Mọ̀ nípa òfin ìṣàkóso gáréèjì ọkọ̀ èrò tí Adeleke buwọ́lù l'Osun lẹ́yìn rògbòdìyàn ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò

Gomina Ademola Adeleke
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ki nnkan le ri bo ṣe yẹ ko ri lẹka awọn ọlọkọ ero nipinlẹ Osun, paapaa lẹyin gbogbo rogbodiyan to waye ninu ẹgbẹ onimọto NURTW nibẹ, Gomina Ademola Adeleke ti buwọ lu ofin tuntun ti yoo sọ iṣẹ wọn di ti igbalode.

Ibuwọlu yii ni wọn ni yoo lana fawọn atunto to ti yẹ ko waye tipẹ lagbo awọn awakọ ero naa.

Gomina Adeleke kede ibuwọlu yii ninu atẹjade to fi sita, nibi to ti ṣalaye pe igbesẹ omi tuntun lo ru lẹka irinna l'Osun bayii.

Tẹ o ba gbagbe, Gomina Adeleke ti figba kan fofin de iṣẹ awọn ọlọkọ NURTW l'Osun, latari rogbodiyan ija agba ati iṣakoso gareeji to ṣẹlẹ leralera lati ọdọ awọn awakọ naa.

Bi mo ṣe buwọ lu ofin yii, yoo bẹrẹ iṣẹ lọwọ kan ni- Adeleke

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Gomina Adeleke sọ pe ofin tuntun naa ko ni i pẹ ti yoo fi di lilo lagbo awọn onimọto, lẹyin toun ti sọ ọ di ofin wayi.

Ilu Osogbo ni Adeleke ti buwọ lu ofin ọhun lọjọ Aje, nile ijọba pẹlu alaye pe:

"Bi mo ṣe ti sọ aba yii di ofin bayii, mo fi n da gbogbo awọn to kan loju pe ẹsẹkẹsẹ la maa bẹrẹ si I ṣe amulo rẹ.

Ni ibamu pẹlu ofin yii, a maa ri i daju pe awọn eeyan Osun jẹ igbadun ilana iṣẹ tuntun to mọyan lori kaakiri Osun."

Bẹẹ ni Gomina Ademola Adeleke wi.

Ki lo fa ofin tuntun yii?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 ni ile igbimọ aṣofin Osun dabaa yii, ti wọn si fi ṣọwọ si Gomina lati buwọlu u.

Amọ ki wọn too gbe igbesẹ naa ni rogbodiyan ti waye laaarin awọn ọlọkọ ero ipinlẹ naa, lori igun ti yoo maa paṣẹ gareeji.

Ẹ o ranti pe rogbodiyan lo waye ti wọn fi yinbọn pa Emir Ajagungbade, ẹni ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Olalekan Oyeyemi.

Ologbe Emir Ajagungbade jẹ ọkan lara awọn to ṣiṣẹ fun Gomina lasiko ibo, o tun jẹ ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ Accord. Amọ wọn yinbọn pa a ni gareeji Mayfair, niluu Ile Ife.

Yatọ si Ajagungbade ti wọn yinbọn pa, awọn ọlọpaa tun ri oku ẹlomi-in nibudokọ Mayfair kan naa lasiko rogbodiyan ọhun.

Nigba to di ọjọ kẹrinla oṣu Kẹsan-an On, Gomina Adeleke fofin de ẹgbẹ NURTW l'Osun.

Lẹyin awọn ipaniyan yii ni gomina paṣẹ pe kawọn ẹgbẹ ọlọkọ to n ja ija agba yii fi gareeji silẹ, kawọn agbofinro si mu awọn afurasi ti ẹnu n kun lori ipaniyan naa.

Ṣaaju eyi ni ijọba Osun ti kọkọ fofin de NURTW lawọn ibudokọ, latari ija ti wọn n ba ara wọn ja pẹlu ẹgbẹ mi-in.

Amọ awọn olori NURTW kọ ifofinde naa, wọn si yan igbimọ alabojuto kan fun ipinlẹ naa.

Ijọba Osun naa tako igbimọ yii, wọn ni alafo kankan ko ṣi silẹ nipo adari ọlọkọ ero.

Tẹ o ba gbagbe, eeyan meji ni iroyin sọ pe wọn padanu ẹmi lasiko rogbodiyan kan to waye lagbegbe Naira and Kobo, niluu Ikire, nibi ti wọn ti n ja si igun ti yoo maa ṣe olori ati akoso gareeji.

APC tako aba ti Adeleke sọ dofin

Bi Gomina Adeleke ṣe buwọlu ofin tuntun yii, eyi ti yoo mu ki ijọba maa ri si ohun to n ṣẹlẹ ni gareeji, ẹgbẹ oṣelu APC Osun to jẹ alatako ti sọ pe ijọba ko ni agbara labẹ ofin lati maa dari iṣakoso ibudokọ.

APC sọ pe abala 7(1) ati ikẹrin ofin Naijiria sọ pe ijọba ibilẹ lo lẹtọ labẹ ofin lati ri si owo gbigba ati iṣakoso gareeji.

APC Osun sọ pe bi wọn ba bẹrẹ si I lo ofin ti Adeleke buwọlu yii, o le mu rogbodiyan waye si i.

Wọn ni ki ijọba Osun dẹkun ofin naa.

Amọ ile igbimọ aṣofin Osun ti tako eyi, wọn ni apa kan ofin ni APC n tẹnumọ.

Bi APC ba mọ pe igbesẹ gomina lodi sofin, ile igbimọ aṣofin Osun ni ki wọn gba kootu lọ.