Ìtumọ̀ 'Èmi Ló Kàn' rèé, ọmọ Naijiria ní láti já ìjọba àwarawa gbà padà lọ́dún 2027

Ọgbẹni Rauf Aregbesola wọ aṣọ funfun, o n sọrọ pẹlu ẹrọ gbohungbohun lọwọ rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun ọrọ abẹnu tẹlẹ ri, Ọgbẹni Rauf Aregbesola, ti ke pe awọn ọmọ Naijiria lati ja eto ijọba awarawa gba pada ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.

Aregbesola to sọrọ ninu fidio kan eyi to wa loju opo X rẹ, ṣalaye ohun ti ''Emi Lo Kan'' ọrọ ti Aarẹ Bola Tinubu lo lasiko ipolongo ibo aarẹ ọdun 2023 tumọ si.

Niluu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Tinubu ti sọ pe ''Emi Lo Kan'' nigba to n ṣe ipolongo fun ibo aarẹ ọdun 2023.

Amọ, Aregbesola ṣalaye pe Emi Lo kan tumọ si adari apaṣẹ wa a ti ẹnikẹni ko le yẹ lọwọ wo.

Aregbe ni ''awọn ọmọ Naijiria ni anfaani lati gba ijọba awarawa lọwọ awọn to ja a gba.

Ijọba apaṣẹ wa a ni Emi Lo Kan tumọ si lai deena pẹnu.

Emi Lo Kan jẹ eeyan to lagbara to le ṣe nnkan to ba wu u nigba kugba.

Emi Lo kan la n sọ yii, kii ṣe awa lo kan tabi ẹgbẹ wa lo kan.

''Emi'' jẹ ẹni to lagbara nla lati ṣe ijọba, mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria mọ nnkan ti Emi Lo Kan tumọ si.

Kii ṣe nnkan ti a kan n fi eti wa gbọ lasan an mọ, nnkan to n ṣẹlẹ loju wa ni bayii.

Ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria lanfaani lati dena ikọlu si ijọba awarawa.''

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post