Bí o ṣe lè di olówó gọbọi nípa títú àṣírí àwọn tó ń jí owó ìlú kó lọ sókè òkun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti kede eto ti araalu le fi maa ta awọn lolobo nipa iwa jbibi mki awọn araalu le gba owo gọbọi.

Wọn ni eyikeyi araalu to ba janfani eto naa le di olowo gọbọi latari ere ti yoo gba ti ijọba ba gba owo naa tan lọwọ awọn to ji ko.

Alaga ajọ ọhun, Ola Olukoyede, lo sọrọ naa nibi ipade International Symposium on Economic Crime to waye ni Cambridge, nilẹ Gẹẹsi.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹnikẹni to ba fun awọn ni iroyin ti yoo ran wọn lọwọ lati gba owo ilu ti awọn kan ba ji ko lọ silẹ okeere pada, ẹni naa le ri ida 2.5% si ida 5% apapọ owo naa gba gẹgẹ bii ere lati ọdọ ijọba.

O ni o jẹ iwuri ti ijọba ṣe fun awọn eeyan lati le jẹ ki wọn maa tu aṣiri awọn to n ji owo ilu kọ nipa tita awọn lolobo.

Amọ ṣa, ko sọ boya eto yii yatọ si eyii ti wọn ti kede ṣaaju laye ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Lọdun 2016 ni Buhari kede pe ere ida marun un apapọ owo ti ijọba ba gba pada ni yoo jẹ ti ẹni to ba ta EFCC lolobo.

Minisita eto iṣuna lasiko naa, Kemi Adeosun, sọ pe eto naa yoo waye ni ifọwọsowọpọ ileeṣẹ ọhun ati ileeṣẹ eto idajọ.

O sọ lọdun naa pe eto ọhun yoo maa lọ titi ti ile igbimọ aṣofin yoo fi sọ ọ di ofin.

Lara awọn ofin to rọ mọ ni ki iroyin ti eni to n ta ijọba lolobo jẹ eyii ti ijọba ko mọ nipa rẹ tẹlẹ.

Elo ni ijọba ti gba pada nipa awọn to ta EFCC lolobo?

Fun ọpọ ọdun ni ijọba ti n kede oniruru iye ti wọn ri gba pada latari awọn to ta a lolobo.

Lọdun 2018, Buhari sọ pe ijọba oun ti gba owo to le ni 500b naira pada latari awọn to n sin awọn ni gbẹrẹ ipakọ.

Ni 2017alaga ajọ EFCC lọdun naa lọhun sọ pe owo to le ni 739b naira ni wọn ri gba pada laarin ọdun 2015 si ọdun 2017 labẹ jọba Buhari.

Laye kemi Adeosu gẹgẹ bii minisita eto iṣuna, apapọ owo ti iye rẹ to 143b naira ni ijọba ni awọn gba pada latari awọn to ta ijọba lolobo.

Nigba ti yoo di ọdun 2024, minisita eto iṣuna, Wale Edun kede apapọ owo ti ijọba gba pada laarin ọdun 2017 si 2023, awọn owo naa ree:

  • Naira - 83,019,178,375.86
  • Dollars - 609,083,391.91
  • Euros - 5,494,743.71

Elo ni ijọba ti san fun awọn to ta a lolobo?

Ninu atẹjade kan lọdun 2017, Kemi Adeosun sọ pe apapọ owo ti iye rẹ to 375.8m naira ni ijọba san fun ogun eeyan to ta oun lolobo.

O ni olobo ti awọn eeyan naa ta ijọba ran an lọwọ lati ri owo to le ni 11.6b naira gba pada.

Nigba ti yoo fi di ọdun 2018, owo to le ni 439.3m naira ni ijọba san fun eeyan mẹrinla to ta a lolobo.