Awuyewuye tún bẹ́ sílẹ̀ lórí ìyọnípò olórí ilé aṣòfin Ondo

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ifanfa to n waye laaarin olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, Olamide Oladiji atawọn aṣofin ṣi n tẹsiwaju bawọn ẹsun tuntun mii ṣe n jade.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn aṣofin naa n ṣepade lọwọ, ninu igbiyanju wọn lati yọ olori ile aṣofin naa nipo, ki awọn janduku mẹta kan, ti wọn fẹsun kan pe wọn jẹ janduku oloṣelu to lọ da ibi ipade naa ru.

Iroyin fi kun pe awọn ọlọpaa lati olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lo tete ji giri sawọn janduku naa ki awọn aṣofin naa to le maa ba ipade wọn lọ.

Awọn aṣofin naa tẹsiwaju pẹlu ipade wọn lẹyin ti wọn le awọn janduku naa sita.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ o ranti pe lati bii oṣu kan sẹyin ni ifanfa ti n waye laaarin olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo atawọn aṣofin ile naa nibi ti aṣofin mọkanlelogun ninu mẹrindinlọgbọn to wa nile aṣofin naa ti tọwọ bọ iwe lati yọ olori ile naa nipo.

BBC News Yoruba kan si alaga igbimọ ile lori iroyin, Olatunji Fabiyi nigba ti iroyin naa kọkọ jẹ jade ninu oṣu Keje to kọja lati mọ idi ti ile fi n gbe igbesẹ lati yọ olori ile naa nipo rẹ.

Fabiyi sọ pe idi ti awọn fi gbe igbesẹ naa ko ṣẹyin ẹsun pe olori ile aṣofin naa ati igbakeji rẹ, ṣagbeyẹwo aba isuna ajọ to n ri si idagbasoke awọn ẹka to n pese epo rọbi ni ipinlẹ Ondo, (OSOPADEC).

O ni wọn si buwọlu u lorukọ gbogbo awọn ọmọ ile aṣofin lai si imọsi awọn nibẹ.

O fi kun pe olori ile naa tun gbe miliọnu mẹrinlelogoji naira ninu aba isuna ajọ naa gba oko ibomiran.

Fabiyi sọ pe awọn aṣofin mọkanlelogun ninu awọn mẹrindinlọgbọn to wa nile aṣofin naa ni wọn ti buwọlu iwe pe awọn ko fẹ ki olori ile naa dari awọn mọ nitori o ti tapa si ofin to de ọfiisi rẹ.

O fi kun pe ọrọ naa ko fa ija tabi mu ifanfa dani rara, nitori gbogbo awọn ọmọ ile to n binu lori iṣẹlẹ naa ti fi ọrọ naa to gomina leti to si ti ba awọn da si.

O ṣe afọmọ rẹ pe ki i ṣe pe awọn n ditẹ mọ ijọba tabi gbiyanju lati tapa si awọn alaṣẹ, bikoṣe pe awọn fẹ fi han pe iwa ti olori ile naa hu lodi si ofin, to si jẹ ohun to le gbe de ọgba ẹwọn.

O fi kun un pe awọn ko ba olori ile fa ijangbọn, awọn wulẹ sọ fun un pe ko kọwe fipo silẹ ni, amọ ẹbẹ lo n bẹ.

Bakan naa lo tun ṣalaye ipa ti Gomina Lucky Aiyedati ti ko lori ọrọ naa, to si sọ pe

Gomina Aiyedawati ko da awọn lọwọ kọ lori igbesẹ tawọn fẹ gbe, o kan ni kawọn ni suuru.

"Gomina ni ka ni suuru, o ti pe wa lẹẹmeji tẹlẹ a si ti dahun, a n reti ipe rẹ lẹẹkẹta si i.

N jẹ bi gomina ba ni ki wọn ma yọ Oladiji nipo, ṣe wọn yoo gba si I lẹnu ni BBC beere lọwọ Fabiyi, o si dahun pe aarin awọn ati gomina ni iyẹn wa.

Ibi ti ọrọ de duro

Amọ niṣe ni ọrọ tun gba ibomiran yọ ni ọjọbọ nigba ti awọn janduku tun ṣe ikọlu sawọn aṣofin lasiko ti wọn n ṣepade lọwọ ti wọn si n fẹsun kan pe olori ile aṣofin lo ran awọn janduku si wọn.

Ile iṣẹ iroyin The Punch sọ pe ṣaaju ki ipade naa to waye ni awọn ba alaga igbimọ to n ri si iroyin ile sọrọ, Fabiyi to si sọ pe awon ṣi maa yọ olori ile nipo ati pe awọn ko fopin si igbesẹ iyọnipo naa gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe kiri.

O ni gbogbo awọn aṣofin lo ti pinnu pe Oladiji ko le ṣe olori fun awọn mọ bi o tilẹ jẹ gomina Aiyedatiwa ti n ba awọn sọrọ amọ ko ni da ipinnu awọn duro.

Nigba to n fesi si ẹsun ti wọn fi kan an pe o ran awọn janduku sawọn aṣofin nibi ti wọn ti n ṣe ipade, olori ile aṣofin naa, Olamide Oladiji jiyan ẹsun naa, to si ni ohun ko ran ẹnikẹni lati lọ da ipade awọn aṣofin ru.

Oladiji tẹmpẹlẹmọ gbogbo igbesẹ lati yọ oun nipa olori ile aṣofin lo ti lọ sodo lọ mumi nitori wọn ti yanju ọrọ naa ni tubi n nudi.

O ni Gomina Aiyedatiwa atawọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti ba awọn da si ọrọ naa ati pe ọjọbọ gan lo yẹ ki awọn bẹrẹ ijokoo ile pada.

Bakan naa lo fi kun pe awọn ti wọn wọ ile aṣofin ti wọn fẹsun kan wọn lọ da ile aṣofin ru lo jẹ awọn olorin ọdọ ni awọn agbegbe ti oun n ṣoju rẹ ati pe wọnse abẹwo si oun nitori ati gba fọọmu iwe iṣẹ kan ti oun ni ki wọn wa fun ni.

O sọ pe igba akọkọ ti awọn eeyan naa yoo maa ṣabẹwo si oun niyẹn ṣugbọn tawọn aṣofin yari pe awọn ko fẹ ri wọn ninu ọgba.

O fi kun pe awọn pada pari ọrọ naa nigbẹyin nigba ti oun jade sawọn aṣofin naa pe oun ni wọn wa wa ti oun si ṣalaye oun ti wọn ba wa fun wọn amọ ti wọn kọ pe awọn ko fẹ ri wọn ninu ọgba naa mọ ni.

O ni ko si ohun to jọ mo iyọnipo tabi fifun oun ni iwe lati kuro ni ipo oun mọ nigba ti wọn ti ba awọn da si.