Àlàyé lórí i bí ẹ̀ṣọ́ Amọtẹkun, àjọ DSS àti àpapọ̀ ọmọ ogun ṣe gbẹ̀mí adarí ISWAP nílùú Owo l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Channels TV
Apapọ ajọ eleto aabo Naijiria ti ṣekupa ọkan gboogi lara awọn olori ikọ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP), Abdussamad Ohida ninu igbo kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ajọṣepọ laarin ikọ ileeṣẹ ọmọ ogun, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ati ikọ Amọtẹkun lo mu ki iṣẹ naa ṣeeṣe.
A gbọ pe ọdaran naa, Ohida, ti inagijẹ rẹ n jẹ Anwar n mura lati ṣe akọlu si awọn ipinlẹ kan ṣaaju ki awọn ẹṣọ eleto aabo to ṣẹ egungun rẹ toun ti awọn ẹmẹwa rẹ ninu ibuba wọn.
Ṣaaju iku rẹ, Ohida yii ni igbakeji Abu Ikrimah, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Uwais, to jẹ olori ISWAP ni aringbungbun Naijiria ki ọwọ ajọ DSS to tẹ ẹ lọdun 2023.
Lẹyin ti ọwọ tẹ Ikrimah tan ni Ohima goke agba to si di olori ikọ agbesunmọmi naa ni ni apa ariwa ilẹ Afrika ati awọn ipinlẹ kan ni Naijiria.
Ninu iwadii ajọ DSS ni Abu Uwais ti fidi rẹ mulẹ pe wọn n gbimọ lati ṣe awọn ikọlu kan lasiko ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, erongba ẹgbẹ agbesunmọmi naa ni lati da ilu ru lasiko ọdun, ki wọn tun tẹsiwaju lati da eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 ru pẹlu.
A gbọ pe Ohida yii kan naa lo wa nidi ikọlu kan ti wọn ṣe si agọ ọlọpaa ilu Ipele, lẹba ilu Owo lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2025, nibi to wọn ti ji awọn ibọn AK-47 lọ ti wọn si tun fi ado olowo wo agọ ọlọpaa ọhun lulẹ.
Awọn ikọlu mii ti a tun gbọ pe ọdaran naa ṣe onigbọwọ rẹ ni ikọlu oju ọna Suleja–Zuba nipinlẹ Niger lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, odun 2022 nibi ti ọpọlọpọ ọmọ ogun ati araalu ti pade iku ojiji.
Ki lo ṣẹlẹ lasiko ikọlu si ibuba agbesunmọmi naa?
Awọn olugbe ilu Owo to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye ohun ti oju wọn to ṣaaju ikọlu awọn ologun si ibuba agbesunmọni naa.
Obrinin kan ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede to n gbe nillu Owo sọ pe "Ohun ti a ṣakiyesi ni pe gbogbo nẹtiwọọki ori ẹrọ ilẹwọ wa lo salọ bẹrẹ lati alẹ ọjọ Ẹti titi di afẹmọju ọjọ Abamẹta.
"Ko si nẹtiwọọki lori MTN, Glo ati Airtel wa, awa n woye pe o ni nnkankan to n ṣẹlẹ nitori kaayefi lo jẹ fun wa pe nẹtiwọọki salọ lori gbogbo ila naa.
"Yatọ si nẹtiwọọki to salọ, a tun ṣakiyesi pe awọn ọmọ ogun kan n korajọ si awọn igun to ṣe pataki ninu ilu, paapaa lawọn orita to wọ ilu.
"Ohun ti a ṣakiyesi niyẹn ko to di pe a gbọ iroyin iku ọkunrin naa, a si dupẹ lọwọ ijọba atawọn agbofinro fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe."
Moki awọn ọmọ ogun wa ku iṣẹ takuntakun – Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Amọtẹkun Ondo
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ti kan sara si awọn ọmọ ogun fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati rẹyin agbesunmọmi naa.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun ọrọ to n lọ, Idowu Ajanaku, fi lede, o ni Aiyedatiwa ki gbogbo ikọ agbofinro to lọwọ ninu iṣẹ ọhun ku iṣẹ takuntakun.
O ni "Bi wọn ṣe pa olori ẹgbẹ agbesunmọmi yii n ṣafihan pe awọn ẹṣọ alaabo wa yoo ṣe ọpọ aṣeyọri ti wọn ba fọwọsowọpọ pẹlu ara wọn.
"Mo gboriyin fun ileeṣẹ ọmọ ogun, DSS ati ikọ alaabo Amọtẹkun fun ọkan akin ti wọn ṣe ati bi wọn ṣe tete jara mọ iṣẹ naa lai fi akoko ṣofo lori rẹ."
O pari atẹjade naa pe ijọba Aiyedatiwa ko ni la oju rẹ silẹ fun awọn ẹni ibi ti da alaafia ipinlẹ naa ru.

























