You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ Ààrẹ NFF, Ibrahim Gusau
O ti to igba diẹ ti nnkan ko ti fararọ lagbo ajọ to n ri si bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, NFF, to bẹẹ ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Ibrahim Gusau, ti kọwe fipo silẹ bayii.
Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni Gusau kede pe oun ko ṣe mọ niluu Abuja.
Ṣaaju ikọwefiposilẹ rẹ ni awọn agbabọọlu ọkunrin Naijiria ti kuna lati pegede fun idije ife Ẹyẹ Agbaye to kọja, eyi ti ko dun mọ awọn ọmọ orilẹede yii ninu.
Ikọ agbabọọlu obinrin (Super Falcons) to raye de idije awọn obinrin ti a mọ si (WAFCON) ni Morocco laipẹ yii naa ko rin pupọ ti wọn fi ja ninu idije naa.
Ikọ agbabọọlu Cameroon lo ja wọn bọ nipele kẹta si aṣekagba.
Awuyewuye ọrọ owo
Nnkan miran to tun mu awuyewuye waye fun ajọ NFF ni ọrọ owo tijọba ni ki ajọ naa san gẹgẹ bii ajẹsilẹ gbese fawọn agbabọọlu kan atawọn akọnimọọgba.
Ọna ti wọn n gba fi ṣakaso NFF tun jẹ nnkan miran to n mu awuyewuye wa pẹlu.
Owo kan pato ti ẹnu fi kun NFF ju ni 17bn naira ($12.66m, £9.31m), owo ti Aarẹ Tinubu ti buwọlu lati oṣu Kin-in-ni ọdun 2024 lati fi san ajẹsilẹ gbese ajọ naa.
Igbimọ oluwadii kan wa ti NFF gbe kalẹ lẹyin ti awọn agbabọọlu obinrin Naijiria ja kulẹ ninu idije WAFCON 2026, wọn ti n gbe awọn idi kan kalẹ fun ajọ naa bayii lẹka ipilẹ ati ti apapọ.
Lara ohun ti igbimọ naa n tọka si ni pe awọn alakooso NFF maa n ṣe ojuṣaaju.
Wọn ni owo ti wọn n gba lo jẹ wọn logun ju bi ẹni ti wọn fẹ ko gba bọọlu ṣe daa si lọ.
Bẹẹ ni ipe n wa lọtun-un losi pe ki atunto ba NFF, ki wọn jawe gbele ẹ tabi lọ rọ ọ kun nile fawọn to n ṣakoso ajọ naa.
Wọn ni iṣẹ wọn n mu ijakulẹ ba awọn agbabọọlu Naijiria, o si n mu ibanujẹ ba awọn ololufẹ ere idaraya naa lorilẹede yii.
John Obi Mikel, Jay-Jay Okocha ati Segun Odegbami ti gbogbo wọn jẹ agba ninu ere bọọlu, wa lara awọn to ni afi ki wọn paarọ awọn to n dari NFF ni nnkan fi le yipada.
Lori rẹ naa ni wọn wa ti Gusau fi kọwe fipo silẹ, to kuro nipo Aarẹ NFF.
Ohun ti awọn eeyan Naijiria n beere ti wọn si n foju sọna fun bayii ni bi ayipada rere ti kaluku n fẹ lagbo ere bọọlu alafẹsẹgbe yoo ṣe de, ati igba ti yoo jẹ pẹlu.
Nnkan bii oṣu kan lo ku fun Ibrahim Gusau lati pari saa iṣakoso rẹ, o si kede nibi ipade oniroyin kan l'Abuja l'Ọjọbọ pe oun ti fipo naa silẹ.
Aarẹ tẹlẹ fun NFF naa sọ pe oun pinnu lati fipo silẹ lẹyin toun ba awọn ẹbi, ọrẹ atawọn tọrọ kan sọrọ lori igbesẹ naa.
Oṣu Kẹsan-an ọdun 2022 ni wọn dibo yan Gusau gẹgẹ bii aarẹ NFF, awọn eeyan si ti n naka aleebu si i nipa iṣakoso rẹ tipẹ.
Amọ Gusau naa sọrọ, o ni:
"Nigba ta a gba ami ẹyẹ Bàbà (Bronze) ni Morocco, awọn eeyan o sọrọ nigba yẹn nitori wọn ri ireti.
"Mo le fọwọsọya pe mo kopa ninu aṣeyọri naa."
Gusau sọ nibi ipade naa pe bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ oriṣiriṣi to wu wọn nipa oun, o loun mọ pe o ni awọn ohun toun naa ṣe lati mu nnkan da fun bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria.