You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Èrò àwọn èèyàn ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí Ademola Adeleke ṣe wọlé ṣáá kejì sípò gómìnà Osun
Giwa agba fasiti apapọ to wa niluu Oye Ekiti, Ọjọgbọn Joshua Ogunwole to jẹ alakoso eto idibo ọhun lo kede Adeleke ni deedee agogo meje kọja iṣẹju mẹrinlelogun ọjọ Aiku, lẹyin akojọpọ gbogob idibo ti awọn araalu di kaakiri.
Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi àyájọ́ ọdún Sango àgbáyé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Oyo
Ọpọ awọn aṣoju aṣa kaakiri agbaye bii Paulo Santos lati orileede Portugal, ati Felix Coastales lati orileede Spain ni wọn peju sibi eto ayẹyẹ ọdun Sango naa, to wọn si gbe oriyin fun Alaafin Oyo lori ipa ati akitiyan rẹ nipa gbigbe aṣa ati iṣẹṣe larugẹ.
Kókó ohun mẹ́fà nípa Ademola Adeleke, gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó wọlé ṣáá kejì
Fasiti Jacksonville State to wa niluu Alabama ni Adeleke lọ nilẹ Amẹrika, nibi to ti kẹkọọ nipa ẹkọ nipa eto oṣelu.
Adeleke fìdí Oyebamiji àti Salaam janlẹ̀, ó borí ìbò fún sáà kejì
Bi idibo ṣe waye naa ni kika rẹ ti gbera sọ lawọn ibi kan l'Osun
NÍ YÀJÓYÀJÓ, Àkójọpọ̀ ìròyìn bó ṣe ń lọ nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun
Ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun
Afurasí tó gún ₦56.4m owó Hajj tó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́bẹ n'Ibadan fojú ba ilé ẹjọ́
Gẹgẹ bi EFCC ṣe ṣalaye, awọn ti olujẹjọ lu ni jibiti owo naa ni: Jibril Adamu, Suleiman Aminatu, Musa Haruna, Suleiman N. Abdullahi, Audu Bello, Yusuf Umaru, Saidu Musa, Idris Suleiman, Musa Yunusa ati Usman Haruna.
Wo bí àwọn obìnrin Afghanistan tíjọba Taliban fòfin dè pé wọn ò gbọdọ̀ gbá bọ́ọ̀lù ṣe di agbábọ́ọ̀lù nílẹ̀ òkèèrè
Lati ọdun 2021 ti awọn Taliban ti gbajọba ni wọn ti fofin de awọn obinrin wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ere bọọlu atawọn ere idaraya mii.
Olùdìbò 1.9m ni wọ́n ti n gbaradì fún ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun – INEC
Gbogbo awọn oludije, alatilẹyin oludibo, alẹnulọrọ nidi oṣelu, to fi mọ awọn araalu ni wọn ti wa ni igbaradi eto idibo idibo gomina ọhun.
Makinde lóùn ṣetán láti ṣàtúntò Nàíjíríà lọ́dún 2027
Gomina Oyo to n jade du ipo Aarẹ ilẹ Naijiria l'ọdun 2027 sọ pe oun yoo ṣiṣẹ lati rii pe Naijiria de ipo ti awọn araalu n foju sọna fun.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Pásítọ̀ Olùdásílẹ̀ ìjọ Ọlọ́run ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ di oníṣẹ̀ṣe tó sí pa orúkọ dà láti Felix sí Ifawamiri
Ifawamiri tun fikun ọrọ rẹ wi pe ẹtan lo wa ninu ẹsin ajoji tawọn oyinbo mu wa silẹ alawọ dudu.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Má forúkọ mi ṣe ìpolongo ìbò mọ́, Makinde dá a padà fún Oriyomi
Makinde wa rọ àwọn eeyan to n dupo òṣèlú wí pé ki wọn gbaju mọ nnkan ti wọn ba fẹ ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Oyo, dipo bi wọn ṣe n bu oun kaakiri.
Ìye èèyàn tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì Columbia ti lé ní 240
A gbọ o ṣeeṣe ki iye awọn to ti ku naa tunbọ pọ si latari ọpọ eeyan ti wọn ti ha sabẹ awọn ile to dawo.
Ooni Ile Ife kéde orúkọ ọmọbìrin rẹ̀ tuntun
Ọjọ kẹjọ lẹyin ti Olori Oluwatosin Ogunwusi bi ọmọbinrin tuntun naa ni ayẹyẹ isọmọlorukọ ọhun waye.
Àgbékalẹ̀ ètò agbófinró tí kò ní ṣe ojúṣàájú fún ẹnikẹ̀ni ni ìjọba ń fẹ́ – Fagbemi
Adajọ agba sọ pe eto agbekalẹ naa ni lati fi ọkan gbogbo araalu balẹ nipa ilana eto iṣẹ awọn ọlọpaa fun ti idasilẹ ọlọpaa agbegbe ti wọ n foju sọna fun, iyẹn nigba ti wọn ba da a silẹ.
Ìdí tí Iran ṣe n sa gbogbo ipá rẹ̀ lórí òpó Strait of Hormuz
Ọna mẹta to la silẹ fun Iran bii abayọ ko fi gbogbo ara pé wọn
Farooq Oreagba ṣàlàyé bó ṣe di olówó l'ọ́gbọ̀n ọdún
Oreagba lo tu awọn aṣiri yii lasiko to n dahun ibeere lori eto ori ayelujara laipẹ yii, to si tun jẹ ko di mimọ pe oun mu ọrọ igbe aye ju owo lọ.
Mọ̀lẹ́bí St. Janet kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ilu-mọ-ọn-ka olorin naa fi aye silẹ, .
Àwọn agbéṣùmọ̀mí ti ń lo ẹ̀rọ drone àti crypto láti mú ìmúgbòòrò bá iṣẹ́ ibi wọn - Ajọ UN kìlọ̀
Akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, Leonardo Simão, lo ke gbajare naa fun awọn adari ilẹ Afrika ati Sahel.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Wo kókó ohun márùn-ún tó ń fa àìgbọ́raẹniyé láàárín tọkọtaya
Fun apẹẹrẹ, ọkọ le ma nigbagbọ ninu iyawo rẹ lasiko to ba jade lọ, tabi pe iyawo naa ma nigbagbọ ninu ọkọ rẹ.
Nítorí ìjà ilẹ̀ àti ìdigunjalè, èèyàn mẹ́wàá bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá l'Ondo
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Felix Ohagwu, ṣalaye pe meje ninu awọn mẹwaa naa ni awọn mu latari rogbodiyan ija ilẹ kan to ṣẹlẹ ni Kajola, niluu Akure.
Ilé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé dàwó, èèyàn méjì kú, mẹ́ta dèrò ilé ìwòsàn
Akojọpọ awọn adoola ẹmi lati ajọ Red Cross, NEMA, ileeṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Anambra, SEMA, ileesẹ panapa, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn adoola ẹmi miran ni wọn wa nibẹ.
Baálé ilé fi ìyàwó àtàwọn ìbejì tí wọ́n bí sílẹ̀ ní South Africa, sá wá sí Nàìjíríà, àlàyé rẹ̀ rèé
Ọkan lara awọn to koju idaamu ti South Africa gbe lu awon ajeji laya ni Richard Itoro
Aláboyún méje bí ọmọ kú lọdọ̀ ajínigbé, márùn-ún gbé ọmọ wálé, àgbàdo àti iyọ̀ lóunjẹ wa lẹ́ẹ̀kan lọ́júmọ́ - Àwọn èèyàn ìlú Wọrọ tó gba ìdáǹde lọ́wọ́ ajínigbgbé sọ̀rọ̀
BBC News Yoruba wa nibi igbalejo fáwọn èèyàn ìlú Woro tí wọn gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ajínigbé, wọn ṣàlàyé ohun tí ojú wọn rí.
Àgbà òṣère;Kola Oyewo wọ káà ilẹ̀ sùn l'Osun
Tẹ o ba gbagbe, Oloogbe Kola Oyewo jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii lẹni ọgọrin ọdun.