"Àwọn àgùnbánirọ̀ 20 Oyo tí wọ́n jí gbé ní Imo ti gba ìtúsílẹ̀"-Olubadan Ladoja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe awọn agunbanirọ ogun ti awọn ajinigbe da lọna ti wọn si gbe lọ nipinlẹ Imo lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ti gba itusilẹ.
Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, fidi ọrọ naa mulẹ ninu ọrọ to ba Olubadan ilẹ Ibadan,Ọba Rashidi Ladoja sọ lori ẹrọ ibanisọrọ.
Oni Ọjọru, ọjọ keje oṣu Kẹwaa ni iroyin itusilẹ naa gbode lọwọ irọlẹ, nnkan bii aago marun-un irọlẹ si ni Uzodinma ba Olubadan sọrọ bi a ṣe gbọ.
Atẹjade lati aafin Olubadan tun fidi itusilẹ awọn agunbanirọ naa mulẹ
Yatọ si ọrọ ori aago ti Gomina ipinlẹ Imo ati Olubadan Rashidi Ladoja sọ, Aafin Olubadan paapaa tun fi atẹjade sita lori itusilẹ awọn agunbanirọ naa.
Akọwe iroyin Olubadan; Adeola Oloko lo fi atẹjade to kede itusilẹ naa lede nirọlẹ Ọjọru.
Bakan naa ni BBC News Yoruba sare ba ọkan lara awọn obi ti ọrọ naa kan sọrọ bi iroyin yii ṣe gbode, wọn si fidi rẹ mulẹ pe òdodo ni, awọn ọmọ naa ti gba itusilẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ayajọ Ominira Naijiria ti ọdun 2026 yii lo n lọ lọwọ, ti iroyin fi jade pe awọn ajinigbe ti ji awọn agunbanirọ to n lọ sinru ilu lati ipinlẹ Oyo gbe ni ipinlẹ Imo.
Ominira ti wọn gba yii lo n waye lẹyin ọjọ keje ti wọn ti wa nigbekun, ti awọn ajinigbe naa si ti kọkọ ni awọn yoo gba biliọnu kan owo itusilẹ, ki wọn too tun din I ku si miliọnu marun-un fun ẹnikọọkan wọn.
























