You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn wo ni ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Black Axe' tí ọlọ́pàá àgbáyé mú fún jìbìtì orí ayélujéra káàkiri àgbáyé àti ní ìwọ̀ oòrùn Africa? Àlàyé rèé
Ẹka ọlọpaa agbaye ta a mọ si International Criminal Police Organization (Interpol), ti nawọ gan eeyan mejidinlaadọta (58) ti wọn pe ni onijibiti ori ayelujara.
Awọn ọlọpaa Interpol mu awọn eeyan naa ninu iṣẹ kan ti wọn doju rẹ kọ awọn ẹgbẹ ọdaran kaakiri Iwọ-Oorun Africa (West Africa).
Wọn fi kun un pe iṣẹ naa gba awọn to oṣu mẹjọ lati tọpinpin awọn orilẹede tawọn onijibiti naa wa, lapapọ, afurasi ẹtalelọgọtalenigba (263) ni wọn darukọ.
Orukọ ti wọn pe iṣẹ itọpinpin ọhun ni 'Operation Jackal IV', o si gba wọn lati oṣu Kọkanla ọdun 2025 si oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Bakan naa ni Interpol sọ pe itọpinpin naa waye lati fopin si kikowo jọ lọna eru fi ṣe nnkan ti yoo da bii pe otitọ ni wọn fi gbe e kalẹ (Money laundering).
Gbigba awọn nnkan ti wọn fi eru ko jọ, ati ṣiṣẹ atilẹyin fun igbẹjọ.
Wọn darukọ ẹgbẹ okunkun Black Axe (Aake dudu) to wa lati Naijiria bii ọkan lara awọn ẹgbẹ okunkun to wa nidii jibiti ayelujara yii.
Ki ni Interpol sọ pe awọn tọwọ ba naa ṣe gan-an ati ọna ti wọn n gba ṣiṣẹ wọn?
Iṣẹ iwadii ti wọn fi ko orilẹede mejilelogun jọ lati kọntinẹnti mẹfa ni Interpol sọ pe o jẹ esi si idunkooko to kari aye, eyi to jẹ latọdọ awọn Black Axe atawọn ẹgbẹ bii wọn lo ti n wa.
Ọlọpaa agbaye sọ pe awọn ikọ ọdaran yii ni wọn wa nidii jibiti ayelujara kari aye.
Ọna ti wọn ni awọn ikọ ọdaran yii n gba ṣiṣẹ wọn ni:
"Ọrọ ìfẹ́, okoowo ayelujara (cryptocurrency) ati fifi idokowo lu jibiti, lilo lẹta email atawọn ilana jibiti gbogbo to le to si le mu jagidijagan dani."
Gẹgẹ bi Interpol ṣe wi, Operation Jackal IV jẹ ki wọn ṣawari awọn ilana tuntun ti wọn fi n lu awọn eeyan ni jibiti.
Awọn ọlọpaa naa tun sọ pe iwadii awọn fi han bawọn onijibiti ori ayelujara ṣe n fi ibalopọ mu awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju mẹrinla lọ.
" Wọn yoo ba awọn ọmọde naa dọrẹẹ lori ayelujara, wọn yoo si pada fipa mu wọn lati fi fọto ihoho wọn ranṣẹ, wọn yoo wa maa dunkooko mọ won pe awọn yoo pin in ka, abi bi ọmọ naa ba sanwo."
Bẹẹ ni Interpol ṣalaye ninu atẹjade rẹ.
Awọn orilẹede wo ni Interpol fọwọ ba?
Orilẹede érindinigba (196) ni Interpol n ṣakoso, iṣẹ wọn ni lati ran awọn ọlọpaa awọn ilu naa lọwọ ninu iṣẹ wọn.
Gẹgẹ bi Adari "Interpol Financial Crime and Anti-Corruption Centre", Tomonobu Kaya, ṣe wi, ni Argentina, eeyan 196 ni wọn lo lọwọ ninu iwa ọdaran to le
Ni South Africa, ibi meje ni wọn wọ ni Johannesburg, ti wọn ni ikọ to n fi ifẹ lu jibiti ni wọn.
Wọn de Italy naa, nibi ti wọn ti mu ẹnikan lori ẹsun pe o n lo ileeṣẹ Shell lu jibiti.
"Akanti kan ṣoṣo n gba EUR 845,000 (USD 736,000) kaakiri idokowo 560 , o si n lo awọn irinṣẹ okowo ogun (20) ti ko jọ ara wọn "
Bẹẹ ni Interpol sọ ninu atẹjade rẹ
Ni Romania, ọlọpaa mu eeyan mọkanla, wọn gba EUR 330,000 (USD 379,000) kiṣi lọwọ wọn, owo cryptocurrency, ati ile mẹfa pẹlu awọn aago olowo iyebiye.
Awọn orilẹede ti wọn kopa ninu iṣẹ yii ni: Austria, Argentina, Australia, Canada, Côte d'Ivoire, France, Germany, Indonesia, Ireland, Italy, Japan, Malaysia, Netherlands, Nigeria, Portugal, South Africa, Spain, Sweden, Switzerland, United Arab Emirates, United Kingdom ati America.
Awọn wo ni Black Axe gan-an?
Orilẹede Naijiria ni wọn ti da ẹgbẹ Aake Dudu (Black Axe ) silẹ, bo tilẹ jẹ pe o ti di ẹgbẹ to kari agbaye bayii.
Awọn Neo Black Movement (NBM) lo da a silẹ ni Yunifasiti Benin lọjọ keje, oṣu Keje ọdun 1977. (7-7-77).
Lọjọ naa ni awọn akẹkọọ mẹsan-an kan ti Nicholas Idemudia, lewaju wọn, da ẹgbẹ Neo Black Movement silẹ.
Wọn lo da lori jija fun igbiyanju ilẹ Africa, wọn si mu aake dudu ṣe ami idanimọ, wọn ni awọn fi bẹ imunisin danu.
NBM gbilẹ pupọ lawọn yunifasiti Naijiria lawọn ọdun 1980 soke, awọn alakooso rẹ ro o pe kawọn da pọ mọ Neo Black Movement of Africa, wọn n pe ara wọn ni ẹgbẹ to wa fun ododo adulawọ ati ipinnu.
Ẹyi lo bi ẹgbẹ to yapa lara wọn ti wọn n pe ni Black Axe lonii, ti wọn da silẹ ni nnkan bii ọdun 1994.
Black Axe mu awọn nnkan mi-in mọ tiẹ, to jẹ kawọn kan maa pe e ni ẹgbẹ okunkun.
Wọn fi ipa kun tiwọn, awọn ọkunrin to sanngun ni wọin si n gba, bẹẹ ni wọn ni ẹgbẹ awọn yoo kan maa pa eeyan fun idajọ ododo ni, awọn o ni i pa alaiṣẹ.
Bi Black Axe ṣe n dagba si i ni iwa iparẹ n pọ si i.
Nigba ti yoo fi di 2008, awọn ọmọ ẹgbẹ Black Axe ti le ni ẹgbẹrun kan, wọn kan fun awọn to kawe lọkunrin.
Ni 2024, NBM of Africa kede pe oun ki i ṣe ara Black Axe mọ, wọn si le ọmọ ẹgbẹ to to aadọta (50), titi kan awọn merin ti wọn ti jẹ aarẹ NMB apapọ ri danu
Ami idanimọ wọn
Ami idanimọ Black Axe wa lati ara NBM, oun naa si ni aake to wa lori ọwọ meji ti wọn de ṣẹkẹsẹkẹ mọ.
Bii NBM, awọ tiẹ naa ni funfun, dudu ati ofeefe (White Black ati Yellow."
Iṣejọba wọn:
Alufaa
Alaga
Oju– awọn lo maa n ṣọ ọlọpaa bi wọn ba n ṣeto igbaniwọle tabi orò mi-in
Akede – Awọn ni wọn fi eto to ba wa to ara wọn leti.
Alapata:Awọn ni wọn n ri I pe ofin fẹsẹ mulẹ, fiya jẹ ọmọ ẹgbẹ to ba ṣẹ, ba alatako ja
Iwa ọdaran ori ayelujara
Loṣu Kẹwaa ọdun 2021, ọmọ ẹgbẹ Black Axe mẹjọ bọ sọwọ lori jibiti ayelujara to ni I ṣe pẹlu ọrọ ifẹ
Ni 2023,wọn mu ọmọ ẹgbẹ Black Axe kan fun jiji miliọnu kan dọla nipasẹ kikojọ lọna eru
Ipaniyan
Iroyin sọ pe o kere tan, eeyan 53 farapa tabi ki wọn ti ku ninu ija ẹgbẹ Black Axe ati ẹgbẹ Ẹiyẹ to je alatako wọn.
Eyi waye losu kẹta odiujn 2009 si oṣu Kẹfa 2013.
Ọjọ kẹwaa oṣu Keje 1999, ogoji ọmọ ẹgbẹ Black Axe wa mọto lọ si yunifasiti Obafemi Awolowo, n'Ile Ife, wọn mu ibọn dani, wọn n darukọ awọm eeyan kan, wọn n sọ pe "Faro, jade to ba jẹ ọkunrin ni ọ, to ba jẹ baba rẹ lo bi ọ.
Eeyan marun-un ni wọn pa lọjọ naa bi akọsilẹ ṣe sọ.