You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn orílẹ̀èdè Afrika tí Amẹrika kéde pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí àǹfààní ìgbà díẹ̀ tí wọ́n ní láti gbé ní US mọ́
Eto kan wa ti wọn n pe ni Temporary Protection Status (TPS), eyi to maa n fun awọn ọmọ orilẹede mi-in ti wọn gbe nilẹ okeere ni anfaani ati aabo lasiko ti nnkan ko ba rọgbọ mọ ti wọn si n le awọn ti ko ni iwe igbeluu kuro lorilẹede kan.
Awọn to ba ni anfaani TPS yii maa n ni ẹtọ lati ṣiṣẹ niluu naa, wọn si ni anfaani ati ri irinajo wọle jade nigba ti ofin ti fọwọ si gbigbe ilu naa fun wọn.
Bo tilẹ jẹ pe TPS yii ko sọ wọn di ọmọ oniluu tabi ẹni to le maa gbebẹ titi lai, sibẹ, anfaani nla ni fun ẹni to ba ni i.
Anfaani yii ni ijọba orilẹede America ti wa fi opin si fawọn orilẹede Africa kan bayii.
Alaye America lori ipinnu rẹ
Idi pato ti America fi fopin si TPS bi Kristi Noem, Akọwe to n ri si ọrọ yii lorilẹede America tẹlẹ ṣe ṣalaye, ni pe awọn orilẹede naa ko kunju oṣuwọn mọ lati maa jẹ anfaani eto naa lọ.
Amọ won fi kun alaye naa pe opin to de ba TPS fawọn orilẹede yii ko tumọ si pe wọn yoo sare ti awọn eeyan naa jade lati pada si orilẹede wọn.
America ṣalaye pe o ṣee ṣe ki ẹlomi-in ninu awọn tọrọ kan tun ni ẹtọ miran to le da aabo bo gẹgẹ bii ajeji, ti yoo si le duro fun asiko kan.
Bakan naa ni wọn ni awọn kan wa to jẹ kootu yoo dajọ lorii rẹ ki ijọba too gbe igbesẹ lorii wọn.
Iru awọn yii ni orilẹede Ethiopia, ti idajọ ile ẹjọ apapọ kan da duro titi di oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, ni Massachusetts.
Iru rẹ naa tun ni eyi to kan awọn ilu bii Honduras, Nepal ati Nicaragua.
Awọn orilẹede to kan
Ijọba Aarẹ Donald Trump kede pe lẹyin ayẹwo finni-finni ati ijiroro laaarin awon ẹka ijọba, awọn ọmọ orilẹede bii :
- Somalia
- South Sudan
- Cameroon
- Ethiopia to n gbe l'America ko ni anfaani si TPS mọ
- Awọn wọnyi ni afikun tuntun tie to naa ṣẹṣẹ kan
Ni ti Somalia, ọjọ kẹrinla oṣu Kẹjọ yii ni won ni anfaani naa dopin fawọn eeyan rẹ to n gbe l'America.
Ti South Sudan ni tiẹ bẹrẹ lọjọ keje oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Awọn orilẹede mi-in ti wọn ti gba anfaani yii kuro lọwọ wọn
- Haiti
- Syria
- Yemen
- Afghanistan
- Venezuela ati
- Myanmar