You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé lórí ohun tó fa gbas-gbos láàárín VDM àti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Naijiria
Gbas-gbos tuntun ti bẹrẹ laarin ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ati ajafẹtọ lori ayelujara, Martins Vincent Otse, ti ọpọ mọ si Very Dark Man, VDM.
Eyii ko ṣẹyin bi VDM ṣe sọ pe awọn ọlọpaa lo n ṣe agbodegba fun awọn ajinigbe atawọn janduku agbenipa ni Naijiria.
Amọ ọrọ naa ko dun mọ ileeṣẹ ọlọpaa ninu, eyii lo mu ki wọn kọ atẹjade kan sita pe ki VDM mu ẹri ohun to n sọ jade.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ
Gbas-gbos naa bẹrẹ lasiko ti VDM n sọrọ nibi ipade ẹgbẹ ọlọdọdun awọn agbẹjọrọ ni Naijieia, NBA, to waye niluu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.
Nibi ipade naa ni VDM ti fẹsun kan awọn agbofinro pe awọnlo wa nidi pupọ ijinigbe ati idigunjale to n waye ni Naijiria.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, pupọ igba ni ọlọpaa maa n ja raalu lole.
O tun ni lọpọ igba ni awọn ọlọpaa to n ṣọ oju popo maa n ta awọn ajinigbe lolobo nipa awọn ero oju popo ki wọn le lọ ji awọn eeyan naa gbe.
DVM gbọdọ fi ẹri ọro rẹ lede – Ileeṣẹ ọlọpaa
Ẹwẹ, ọrọ ti VDM sọ naa ko dun mọ ileeṣẹ ọlọpaa ninu, eyii to mu ki wọn ke si pe ko mu ẹri ọrọ naa jade.
Ninu atẹjade kan ti agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, CSP Ani Iniedu fi lede, o ni irufẹ ọrọ bẹẹ ko daa rara, o si le mu ki araalu sọ ireti nu ninu ileeṣẹ ọlọpaa.
Ọlọpaa ni ti VDM ba le mu ẹri jade pe awọn ọlọpaa to n wa loju maa n pe awọn ajinigbe ki wọn lọ ji awọn arinrinajo to lowo lọwọ gbe, awọn yoo ṣe iwadii lori rẹ.
Amọ nigba ti yoo fesi, VDM ni oun ko ni ko ọrọ oun jẹ, ati pe ti ọlọpaa ba le gbe oun lọ sile ẹjọ loun yoo to fi ẹri ọrọ oun lede, ati pe ẹru ko ba oun nitori awọn agbẹjọro oun wa ni digbi.
O ni "Awọn ọlọpaa lo n ṣagbatẹru eto aabo to mẹhẹ. Awọn ologun lo n janfani eto aabo to mẹhẹ. Idi ree tie to abo to mẹhẹ ko fi ni dopin."
Lẹyin naa lo ni oun ko ni dẹkun ati maa sọrọ nipa kudiẹkudiẹ to n ṣẹlẹ ni Naijiria yala o tẹ awọn alaṣẹ lọrun tabi bẹẹ kọ.
O pari ọrọ rẹ pe oun ko ni ko ọrọ oun jẹ, ati pe kaka ki ọlọpaa maa gbogun ti oun niṣẹ lo yẹ ki wọn ṣe ohun to yẹ.
Wayi o, VDM ti bẹrẹ si n fi awọn ẹri kan lede lopo ayelujara rẹ lati ki ọrọ to sọ lẹyin pe awọn ọlọpaa lo n ṣagbatẹru ijinigbe ati eto aabo to mẹhẹ ni Naijira.
Ninu fidio to kọkọ fi lede ni eyii ti ọwọ ti tẹ awọn ọlọpaa to ji araalu araalu gbe lati ja wọn lole wa.