba
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi idibo apapọ ọdun 2027 ṣe n sunmọle, ti ajọ INEC si ti bẹrẹ si I ka ọgọrun-un ọjọ walẹ, ajọ naa ti kede pe oludibo to le ni miliọnu mẹtalelọgọrun-un (103 million) lo ti forukọ silẹ fun idibo naa.

Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa, Ọjọgbọn Joash Amupitan lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣẹgun, nibi ipade awọn alẹnulọrọ niluu Abuja.

Ọjọgbọn Amupitan ṣe afikun alaye rẹ, pe awọn ipinlẹ mẹta ti i ṣe Eko, Kano ati Kaduna ni wọn ti fi orukọ silẹ ju.

O tẹsiwaju pe afikun ba iye awọn to fi orukọ silẹ naa pẹlu eeyan miliọnu mẹwaa mi-in, ju awọn eeyan miliọnu 93.47 to forukọ silẹ ni ninu idibo apapọ ọdun 2023 lọ.

Atupalẹ nipa bawọn oludibo naa ṣe fi orukọ silẹ

Gẹgẹ bi Alaga INEC ṣe wi, oludibo miliọnu meje lo ti forukọ silẹ l'Ekoo.

Miliọnu mẹfa lo forukọ silẹ ni Kano.

Kaduna: O sunmọ miliọnu mẹrin.

Katsina, Rivers, Oyo, Delta, Benue, Ogun ati Bauchi ni eeyan to to miliọnu mẹta-mẹta to ti forukọ silẹ, gẹgẹ bi akọsilẹ INEC ṣe sọ.

"Gbigba kaadi idibo alalopẹ (PVC) yoo bẹrẹ lọjọ kẹsan-an oṣu Kẹwaa ọdun 2026"

Ohun miran ti Ọjọgbọn Amupitan tun fi lede ni pe gbigba kaadi idibo alalopẹ ti a mọ si PVC, yoo bẹrẹ fawọn oludibo lati ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii.

Kaakiri orilẹede Naijiria lo ni eto naa yoo ti gberasọ ni pẹrẹwu.

O rọ awọn oludibo lati tete maa lọ gba bi eto yii ba ti bẹrẹ.

Lati mojuto onka awọn oludibo to ti pọ si i, Alaga INEC sọ pe ajọ naa ti gba ẹrọ Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta (57,000) to jẹ tuntun.

O ni awọn si ti ṣabojuto awọn eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ naa.

"Oludije mejidinlogun (18) lo n dupo aarẹ Naijiria, ọkunrin 16, obinrin meji"

Bakan naa ni Ọjọgbọn Amupitan fi lede pe oludije mejidinlogun (18) lo n dupo aarẹ orilẹede yii lọdun 2027.

O ni eeyan mejidinlogun naa ni awọn si ni ninu iwe INEC bii oludije.

Gẹgẹ bi Amupitan ṣe wi, ọkunrin mẹrindinlogun (16) ni awọn oludije sipo aarẹ naa, nigba ti awọn obinrin ko ju meji lọ.

Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2027 ni idibo aarẹ ati tawọn ile igbimọ aṣofin naa yoo waye bi INEC ṣe kede.

O fi kun un pe INEC ti kede orukọ awọn oludije sipo gomina pẹlu, ati awọn igbakeji wọn, fun idibo sipo gomina ti yoo waye lọjọ kẹfa, oṣu Keji ọdun 2027.

INEC n gbe eto tuntun bọ lori esi idibo bi Alaga wọn ṣe wi, pẹlu lilo ẹrọ igbalode ti yoo ṣe onka esi, ti yoo to wọn lẹsẹesẹ si oju opo ibo IReV .

Wọn tun n ba awọn ileeṣẹ ilẹ okeere sọrọ lorii lilo imọ ẹrọ AI pẹlu, lati fi kẹẹfin awọn ibi ti magomago ba ti fẹ waye ninu idibo naa lori ayelujara.

Awọn ibi ti aabo ti mẹhẹ, ti ọna ko daa, ti ina ọba ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ ko ṣiṣẹ daadaa nkọ?

Nigba to n ṣalaye nipa iṣoro aabo, ọna to buru, ai si ina ọba, eto ibaraẹnisọrọ nirọrun atawọn mi-in, Alaga INEC sọ pe awọn ibeere naa ṣe pataki lati fesi si.

Amupitan sọ pe ipa kekere kọ ni imọ ẹrọ ko ninu idibo ọdun 2023, paapaa lawọn ibi ti awuyewuye ti waye lori esi ibo.

O ni INEC ti ṣetan lati yanju awọn iṣoro yii nipa lilo imọ ẹrọ to tun le ju ti iṣaaju lọ to si jẹ ti igbalode.

O ni ajọ naa ti ṣe mẹjọ ninu nnkan mẹrinla to la kalẹ lati ṣe ṣaaju idibo yii.

Bi INEC yoo ṣe ṣeto ibo to kun fun akoyawọ pẹlu imọ ẹrọ, ti awọn ọmọ Naijiria yoo si gbagbọ lo ku lati gbajumọ bi Alaga wọn ṣe sọ.