You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé NDLEA rèé tó ṣe dáná sun òògùn olóró tí iye rẹ̀ tó ₦301bn l'Eko
Awọn eeyan to n ti inu gbigbe oogun oloro ati tita rẹ di ọlọ́rọ̀ niluu Eko ti padanu obitibiti Cocaine, Heroin, atawọn mi-in si ọwọ ajọ NDLEA to n gbogun ti oogun oloro.
Niṣe ni NDLEA dana sun awọn nnkan mimu naa ti owo rẹ to ₦301bn.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni wọn dana sun awọn nnkan naa niluu Eko.
Ìwọ̀n awọn oogun oloro naa ati ibi ti NDLEA ti dana sun wọn
Gẹgẹ bi NDLEA ṣe pe onka awọn oogun oloro ti wọn dana sun naa loju opo X wọn, wọn ni o ju iwọn 329,865 lọ, owo rẹ si to biliọnu ookan le ni ọọdunrun naira (₦301 billion).
Ita gbangba ni wọn ti dana sun awọn oogun oloro ti wọn ti gbẹsẹ le tẹlẹ naa, Navy Town lagbegbe Ojo, nipinlẹ Eko ni wọn ti sọna si i.
NDLEA ṣalaye pe ile ẹjọ lo paṣẹ pe kawọn yanju awọn nnkan to n ṣe ara ni ijamba tawon ti gba lọwọ awọn to n huwa ọdaran naa.
Lara awọn oogun oloro ti wọn dana sun naa ni ọkan ti wọn fi oriṣi mẹfa po pọ.
Awọn yoku ni Cocaine, Heroin, Methamphetamine, Ephedrine, ewe Khat, Tramadol ati Codeine to wa fun itọju ara riro nla, amọ tawọn eeyan ti sọ di oogun oloro nipa amuju rẹ.
Bakan naa ni awọn oriṣi igbo mimu ọlọkan-o-jọkan wa nibẹ, awọn bii eyi ti wọn n pe Loud ati Skunk.
Láàárín 2025 si 2026 ni NDLEA gbẹsẹ le awọn oogun oloro naa
NDLEA ṣalaye pe laaarin oṣu Kẹrin ọdun 2025 si oṣu Karun-un ọdun 2026 ni awọn gbẹsẹ le awon nnkan wọnyi niluu Eko.
Ajọ naa sọ pe o to iwọn 246,864.535 nnkan oloro ti oun dana sun.
Wọn fi kun un pe afikun ogun oloro ti iwọn rẹ to 83,001.05 naa wa lara eyi tawọn ẹka pataki kan l'Eko gba, titi kan awọn eyi ti wọn gba ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport (MMIA), ati Tincan .
Alaga NDLEA to tun jẹ ọga agba ajọ naa, Ajagunfẹyinti Ọgagun Mohamed Buba Marwa, ṣapejuwe awọn oogun oloro rẹpẹtẹ ti wọn dana sun yii bii ọna kan lati da aabo bo awọn ọmọ Naijiria, ati igbogunti imukumu tawọn kan fi n ṣe okoowo.
"Ibi yowu ki o sa si, ẹni yowu to n ṣe onigbọwọ fun ọ, bo si tilẹ wu ki imọ igbalode yin le to, ọwọ ofin yoo tẹ ọ"
Ọgagun Marwa lo kilọ bẹẹ.
"Awọn bandiiti, ajinigbe, adigunjale, agbesunmọmi ati bẹẹ bẹẹ lo n lo awọn oogun oloro wọnyi bii eemi ti wọn n mi simu"
Bakan naa ni ọga agba ajọ Aṣọbode ilẹ Naijiria, Bashir Adewale Adeniyi, nigba to n sọrọ lori igbesẹ NDLEA yii, sọ pe:
"Awọn bandiiti, ajinigbe, adigunjale, agbesunmọmi ati bẹẹ bẹẹ lọ n lo awọn nnkan wọnyi bii eemi ti wọn n mi simu.
" Ba a ṣe dana sun wọn yii n tọka si pe awọn to n ṣowo oogun oloro ti jẹ gbese owo to to biliọnu naira, a si tun dena iwa ọdaran."
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti Akọwe ijọba ipinlẹ Eko, Abilekọ Bimbola Salu-Hundeyin, ṣoju fun nibi eto naa, sọ pe iranti ni eyi jẹ, pe ewu gidi lo n bẹ ninu oogun oloro lilo.