Mo ti foríji gbogbo àwọn tó ṣe búburú sí mi- Gómìnà Ademola Adeleke

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti jawe olubori fun saa keji, pẹlu gbogbo rogbodiyan to koju ki ibo naa too de, Imọlẹ bi wọn tun ṣe maa n pe e ti ni oun ti foriji gbogbo awọn to ṣe buburu si oun lasiko naa.

Gomina Adeleke sọrọ yii loni Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, lasiko to tẹwọ gba iwe aṣẹ mo yege lẹẹkeji lọwọ ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun.

"Oni ni inu mi dun julọ, mo tẹwọ gba iwe mo yege fun ipo gomina Osun lẹẹkeji, mo ti dari ji gbogbo awọn to ṣe aburu si mi.''

Bẹẹ ni Gomina Ademola Adeleke fi idunnu ṣalaye ọrọ.

"Gbogbo ọna ni awọn alatako gba lati gbe mi ṣubu, ṣugbọn Ọlọrun mu mi bori"

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Ademola Adeleke ṣalaye iji to ja, bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣe sa gbogbo ipa wọn lati ri i pe idibo naa ko kẹsẹ jari.

O sọ nipa bi wọn ṣe wa gbogbo ọna ti oun yoo fi lulẹ ninu idibo to waye lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, amọ ti Ọlọrun fi ajulọ han wọn.

"Mo dupẹ pupọ lọwọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ọsun fun atilẹyin ti wọn se fun mi lati ri i daju pe mo jawe olubori ninu idibo naa.

"Bakan naa ni mo si dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu naa fun ipa alaafia ti wọn ko.

"Mo n fi asiko yii da gbogbo eeyan ipinlẹ Osun loju pe mi o ni i ja yin kulẹ ni saa keji yii naa. Ma a tun dẹrin-in pa ẹẹkẹ yin si i ni."

Bẹẹ ni Gomina Ademola Adeleke wi.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn oṣiṣẹ ijọba Osun paapaa yoo kun fun ayọ ni saa keji yii, nitori oun yoo mu tiwọn ro si i.

Ninu ọrọ ti Kọmiṣanna ajọ eleto idibo INEC l'Osun, Oluwatoyin Babalola, sọ nibi eto ti gomina ti gba iwe ẹri mo yege naa lo ti fi ẹmi imoore han si bi eto idibo naa ṣe lọ ni alaafia.

O waa rọ gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu to ku lati fi aaye gba alaafia, ki eto idibo apapọ to n bọ ni ọdun 2027 naa le lọ ni irọwọrọsẹ.