Ṣé lóòtọ́ọ́ ni agbébọn jí akẹ́kọ̀ọ̀ 18 tó ń bọ̀ láti Sokoto wá sí Oke Ogun l'Oyo gbé lọ bí ìjọba Makinde ṣe ń gbara ta pé àwọn kan ló mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ da ìjọba rú mọ́ òun lórí?

Awọn agbebọn meji to gbe ibọn lọwọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn iroyin to n tẹ wa lọwọ fihan pe awọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ mejidinlogun gbe lọ lasiko ti wọn n bọ lati ipinlẹ Sokoto wa si ipinlẹ Oyo.

Gẹgẹ bi asaaju awọn ọdọ nile ẹkọ naa ti wi, awọn agbebọn naa yinbọn pa awakọ mọto naa, eyi ti awọn akẹkọọ naa gba funra wọn.

Awọn akẹkọọ naa lo n bọ lati ile ẹkọ eleto ilera ti Gamji nipinlẹ Sokoto wa si ilu Igboho lagbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo lasiko ti isẹlẹ naa waye.

Asaaju ọdọ kan lagbegbe Oke Ogun, to fidi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe awọn akẹkọọ naa kii se akẹkọọ fasiti Usmanu Danfodiyo nipinlẹ Sokoto gẹgẹ bi awọn iroyin kan se n gbe sita.

O fikun pe agbegbe Mokwa ni awọn agbebọn naa ti ya bo mọto ti awọn akẹkọ naa wọ, wọn si ti sin oku awakọ naa.

Gẹgẹ bi a ti gbọ, awọn akẹkọọ naa lo n haya ọkọ naa lati gbe wọn wa sile nipinlẹ Oyo, ti yoo si ja wọn si ilu abinibi koowa wọn.

Ijọba Oyo gbarata lori isẹlẹ ijinigbe yii, to si n beere pe se kii se pe awọn isẹlẹ yii jẹ ara igbesẹ lati da ipinlẹ Oyo ru?

Wayi o, ijọba ipinlẹ Oyo ti figbe ta lori iwa ijinigbe to kan awọn ọmọ ipinlẹ Oyo eyi to n se lemọlemọ ati gbọnmọgbọnmọ lasiko yii.

Ijọba ipinlẹ Oyo wa n beere pe se kii se pe awọn isẹlẹ yii jẹ ara igbesẹ lati da ipinlẹ Oyo ru?

Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade lo figbe ta bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita lasiko to n sọrọ nipa bi awọn ajinigbe se gbe awọn akẹkọọ mejidinlogun.

Oyelade sisọ loju rẹ pe isẹlẹ yii ni isẹlẹ gbankọgbi ijinigbe kẹta ti yoo kan awọn eeyan ipinlẹ Oyo laarin osu mẹrin.

O ni bi awọn isẹlẹ ijinigbe naa se n waye lemọlemọ yii jẹ eyi to yẹ ka fura le lori paapaa lasiko yii ti igbimọ to n se iwadi isẹlẹ ijinigbe ni agbegbe Oriire gbe abọ iwadi rẹ kalẹ.

Ijọba ipinlẹ Oyo wa n beere pe "Se wọn n mọọmọ doju kọ w ani? Se awọn eeyan kan mọọmọ n do le ipinlẹ Oyo lori ni abi awọn isẹlẹ yii wa lati yi oju wa kuro lori ohun ti a n se ni?

Nigba to n salaye pe o seese ki awọn isẹlẹ ijinigbe naa lọwọ oselu ninu, ijọba ipinlẹ Oyo ni se wọn n gbe igbesẹ naa lati tako ipese ọkọ ọfẹ ati idalẹbi ni?

Ijọba ipinlẹ Sokoto ati ileẹkọ imọ ẹrọ nipa ilera to wa nilu Gamji sọrọ nipa isẹlẹ yii

Wayi o, ijọba ipinlẹ Sokoto ati ile ẹkọ imọ ẹrọ nipa ilera to wa nilu Gamji nipinlẹ Sokoto ti kede pe irọ to jinna sootọ ni iroyin ijinigbe awọn akẹkọọ naa, to si kede pe ko si akẹkọọ kankan nile ẹkọ naa to sọnu.

Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Sokoto fisita loju opo ayelujara rẹ ati eyi ti Akọwe agba funle ẹkọ naa, Abdulrahman Bello kede, lo ni ofege lasan ni iroyin naa.

Awọn atẹjade naa ni iroyin ọhun kii se otitọ rara, eyi to n si awọn eeyan lọna, ti ko si sọ otitọ Ọrọ nipa bi nnkan se ri.

"Ko si akẹkọ ileekọ yii ti wọn ji gbe, ko si si isẹlẹ ijinigbe kankan to kan awọn akẹkọọ wa.

Ileeẹkọ wa atawọn akẹkọọ rẹ ni wọn w ani alaafia, ti wọn si ti de ile koowa wọn ni alaafia.

Wọn wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati kọ ẹyin si iroyin naa tori ko si otitọ kankan ninu rẹ.

Ki ni ileesẹ ọlọpaa sọ nipinlẹ Niger ati Oyo sọ nipa isẹlẹ yii?

Bakan naa ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, ti ni oun ko ti gbọ nipa isẹlẹ naa ti wọn lo waye ni agbegbe Mokwa.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Niger, Wasiu Abiodun, wa seleri lati se iwadii nipa isẹlẹ ijinigbe naa.

Amọ aayan si n lọ lọwọ lati ba agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo sọrọ nipa isẹlẹ naa.

Bẹẹ si ni iwadii BBC News Yoruba n tẹsiwaju lori isẹlẹ naa eyi ti a mu abọ rẹ wa fun yin laipẹ.

Awọn isẹlẹ ijinigbe to milẹ titi to ti waye saaju nipinlẹ Oyo laarin osu mẹrin

Isẹlẹ ijinigbe nla to waye saaju isẹlẹ yii lo sẹlẹ lẹyin ọjọ diẹ ti awọn ajinigbe ji awọn ọdọ to to ogun niye, ti wọn n lọ jẹ agunbanirọ.

Lati ilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo ni awọn agunbanirọ naa ti gbera, fun eto ifinimọle nibudo awọn agunbanirọ, kawọn agbebọn to kọlu ọkọ bọọsi meji to gbe wọn loju ọna Owerri si Onisha nilu Umunoha, Mbaitoli, nipinlẹ Imo ti wọn si ji wọn wọn gbe lọ.

Isẹlẹ ijinigbe miran to tun milẹ titi ni ti bawọn agbebọn se ji awọn olukọ ati akẹkọọ gbe lọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to wa nilu Ahoro-Esinele nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

Akẹkọ meta lo ba isẹlẹ naa lọ, ti wọn si ji apapọ eeyan to to mẹtadinlaadọta lọ.

Ọjọ Kẹẹdogun osu Karun ọdun 2026 ni isẹlẹ naa waye eyi to milẹ titi nigba naa.

Ọjọ mẹrindinlọgọta ni awọn eeyan naa lo ni akata awọn ajinigbe ki wọn to ri idande gba lọjọ Kẹwa osu keje ọdun 2026.