Ṣé lóòótọ́ ni Kira, ọmọ Ogogo bímọ tuntun? Mọ̀lẹ́bí Ogogo sọ̀rọ̀ síta

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laipẹ yii ni iṣẹlẹ iku gbajumọ olokiki oṣere tiata, Taiwo Babatunde Hassan ti ọpọ mọ si Ogogo ṣẹlẹ. Ọjọ Aiku ni iroyin iku rẹ jade si igboro aye, ti wọn si sin oku rẹ ni ilana musulumi lọjọ Aje.

Amọṣa ko ti wọn pari isinku gbajumọ oṣere naa ti iroyin kan tun jade leyi tawọn kan ti n sọ pe ọkan lara awọn ọmọ obinrin oloogbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Shakirat, ti ọpọ n pe ni 'Kira' ti bi ọmọ ọkunrin jojolo.

Amọṣa ko pẹ ti iroyin naa jade ti mọlẹbi oloogbe Hassan Taiwo Ogogo ti pariwo sita pe irọ nla ni iroyin naa.

Haleemah ti o jẹ ọkan lara awọn ọmọbinrin oloogbe Ogogo lo gbe iroyin jade lati da omi iroyin ẹlẹjẹ naa nu.

'Lima' gẹgẹbi awọn eeyan ṣe maa n pe e, ṣalaye pe awọn ẹbi oloogbe naa ti n gba ọpọlọpọ ipe latọdọ awọn eeyan lati beere boya otitọ ni iroyin pe Kira ti bimọ ọkunrin lantilanti.

Iroyin ibi naa n waye lẹyin ọjọ diẹ si iku baba wọn eleyi to mu ki ọpọ fẹ mọ boya lotitọ ni iroyin naa.

Lima tun tẹsiwaju lati da awọn eeyan to n gbe iroyin naa kiri lẹkun, pẹlu afikun pe awọn ṣi n ṣe ọfọ baba awọn to jade lọwọ, nitori naa ki kaluku ye gbe iroyin ti wọn ko ba fidi rẹ mulẹ lọdọ awọn mọlẹbi naa kiri mọ.Fọnran ti awọn kan fi gbe iroyin ofege naa jade lo wa ni isalẹ yii:

Nibo ni iroyin ayederu naa ti kọkọ ṣẹ jade wa?

Gẹgẹbi awọn to mọ nipa ẹbi naa ṣe sọ, fido ati fọto ti wọn ṣẹṣẹ n gbe kiri yii ti waye ni nnkan bi ọdun meji sẹyin nigba ti Kira bi akọbi rẹ nigba naa loṣu keji ọdun 2024 nigba ti baba rẹ ṣi wa laye.

Ogogo funrarẹ ko fi idunnu rẹ bo si abẹ aṣọ̀ nigba naa pẹlu bo ṣe n ṣe ajọyọ rẹ ni gbagede loju gbogbo mutumuwa nigba naa.