Pete Edochie: Bí òṣèré nínú eré 'Things Fall Apart' ṣe di gbajúmọ̀ òṣèré lágbo tíátà

Oríṣun àwòrán, Supplied via Leo Edochie / Instagram
- Author, Mansur Abubakar
- Reporting from, Abuja
- Author, Wycliffe Muia
- Reporting from, Nairobi
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Fún ọ̀pọ̀ àwọn ìran nílẹ̀ Nàìjíríà, orúkọ Pete Edochie ju gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tí wọn ń pọn le lọ.
Òun ni Okonkwo – Jagunjagun to lágbára, burú, gberaga to si tún jẹ́ onijangbọn, tí ìfarahàn rẹ nínú eré Things Fall Apart jẹ kò di ilumọọka nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé, to sì tún jẹ́ kó wá ní ọkàn ọ̀pọ̀ miliọnu èèyàn.
Kódà, lẹ́yìn tó kú tán, ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria sì lo n fi orúkọ to jẹ nínú eré náà pe e, èyí tó fìdí rẹ mulẹ pé ipa to ko nínú eré náà lo nípa lórí ìṣẹ to yàn láàyò ọhun.
Edochie kú ní ọjọ́ Kẹẹdọgbọn oṣù Kọkànlá lẹni ọdún mọkandinlọgọrin nílùú Enugu to wa lekun ìlà oòrùn gúúsù Naijiria nítorí àìsàn jẹjẹrẹ Asetọ to tí ń ba a fínra fún òjò pipẹ.
Lọ́dún 1987, Edochie kopa ninu ere orí mohunmaworan kan èyí tí wọn fi sọri ìwé kan tí àgbà onkọwe, Chinua Achebe kọ. Bó ti kopa gẹ́gẹ́ bíi Okonkwo lo mú àyípadà ba igbe ayé rẹ̀, to si sọ ọ di ọkan lara àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tí ayé ń bọ̀wọ̀ fún, èyí tó tún sọ ọ di ilumọọka ni awujọ agbaye.
Ere itage to ni ọpọlọpọ ipa yii lo safihan ijijagudu abule kan nílẹ̀ Áfríkà to wa labẹ imunisin ijọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti bí ẹṣin Kristẹni ṣe mú àyípadà ba ìlànà àṣà abalaye to n tọ tẹ́lẹ̀.
Joy Nnamdi, tíí ṣe ọkàn lára àwọn olólùfẹ́ ìwé náà àti ẹda rẹ̀ bíi ère itage lori telifisan gbagbọ pe Edochie lo yẹ jùlọ láti kó ipa òṣèrékùnrin to n léwájú nínú eré tíátà náà.
O ni kò sí òṣèré tíátà miran to le ko ipa Okonkwo dáradára ju Edochie lọ.
End of podcast promotion
"Ipa Okonkwo to ko lo mu kí ìwé arokọ to di gbajugbaja náà dabi tòótọ́." Ìlú Eko to tóbi julọ bíi ìlú ńlá nílẹ̀ Nàìjíríà ló ti so bẹẹ fún BBC.
Ipa to ko nínú eré náà lo mú kí àwọn aráàlú máa rí i bíi ọkùnrin tó le, ojúṣe yìí ló si di mú nínú sinimá ni gbogbo igba to fi ń ṣiṣẹ́ tó yàn láàyò.
"Ko wọpọ láti rí i pe ko rẹrìn nínú sinimá. Ó sábà máa ń ṣe bíi ọkùnrin kan tó burú." Nnamdi lo fikùn bẹẹ.
Pẹlu ohun rẹ to kì, bíi ohun apasẹwaa, to máa ń fì ara rẹ hàn níbi tó bá dé àti bo se mọ òwe ilẹ̀ Afrika pupọ, Edochie ni ọ̀nà to maa n gba di jẹ gàba nínú eré lai fọhun rara.
Bóyá ó kó ipa àgbà kan ni abule ni, olokoowo to jẹ olówó tàbí Ọba alaye to ni ibẹru, ó má ń ṣe àfihàn àgbàlagbà to ni àṣẹ lẹ́nu lójú ìWòran.
Edochie di ọkan lara àwọn gbajúmọ̀ ni agbo òṣèré tíátà, tíí to tí gbòòrò di ọkan lara awọn agbo òṣèré to tóbi julọ ni agbaye.
Láti Kenya de ilẹ̀ South Africa, iléeṣẹ́ agbohunsafefe MultiChoice tí iléeṣẹ́ Africa Magic seranwọ láti gbé àwọn sinimá rẹ de inu ile to tó àìmọye miliọnu nílẹ̀ Áfríkà nítorí bí agbo òṣèré tíátà ṣe di ilumọọka jákèjádò ẹkùn Afrika.
Bi o tilẹ jẹ pe ọ̀pọ̀ sinimá rẹ lo nii ṣe pẹ̀lú àṣà àti ìṣe ẹ̀yà Igbo, àgbéga opo ìdílé àti ẹbi, aáwọ nìdí ogún pinpin, igbagbọ wọn nínú ẹṣin tí wọn yàn láàyò àti asilo agbára àmọ́ àwọn ere tíátà náà maa n jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ àwọn olólùfẹ́ rẹ to tayọ kọjá orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Àmọ́ kí o to di ilumọọka lágbo tíátà, Edochie tí ṣe àṣeyọrí nìdí ìṣẹ agbohunsafefe to kọ́kọ́ yan láàyò.
Ọjọ́ Keje oṣù kẹta ọdún 1947 ni wọ́n bí Pete Edochie nílùú Zaria to wa lekun àríwá Nàìjíríà, ó lọ sile ẹkọ alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti gírámà nílùú Kaduna, kò tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ ìròyìn àti mohunmaworan nílẹ̀ UK.
Lẹ́yìn tó dé sí Naijiria, ó dára pò mọ iléeṣẹ́ agbohunsafefe ẹkùn ìlà oòrùn Naijiria (Eastern Nigerian Broadcasting Corporation) lọ́dún 1967, tíí ṣe ọdún tí ogún abẹ́le bẹ̀rẹ̀ gan-an?
Ó darapo mọ́ ikọ̀ to n beere fún iyapa eya Biafra, láìpẹ́ yìí ló si ṣàpèjúwe asiko ogún náà bíi ìpèníjà ńlá to tí í koju òun jùlọ.
"Lásìkò ogún náà, ìrírí tí á dojú kọ bíi ẹ̀yà Biafra, ṣe o mọ̀, ó nira fún wa láti gbé ilé ayé, Ebi pa wá dé ìdí ka máa jẹ àwọn nǹkan rádaràda." O mú wá sí ìrántí.
Ní iléeṣẹ́ igbohunsafefe náà lọ tí gòkè díẹ̀ díẹ̀ de ipo àwọn adari lẹ́yìn tí ogún abẹ́le parí tán, to si yipada sidi ìṣẹ òṣèré tíátà. Lórí ìṣẹ to yàn láàyò náà èyí tó ṣe fún àìmọye ọdún, ó farahàn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá, to fi mọ Igodo, Rituals àti Billionaires Club.

Oríṣun àwòrán, T.E.N. / MPM via Netflix
Ìṣẹ to yàn láàyò lo di àlàfo to wa laarin sise àwọn kasẹti àgbéléwò àti ṣíṣe sinimá sórí ayélujára.
Ere olólùfẹ́ Lionheart tíì ṣe àkọ́kọ́ láti ilẹ Naijiria tí wọn yóò ṣe lọ́dún 2018 lójú òpó Netflix, lo ṣe afihaawon ìṣẹ rẹ sáwọn onworan yíká agbaye.
Bákan náà lo ṣiṣẹ ni orílẹ̀èdè Ghana, níbi to tí kopa pẹ̀lú àwọn ilumọọka òṣèré ninu ere aláwàdà John àti John lọ́dún 2017.
Wọn mọ́ rírí ipa to ko si agbelarugẹ ìṣẹ ọna àti àṣà lọ́dún 2003 nígbà tí wọ́n fi òye ilẹ̀ wa, the Member of the Order of the Niger (MON) da lola.
Bákan náà lo tún gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹyẹ dáa lola to fò mọ àmì ẹyẹ Industry Merit Award áti ti Africa Magic Viewers' Choice Awards.
Láìpẹ́ yìí ni Edochie tún rí ìsòrí àwọn olólùfẹ́ miran lórí ayélujára.
Bó ṣe máa ń ṣe ojú, àwọn èsì gbankọ àti ipa manigbagbe to tí kò nínú sinimá lọ di ìtẹ́wọ́gbà, tí wọn sì ń lò ó bíi àwòrán lórí ayélujára, èyí tó ń fi ìṣẹ rẹ hàn fáwọn ọdọ ilẹ̀ Afrika.
Fún ọ̀pọ̀ èèyàn ti ko tii wo ere Things Fall Apart tàbí àwọn ere to tí kọ́kọ́ ṣe ni agbo tíátà ni ibẹ̀rẹ̀ ìṣẹ aayan láàyò rẹ, bó ṣe máa ń kánjú koo lo di ìtẹ́wọ́gbà láti ṣe àfihàn ìgbàgbọ́, aifaramọ nnkan tàbí ìyanu nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojumọ.
Àmọ́ bo ṣe di ilumọọka lójú iworan ọ̀pọ̀ èèyàn kii ṣe awada lọdọ àwọn olólùfẹ́ rẹ to wo àwọn ere onise rẹ dàgbà.
Sani Muazu mú wá sí ìrántí pé àwọn òbí rẹ tó wà nilu Kano, lẹkun àríwá Nàìjíríà máa ń pe orúkọ Edochie láti pé àkíyèsí ọmọ to ba n sì ìwà hù láti dẹkùn rẹ.
"Wọn máa sọ fún ẹ pẹ: 'Okonkwo yóò wa bẹ ọ wo, tí ó kó bá dẹkùn ohun tí ó n ṣe' kíá sì là máa bẹ̀rẹ̀ si hùwà dáadáa."
"Ta bá sọ tòótọ́, a dàgbà pelu ẹrú rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú iworan lo wa, tí ko si farahàn laarin wa, àwọn ojúṣe to tí ṣe nínú eré máa ń sá kún ibẹru wá torí ó tún máa ń kopa ninu ere àwo, tí kikopa bíi onroro èèyàn si ba mú pupọ."

Oríṣun àwòrán, T.E.N. / MPM via Netflix
Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àtàwọn akẹẹgbẹ́ rẹ lágbo tíátà lo n ṣe ìdárò ikú rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ṣe àpèjúwe rẹ bíi Akọni to seranwọ láti mú atunto bá agbo tíátà ni Naijiria.
Gbajúmọ̀ òṣèré Genevieve Nnaji náà daro ikú rẹ̀ lójú òpó ayélujára X rẹ.
"Máa jẹ ki ìdánilójú pé ó jẹ́ ayanfẹ, tí ó sì padà sọdọ Ọlọ́run tó ga jùlọ, borí ibanuje àti ìrora mi. Kí ọkàn kìnnìún tòótọ́ sinmi ni alaafia títí láéláé. A nifẹ rẹ." O ṣe ìdárò.
Patience Ozokwor, tí gbogbo ènìyàn mọ sì Mama G, to tí kopa ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ère tíátà pẹlu Edochie, rántí rẹ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré tíátà to dantọ àti orísun ọgbọ́n.
Oludari Fíìmù Babangida Bangis sọ fún BBC pé ikú Edochie jẹ àdánù ńlá fún gbogbo agbaye.
"Mọ ro pe gbogbo agbaye lo pàdánù nítorí ikú rẹ̀, kìí ṣe Nàìjíríà tàbí Afrika nìkan. Gbogbo wa la maa n wo o lójú iworan bí a ṣe ń dàgbà, tí a sì feran rẹ."
Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu náà daro àgbà òṣèré tíátà náà, ó sì ṣàpèjúwe ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àdánù ńlá ni ẹka agbo tíátà àti àṣà àjogúnbá.
Leo Edochie, tíí ṣe ọmọ olóògbé sọ fún BBC pé jẹ ẹni tó ní ìpinnu ọkàn tó lágbára.
"Nínú gbogbo ogún to fi silẹ, mo rò pé gbogbo agbaye yóò gbà pé èyí ni nnkan méjì tó ṣe pàtàkì, sísọ òtítọ́, ká sì dúró sórí òtítọ́".



























