You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fa ìró ìbọn tó dún lákọlákọ nígboro Osogbo tí ẹ̀mí kan fi bọ́, báwo ló ṣe kan gómìnà Adeleke àti Davido? Àlàyé rèé
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ ọ di mimọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori rogbodiyan ati ikọlu to waye niluu Osogbo l'Ọjọru, ọsẹ yii.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiodun Ojelabi lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita lalẹ ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii.
Ojelabi sọ pe ọsan ọjọ naa ni Gomina Ademola Adeleke ati aburo rẹ to jẹ gbajugbaja olorin takasufee, David Adeleke tọpọ mọ si Davido ṣabẹwo si aafin Ata-Oja tiluu Osogbo, Ọba Jimoh Olanipekun.
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọn kan yinbọn pa baba agbalagba ẹni ọgọta ọdun kan, Tajudeen Yusuf, lẹyin ti awọn tọọgi n gbiyanju lati wọ ọdọ Gomina Adeleke ati Davido lasiko abẹwo wọn si aafin Ata-Oja.
Davido lo tẹle ẹgbọn Gomina Adeleke lọ si aafin ọba alaye naa la ti idupẹ han sii, to si tun fi iwe ẹri ipadasipo han Kabiyesi, pẹlu awọn ileri tuntun ti iṣakoso rẹ yoo ṣe fawọn araalu.
Nnkan bi aggogo mẹta kọja iṣẹju mẹẹdogun ọsan ni wọn sọ pe Gomina de si aafin naa pẹlu ọkọ akọwọrin rẹ ti ko din ni ogun.
Kete ti Gomina kuro ninu aafin naa lati maa lọ, ni wọn lawọn janduku ati tọọgi ti dabọn bolẹ fun ọkọ akọwọrin rẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to farapa.
Gbara ti wọn lawọn janduku naa ti dabọn bọlẹ, ni wọn lawọn ẹṣọ aabo gomina naa ti daa pada fun wọn, to si jẹ pe fun bii iṣẹju mẹẹdogun si ogun iṣẹju ni wọn fi jijakadi pẹlu ibọn.
Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ gangan?
Ninu atẹjade ti ọlọpaa fi sita, wọn ni "Ni nnkan bi agoggo mẹrin irọlẹ Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, ileeṣẹ ọlọpaa gbọ nipa irọyin kan wi pe awọn tọọgi yinbọn fun ọkunrin ẹni ọgọta ọdun kan, Tajudeen Yusuf to n gbe lagbegbe Oke-Ayepe niluu Osogbo.
"Agbegbe Itaolokan niluu Osogbo ni wọn yi yinbọn fun un. Iwadii fi han pe ṣaaju asiko naa ni Gomina Ademola Adeleke pẹlu ọmọ ẹgbọn rẹ, David Adeleke tọpọ mọ si Davido ṣabẹwo si Ataoja tiluu Osogbo, Ọba Jimoh Olanipekun ni aafin rẹ.
"Kete lẹyin abẹwo naa, ọkunrin kan to n jẹ Adebayo Taoreed tọpọ mọ si 'Small Rugged, ọdaran tẹlẹ, afurasi ogbologbo tọọgi to tun jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ okunkun Eye gbiyanju lati wọ ọdọ Davido, ṣugbọn awọn ẹṣọ aabo ko faaye gba a," Ojelabi sọ bẹẹ.
O sọ siwaju pe ohun to ṣẹlẹ yii lo fa faakaja to fi di pe awọn tọọgi agbegbe naa jade lati gbegi dina ẹnu ọna abawọle aafin.
Lẹyin o rẹyin ni Ojelabi sọ pe ọkọ gomina kuro ninu aafin ọhun, ti wọn sib a ti wọn lọ.
"Ko pẹ si igba naa ni awọn afurasi tọọgi yii kuro lagbegbe naa, ṣugbọn ṣa, lasiko ti wọn n lọ, a gbọ pe wọn yinbọn fun Tajudeen Yusuf lagbegbe Itaolokan to wa niluu Osogbo," Ojelabi fi kun ọrọ rẹ.
Ìgbésẹ̀ tó kàn
Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe kete ti iroyin ọhun ti tẹ awọn lọwọ, ni awọn ọlọpaa ti gbera lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn sib a oku Yusuf ninu agbara ẹjẹ.
"Wọn sare gbe e lọ sile iwosan UTH to wa niluu Osogbo lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti awọn dokita sọ pe o tik u."
O wa sọ pe awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ, ati lati rọwọ to gbogbo awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, lati foju wọn bai le-ẹjọ.
Bẹẹ lo sọ pe ọga awọn to ri sọrọ eto idibo l'Osun, Samuel Etaifo tib u ẹnu atẹ lu iwan aa, to si fọkan awọn araalu balẹ wi pe gbogbo ohun ti yoo b agba lawọn yoo fun un lati rii pe ọwọ tẹ awọn to wa nidi ikọlu ọhun.
"Ileeṣẹ ọlọpaa rọ gbogbo awọn to b ani ojulowo iroyin to le ran iṣẹ iwadii wọn lọwọ lati lọ sileeṣẹ wọn to b awa nitosi, tabi ki wọn pe olu ileeṣẹ wọn lori aago lati fi to wọn leti," Ojelabi ṣalaye bẹẹ.
Bakan naa lo tun rọ gbogbo awọn eeyan lati ṣe suuru, ki wọn si farabalẹ lati ma ṣe ṣedajọ lọwọ ara wọn titi digba ti iṣẹ iwadii yoo fi pari.
Ṣe lóòótọ́ ní wọ́n ṣe ìkọlù sí Adeleke?
Kete ti awọn eeyan ti bẹrẹ sii gbe iroyin ọhun, ni gbajugbaja olorin nni, Davido ti gba ori ikanni ayelujara rẹ lọ, lati jẹ ko di mimọ pe irọ to jinna si otitọ ni.
Davido ni ko si nnkan to jọ wi pe awọn tọọgi tabi janduku ṣe ikọlu si ikọ akọwọrin Gomina Adeleke toun wa ninu rẹ.
"Irọ ni! Iwaju ita aafin ni eleyi ti ṣẹlẹ, ko si ni ohunkohun lati ṣe pẹlu wa. Awọn eeyan nifẹ gomina," Davido sọ bẹẹ.