'A kò tíì ri ara bàlúù náà gan, awakọ̀ bàlúú yìí ni ì bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó - Gómìnà Lucky Aiyedatiwa
'A kò tíì ri ara bàlúù náà gan, awakọ̀ bàlúú yìí ni ì bá lè sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó - Gómìnà Lucky Aiyedatiwa
Published
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ti ṣalaye wi pe, ko tii si ẹni tii ri rara baluu ologun to ja si ilu Igbọkọda lọjọ Aje, ṣugbọn iṣẹ atiṣawari ara baluu naa atawọn eeyan to ku ninu rẹ ṣi n tẹsiwaju.
Gomina Ayedatiwa sọ eyi lasiko abẹwo rẹ si ibudo iṣẹlẹ naa ninu eyi to ti kan sara si awọn to n ṣiṣẹ takuntakun lati wa ibi ti baluu naa wọlẹ si ati oku awọn to wa ninu rẹ.
O ni pẹlu bi nnkan ṣe ri lagbegbe ti baluu na ja si, o fihan pe ko si ẹni to ye iṣẹlẹ ijamba naa.
O fi kun un pe adari ikọ ọmọogun ojuomi to wa lagbegbe naa fi to oun leti pe wọn ri ẹya ara awọn eeyan kan, ṣugbọn wọn ti ṣe ifipamọ wọn nitori iwadii to n tẹ siwaju.





