Gbogbo àwọn èèyàn 32 tó wà nínú bàlúù iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà tó já l'Ondo ló kú, Ààrẹ Tinubu ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi awọn eeyan marundinlọgbọn ati oṣiṣẹ baluu naa meje to ku ninu ijamba ọkọ baluu to ja n agbegbe ilu Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun aarẹ,Bayọ Ọnanuga fi sita nirọlẹ Ọjọ Aje, Aarẹ Tinubu ni ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria, Sunday Kelvin Aneke ti fi ẹkunrẹrẹ iroyin ijamba naa to oun leti, oun si ti ni ki iwadi to rinlẹ o bẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa ijamba naa 'lati le dena irufẹ rẹ lọjọ iwaju'.
"Akoko ibanujẹnla gba a niyi fun awọn ọmọogun wa ati fun gbogbo orilẹede yii lapapọ. Awọn ologun ofurufu wa fi ẹmi wọn lelẹ lojoojumọ lati daabo bo orilẹede Naijiria. A ko ni gbagbe ifẹmiaraẹni rubọ wọn."
Bakan naa lo gbadura fun awọn to ku naa ki Ọlọrun le tu awọn ẹbi wọn ninu.
Àkànṣe iṣẹ́ ológun ni bàlúú tó já pẹ̀lú èèyàn 32 l'Ondo ń gbéra láti Benin lọ ṣe l'Eko – Iléeṣẹ́ ọmọogun ofúrufú Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria ni oun ti bẹrẹ eto wiwa ati didoola awọn eeyan to wa ninu baluu ologun to ja ni agbegbe Igbọkọda ni ipinlẹ Ondo, lowurọ ọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọmọogun ofurufu, Ọgagun Ehimen Ejodame fi sita, o ni iṣẹ aṣayan kan ni baluu naa gbera nilu Benin lati lọ ṣe nilu Eko ti ajalu ijamba naa fi waye.
Ọgagun Ehimen Ejodamen tun ṣalaye siwaju sii ninu atẹjade naa pe igbesẹ wiwa awọn eeyan to wa ninu baluu naa ti bẹrẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ijọba gbogbo to yẹ.
Awọn ohun ti a mọ nipa baluu iṣẹlẹ ijamba baluu naa ree

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lowurọ ọjọ aje oni, ọjọ karun-un oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni iroyin jade pe ọkọ baluu kan ti ja lorilẹede Naijiria.
Ohun ti a mọ nipa iṣẹlẹ ijamba baluu naa ree.
- Owurọ ọjọ Aje ni baluu naa gbera ni Ilu Benin to si n lọ si ilu Eko pẹlu eeyan mejilelọgbọn ninu rẹ. Marun ninu wọn jẹ awọn awakọ ati oṣiṣẹ baluu naa ti awọn marundinlọgbọn yoku jẹ ero to ko.
- Nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtala ni atọna rẹ sọnu loju ofurufu ti ibudo atọna baluu ko si rii kan simọ.
- Ko pẹ pupọ si asiko yii ni iroyin jade pe baluu naa ti ja lulẹ nitosi ibudo awọn ọmọogun ojuomi to wa ni ilu igbọkọda ni ipinlẹ Ondo
- Alaye ti minisita fun irinna ofurufu, Festus Keyamo ṣe ni pe nọmba idanimọ baluu naa ni NGR 931 tabi NAF 931, Ẹya baluu ATR-42-500MP Surveyor ni baluu naa.
- Iwadii ti a ṣe fihan pe irufẹ awọn baluu yii jẹ ẹlẹnjini meji ti wọn maa fi n ṣe amojuto ati idaabobo awọn etido atieti omi gbogbo,
- Awọn ọmọogun oju omi ati araalu ṣi nwa awọn eeyan to wa ninu rẹ lẹyin ti wọn ṣawari ibi ti baluu naa ja si
- Lọwọ ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ni awọn iroyin nipa ijamba naa ṣi n jẹyọ lẹyọ ẹyọ ni ati pe iwadi nlọ lọwọ.
Èèyàn 32 ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀ ní Igbokoda-Festus Keyamo, Mínísítà ìrìnàjò òfurufù

Oríṣun àwòrán, Festus Keyamo (SAN)/FB/Getty images
Minisita fun irinajo ofurufu lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, (SAN), ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mejilelọgbọn (32) lo wa ninu ọkọ ofurufu awọn ologun to jabọ n'Igbokoda, ipinlẹ Ondo lọjọ Aje.
Ninu atẹjade ti Keyamo fi sita lọjọ Aje oni lo ti ṣalaye, pe ọkọ ofurufu naa poora lasiko irinajo lati Benin lọ si Eko, ni nnkan bii aago mẹsan-an kọja iṣẹju mẹtala aarọ.
Nọmba baaluu ọhun bi Keyamo ṣe wi ni "NGR 931."
"Gbogbo igbiyanju lati gbe ọkọ naa dide lo ja si pabo, iwadii pada fi ye wa pe ọkọ naa ti ja lulẹ lagbegbe ibudo awọn ọmọ ogun oju omi to wa ni Igbokoda"
Ni itẹsiwaju alaye rẹ ni Keyamo sọ eyi.
O ni, "A ti ri ajaku rẹ, bẹẹ ni wiwa awọn eeyan ati idoola ti n lọ lọwọ.
"Iwadii fi han pe ero mẹẹẹdọgbọn (25) atawọn oṣiṣẹ ọkọ meje lo wa ninu ọkọ ofurufu yii."
Minisita naa lo ṣalaye bẹẹ.
O ni oun ti ba ọga agba ologun oju ofurufu, Sunday Kelvin Aneke sọrọ lori iṣẹlẹ yii, o si ti ṣeleri ifọwọsowọpọ rẹ lori ijamba naa.
Bo ba ṣe n lọ, Minisita irinajo ofurufu ni oun yoo maa fi to araalu leti.
Bàálù ẹlikópítà já lulẹ̀ nílùú Igbokoda l'Ondo, ohun tí a mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Ondo ti sọ pe baalu agberapa ẹlikopita kan ti ja lulẹ lonii niluu Igbokoda ni ijọba ibilẹ Ilaje nipinlẹ Ondo.
A ko le sọ bayii iye eeyan to ku tabi farapa ninu ijamba ọkọ ofurufu ọhun lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Baalu to ja naa ti da ibẹru-bojo silẹ lagbegbe ọhun, pẹlu bi awọn ẹṣo eleto aabo to n doola ẹmi lasiko pajawiri ṣe duro wamu wamu nibi iṣẹlẹ ọhun.
Ẹnikan to n gbe ni agbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Olorunlola Oluwafemi, sọ fun BBC pe ojo n rọ lọwọ ni awọn gbọ ariwo nla kan bi ara.
Oluwafẹmi sọ pe nigba tawọn ri i wi pe kii ṣe ara lawọn jade ti awọn si ri i wi pe baalu lo ja lulẹ.
O ni eefin n ru soke nibi ti baalu naa ti ja lulẹ.
Oluwafemi sọ pe ibi ti baalu naa ja si ko jinna si igbo kan to wa lẹgbẹẹ ibudo awọn ọmogun ori omi Naijiria ti wọn n pe ni Forward Operating Base niluu Igbokoda.
Ẹwẹ, awọn ọmogun oju omi atawọn ẹṣọ eleto aabo mii ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lati doola awọn to wa niluu baalu naa.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.


























