Èèmọ̀! Ọmọ wòlíì f'orúkọ wòlíì míràn lu jìbìtì, gba ₦18m lọ́wọ́ àwọn tó ń wá ojútùú sí ìṣòro ayè wọn lórí ayélujára

Adewale Ogoemi Arojah, afurasi to fi orukọ Pasitọ Muyiwa Akogun lu jibiti loju opo Facebook
Àkọlé àwòrán, Adewale Ogoemi Arojah, afurasi to fi orukọ pasitọ mi-in lu jibiti
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun ẹsun pipe ara rẹ ni ohun ti a ko jẹ, fifi orukọ olorukọ lu jibiti owo to to miliọnu mejidinlogun naira (18m), ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ẹka ti ilu Ilaro ti fọwọ ofin mu Adewale Ogoemi Arojah, ẹni ti wọn ni pasitọ ni baba rẹ, amọ to n fi orukọ pasitọ miran lu jibiti owo lori ayelujara.

DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fi atẹjade to kede iṣẹlẹ yii sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii.

Alukoro sọ pe oju opo Facebook ni Arojah ti n purọ fawọn eeyan to ni iṣoro kan tabi meji, to n pe ara rẹ ni Pasitọ Muyiwa Akogun ti iyẹn jẹ wolii to gbajumọ, to si lo orukọ rẹ fi gba miliọnu mejidinlogun naira.

Bawo ni aṣiri sẹ tu?

Gẹgẹ bi DSP Babaseyi ṣe ṣalaye, Muyiwa Akogun tawọn eeyan mọ si "Prophet Dr. Muyiwa Akogun," lori Facebook, lo mu ẹjọ lọ si tẹsan lọjọ kẹta oṣu Kẹwaa yii.

Pasitọ Akogun ṣalaye fawọn ọlọpaa, pe awọn eeyan ti n sọrọ lori owo nla ti ẹnikan n gba lọwọ wọn lorukọ Muyiwa Akogun.

O ni ẹni naa ṣi oju opo Facebook ayederu, o si pe orukọ rẹ ni Muyiwa Akogun, bẹẹ lo n fi orukọ naa gbowo lọwọ awọn eeyan pẹlu ẹtan, to n sọ fun wọn pe oun yoo ba wọn gbadura, oun yoo ba wọn ṣẹgun aye wọn.

Eyi ni awọn ọlọpaa ilu Ilaro ṣiṣẹ tọ, wọn si bẹrẹ si I wa bi wọn yoo ṣe mu ayederu Muyiwa Akogun naa.

Abule kan nitosi Ajegunle, lagbegbe Ilaro/ Ibogun ni wọn ti pada ri i mu bi DSP Babaseyi ṣe ṣalaye.

Afurasi jẹwọ

Atẹjade ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe lasiko tawọn agbofinro n fi ọrọ wa Arojah Ogoemi tọwọ ba lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun n lo orukọ Pasitọ Akogun loju opo Facebook.

Wọn ni Arojah jẹwọ pe oun n lo orukọ Pasitọ Akogun lati jiṣẹ èké ati asọtẹlẹ irọ.

O ni oun n lo orukọ naa fi ṣeto adura fawọn eeyan to ni iṣoro, nipasẹ eyi lo ni oun fi n gbowo lọwọ wọn nilẹ yii ati loke okun.

Iwadii ọlọpaa fi han, pe Arojah maa n dọdẹ awọn to n bẹbẹ adura loju opo Pasitọ Muyiwa Akogun, yoo bẹrẹ si I ba wọn sọrọ, nibẹ lo si gba wọle si ọpọlọpọ wọn lara lori ayelujara to si gba 18m lori irọ.

Ṣaa, wọn ti taari rẹ si ẹka to n wadii iwa ọdaran, eyi to wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Eleweeran l'Abeokuta.