Kà nípa àwọn gbajúmọ̀ mẹ́wàá tó ti lùgbàdì àìsàn Jẹjẹrẹ

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aisan ti ko gbọ oogun, k'Ọlọrun ma fi kan wa ni adura ti kaluku maa n ṣe e, amọ nigba mi-in, ọna ki i gba ibi ti ẹda ro, aisan buruku maa n wọle de lai sọ fun ẹnikẹni.

Bo tilẹ jẹ pe awọn dokita sọ pe Jẹjẹrẹ ti a mọ si Cancer ki i ṣe idajọ iku bi eeyan ba tete mọ pe oun ti lugbadi ẹ, sibẹ, ọkan lara awọn aisan to n ja okun ẹmi eeyan ni.

Jẹjẹrẹ ko mọ ọmọde bẹẹ ni ko yọ agba silẹ, ko si sẹni ti ko le mu.

Lagbo oṣere lorilẹede Naijiria, aisan buruku yii ti ṣoro, o ti gba ẹmi awọn miran pẹlu, bẹẹ ni awọn kan ṣi n ba a fa a lọwọ, ti wọn du ẹmi wọn ki Cancer ma baa mu wọn ọ.

Jẹjẹrẹ n ja laaarin awọn gbajumọ lawujọ pẹlu, ti wọn ki i ṣe oṣere. Wọnyi ni diẹ lara awọn gbajumọ lawujọ ti Jẹjẹrẹ ti fọwọba.

Taiwo Hassan (Ogogo)

Ọkunrin rọgbọdọ ti eeyan ko le rokan jẹjẹrẹ si ni Taiwo Hassan tawọn eeyan mọ si Ogogo, ọpọ eeyan lo si ti n ba a kẹdun bi iroyin ṣe gbode pe Ogogo ti ni arun jẹjẹrẹ.

Awọn ọmọ rẹ meji, Shakira ati Halima Taiwo ni wọn n sunkun lori ayelujara lọjọ Aje, nigba ti wọn kede pe Jẹjẹrẹ ti mu baba awọn o, arun naa si ti wa ni ipele kẹrin.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ naa ko sọ irufẹ jẹjẹrẹ to n ṣe Ogogo, iroyin sọ pe jẹjẹrẹ inu ifun ni (Colon cancer).

Monsurat Omotunde Ogundimu

Agba ọjẹ ni iya yii naa lagbo tiata Yoruba, amọ latigba to ti n ba aisan jẹjẹrẹ fa a ni ko ti fi bẹẹ kopa ninu ere mọ.

Opo ni Motunde, ọdun 2012 lo padanu ọkọ rẹ. O n da tọju awọn ọmọ rẹ, amọ jẹjẹrẹ ko wo eyi, o kọlu mama naa.

Laipẹ yii lo sunkun lọ sori eto Talk To B, nibi to ti beere fun iranlọwọ owo lati fi tọju ara rẹ fun aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ (Cervical Cancer) to ni oun ti n koju lati ọdun 2024.

Temitope Osoba

Oṣerebinrin yii lo jade laye laipẹ yii ti iku rẹ si di ariwo latari ọna ti iku naa gba wa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn to sunmọ ọn sọ pe jẹjẹrẹ kọ lo pa a, Tope Osoba naa lugbadi jẹjẹrẹ ọmu ni 2024, o si ṣe iṣẹ abẹ rẹ.

O tilẹ ṣalaye irinajo rẹ lori aisan naa fun BBC News Yoruba lọdun to kọja ninu ifọrọwanilẹnuwo ti a ṣe fun un, amọ ọdun kan lẹyin rẹ lo jade laye yii.

Aisha Abimbola( Omoge Campus)

Gbajumọ oṣerebinrin ti ọpọ eeyan fẹran ni Aisha Abimbola, Ọmọge Campus lawọn eeyan n pe e.

Lojiji ni gudugbẹ ja, Aisha jade laye.

Ohun to pa a, jẹjẹrẹ ọmu ni awọn dokita pe e.

Aisha du ẹmi rẹ, o lọ si Canada fun itọju, amọ ẹlẹmii gba a nigba to di ọjọ kejidinlogun oṣu Karun-un ọdun 2018.

Bukola Iyabo Oshadare

Aṣaraloge lagbo ile tiata ni oloogbe yii, ọdun marun-un lo fi ba jẹjẹrẹ ọyan ja.

O figba kan beere iranlọwọ owo, awọn eeyan si ṣaanu fun un.

Amọ ni ọgbọnjọ oṣu Kọkanla ọdun 2019, Bukola Oshadare jade laye nipaṣe jẹjẹrẹ ọmu.

Banky W

Bankole Wellington gan-an ni orukọ rẹ, akọrin sufee-taka to figba kan ṣe oṣelu ni.

Ojiji ni Banky W kede pe oun ni jẹjẹrẹ ejika, o ṣiṣẹ abẹ lẹẹmeji lorii rẹ ko too ṣẹgun.

Ọjọgbọn Wole Soyinka

Jẹjẹrẹ to maa n ṣe awọn ọkunrin lapa isalẹ nnkan ọmọkunrin to si maa n fa isetọ lo mu gbajugbaja Ọjọgbọn nni, Wole Soyinka ni ibẹrẹ ọdun 2013.

Baba naa ṣalaye pe oun lọ fun itọju ọlọkan-o-jọkan ki arun naa too fi oun silẹ.

Alexx Ekubo

Ọdọ ni a le pe oṣere tiata ọmọ ẹya Igbo yii, nitori ko ju ẹni ogoji ọdun lọ to fi padanu ẹmi rẹ sọwọ aisan jẹjẹrẹ.

Jẹjẹrẹ kidinrin lo pa Alexx Ekubo lọjọ kọkanla oṣu Karun-un ọdun 2026.

Charly Boy

Sọrọsọrọ ni Alagba Charles Oputa tawọn eeyan mọ si Charly Boy, ọdun 2023 lo kede pe oun ṣiṣẹ abẹ lẹyin tawọn dokita ni oun ti ni aisan jẹjẹrẹ ibi nnkan ọmọkunrin ti a mọ si Prostate cancer.

Amọ o pada bori aisan naa.