"Èéfín ti gba gbogbo ara bàlúù náà lófurufú, tí kìí bá ṣe pé awakọ̀ bàlúù náà dùú dáadáa ni, aráàlú gan ìbá kú nínú ìjàmbá náà"

Àkọlé fídíò, “Èéfín ti gba gbogbo ara bàlúù náà lófurufú, Tí kìí bá ṣe pé awakọ̀ bàlúù náà dùú dáadáa ni, aráàlú ga ìbá kú nínú ìjàmbá naáà”
"Èéfín ti gba gbogbo ara bàlúù náà lófurufú, tí kìí bá ṣe pé awakọ̀ bàlúù náà dùú dáadáa ni, aráàlú gan ìbá kú nínú ìjàmbá náà"
Published

Awọn olugbe ilu Igbọkọda ti ṣalaye fun BBC bi awọn asiko to kẹyin ki baluu ologun ATR42- 500 ti nọmba rẹ jẹ NAF 931 to ja wọ inu ira kan ni ilu naa lọjọ Aje.

Ninu alaye ti wọn ṣe fun BBC, wọn ni awọn ṣakiyesi bi baluu naa ṣe n fi sihin sọhun bi ẹni pe awakọ rẹ n jijadu ko maa balẹ si ibi ti ko yẹ.

Wọn ni eefin ti gba gbogbo ara baluu naa loju ọrun gan bi o ṣe n bọ nilẹ, ti ko si jẹ ki awọn to wa nilẹ rii daadaa nigba naa.

"Awakọ baluu naa gbiyanju lati rii pe baluu yẹn ma ṣaa wọ inu ilu" ni alaye ti ọkan ninu awn to ba BBC sọrọ sọ.

Ẹkurẹrẹ alaye ti wọn ṣe nipa iwa akin ti awakọ baluu naa hu lati rii pe baluu naa ko ja saarin ilu wa ninu fidio yii.