You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fá àkọ̀tun ìjà láàárín Gómìnà Dapo Abiodun àti Sẹnetọ Ibikunle Amosun? Ohun tí a mọ̀ rèé
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato nipa igba tabi akoko ti ija oṣelu to wa laaarin gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun ati gomina tẹlẹ, Sẹnetọ Ibikunle Amosun yoo pari.
Lati ọdun 2014 ni ija ti bẹ silẹ laaarin awọn mejeeji, iyẹn lasiko ti eto idibo gomina to gbe Abiodun wọle n bọ, nigba ti wọn sọ pe Amosun ko nifẹ si bi wọn ṣe fa gomina naa kalẹ lati dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọpọ igba ni awọn agba oṣelu mejeeji nipinlẹ Ogun naa ti gbena woju ara wọn lori ọrọ to nii ṣe pẹlu oṣelu, ati iṣakoso.
Ni bayii, ọna ọtun ni ija wa laaarin wọn tun gba waye, nigba ti wọn sọ pe Gomina Abiodun sọ fawọn eeyan pe iṣakoso oun lo gba Ẹsiteeti Buhari to wa niluu Abẹokuta silẹ loko iparun.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Amosun ti da a lohun wi pe "irọ to jinna si otitọ ni Abiodun n pa."
BBC News Yoruba wa se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ohun to fa
Ni bayii, ọna ọtun ni ija wa laaarin wọn tun gba waye, nigba ti wọn sọ pe Gomina Abiodun sọ fawọn eeyan pe iṣakoso oun lo gba Ẹsiteeti Buhari to wa niluu Abẹokuta silẹ loko iparun.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe Amosun ti da a lohun wi pe "irọ to jinna si otitọ ni Abiodun n pa."
Kí ló fa ááwọ̀ tuntun?
Gomina Abiodun lọsẹ to kọja yii lo sọ pe iṣakoso oun lo gba ẹsiteeti Buhari silẹ loko iparun, ti ko si jẹ ki wọn wọgile e.
Abiodun sọ pe awọn ti sọ agbegbe naa di ti igbalode pẹlu ile alarambara to ti ko din ni mejidinlaadọfa ti wọn ti kọ sibẹ.
Oni, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni wọn fẹẹ ṣiṣọ loju awọn ile naa, ko too bẹrẹ sii di tita ati rira.
Iyawo aarẹ ilẹ Naijiria, Oluremi Tinubu la gbọ pe yoo ṣe ifilọlẹ awọn ile ọhun ninu gbọngan aṣa ti June 12 to w ani Kuto niluu Abẹokuta.
Gomina Abiodun sọ pe iṣẹ akanṣe naa ṣafihan ifarajin iṣakoso oun lati daabo bo ohun ini idokoowo ijọba, ati lati pari awọn iṣẹ akanṣe ti iṣakoso oun jogun, dipo ki wọn pa a ti sẹgbẹ kan.
"Iṣẹ akanṣe yii lo ṣafihan ifarajin iṣakoso wa nipa pipese ile gbigbe ti ko ga ni lara fun awọn araalu, nigba ti a n fọkan awọn eeyan balẹ wi pe ijọba a n pari awọn iṣẹ ajogunba dibo ki a pa wọn ti," Abiọdun sọ bẹẹ.
O ni ohunkohun ko tii ṣẹlẹ lagbegbe naa nigba ti awọn gba iṣakoso, yatọ si wi pe wọn tig be e fun awọn ileeṣẹ kan, to si jẹ pe ile kan ṣoṣo ni wọn ṣi kọ sibẹ.
Abiodun jẹ ko di mimọ pe kikọ lati san awọn owo to yẹ, lo fa a, ti iṣẹ fi duro ko to di pe awọn gba ijọba.
O ni eyi lo fa idi to fi jẹ pe diẹ lo ku ki wọn wọgile iṣẹ akanṣe naa nipa ofin, ki oun too lọ yanju ọrọ ọhun to wa nile ẹjọ, lati bẹrẹ sii san awọn gbese.
Amosun dáa padà fun Abiodun
Ṣugbọn nigba to n tako ọrọ Abiodun, Ibikunle Amosun sọ pe ko si otitọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti gomina naa fi kan iṣakoso oun.
Amosun sọ pe ọna lati dabaru itan akọsilẹ ẹsiteeti naa ni Abiodun n wa, nitori pe awawi lasan ni gbogbo ohun to sọ nipa wi pe wọn gbe ijọba oun lọ sile-ẹjọ nitori kikọ lati san owo to yẹ fawọn agbaṣẹṣe.
Ninu atẹjade ti Amosun fi sita lọjọ Aje, eyi to pe akori rẹ ni "Bi Gomina Abiodun ṣe gba Ẹsiteeti Buhari silẹ: Odiwọn agbekalẹ ẹtanjẹ", lo ti sọ ọ di mimọ pe "irọ to jinna si otitọ ni".
"A ko dahun nitori wi pe ẹsun ti wọn fi kan wa jẹ otitọ,, tabi nitori pe awọn to kọ ọ n wa ọna lati tun itan wa kọ.
"A ko dahun nitori ti a gba wi pe alaafia ati iṣọkan to ti n jọba nipinlẹ wa ṣe patai ju ka maa ṣe faakaja pẹlu awọn to yẹ ki wọn maa fi orukọ wa ṣalaye awọn iṣẹ aṣeyọri wọn," Amosun sọ bẹẹ.
O tun sọ siwaju pe "ko yẹ ki ipàde awọn oniroyin jẹ eyi ti wọn yoo maa fi sọrọ nipa iṣakoso to ti kọja," pẹlu afikun wi pe gbogbo iṣakoso ni wọn gbọdọ maa ri awọn iṣẹ ti wọn ba ṣe.
"Ni awọn igba kan, awawi kii ta leti mọ, ibanilorukọjẹ si maa n awọn ti ko wulo, ati pe gbogbo iṣakoso lo gbọdọ le duro niwaju awọn eeyan nipa okun to ni – tabi nipa ibi to ku diẹ kaato si – fun awọn iṣẹ to ti ṣe."
Amosun sọ siwaju pe pupọ ninu awọn aṣeyọri ti iṣakoso Abiodun ṣakọsilẹ fun ara rẹ, lo jẹ pe iṣakoso oun lo ṣe e, lati fi saami ayẹyẹ ogoji ọdun ti wọn da ipinlẹ Ogun silẹ, eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari wa a ṣi lọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun 2016.
"Lara rẹ ni opopona mẹtalelogoji to ja sira wọn, eyi ti a ti sọ lorukọ awọn ababa-nla wa to lọwọ ninu idasilẹ ipinlẹ Ogun,, pẹlu awọn ina opopona, ina mọnamọna, omi ẹrọ igbalode, agbegbe ida idọti si, agbegbe omi, agbekalẹ afẹfẹ gaasi ati awọn miran.
"Ni afikun, agbekalẹ ọtun nipa okoowo ṣiṣẹ fun awọn olugbe ati awọn to n wa lati ita, ile-ẹkọ ati awọn agbegbe dukia miran ti a ya silẹ ni ilẹ ẹkita aadọsan (170)," atẹjade ọhun ṣalaye.