Ohun tí a mọ̀ nípa bí odò ṣe gbé ọmọ bàbá kan náà mẹ́ta lọ

Maryam, Umar ati Hanif ninu aṣọ ile-ẹkọ wọn
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lọjọ ti gbogbo ọmọ Naijiria n ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọjọ igbominira, ni awọn idile kan yoo maa ranti ọjọ naa gẹgẹ bi ọjọ ibanujẹ fun wọn.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 jẹ ọjọ manigbagbe fun awọn mọlẹbi kan niluu Abuja, pẹlu bi wọn ṣe padanu ọmọ mẹta lẹẹkan naa, ninu ijamba omi to gbe wọn lọ.

Maryam, ọmọ ọdun mejila; Umaru, ọmọ ọdun mẹwaa, ati Hanifa toun jẹ ọmọ ọdun mẹjọ ni awọn mẹtẹẹta ti odo gbe lọ lagbegbe Kuje.

Agbegbe ti wọn n pe ni El-Rufai Housing Estate to wa ni Kuje la gbọ pe awọn ọmọ naa n gbe pẹlu baba wọn, Ayaworan-ile Aliyu Abubakar.

Ohun ti a gbọ ni pe asiko ti awọn akẹkọọ wa ni isinmi, ni ijamba naa waye, nigba ti wọn sọ pe kekere inu wọn lo jabọ sodo, ti awọn yooku si n gbiyanju lati doola ẹmi rẹ.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Baba awọn ọmọ naa, Abubakar sọ fun BBC pe gbogbo awọn ọmọ lo wa nile, nitori pe isinmi wa lọjọ naa fun gbogbo oṣiṣẹ.

O ni awọn ọmọ oun n lo asiko naa lati maa ṣere ninu ile, ati pe nigba to ya, ni wọn sọ fun mama wọn lati gba wọn laaye, ki wọn lọ ṣere nita.

O ni iya wọn ko gba wọn laaye, ṣugbọn nigba ti wahala naa pọ, lo jẹ ki mama wọn ran wọn niṣẹ lọ si adugbo keji si wọn.

"Mama wọn ko faaye gba wọn lati jade kuro ninu ọgba inu ile, igba to ya, lo ran wọn niṣẹ lọ si Freedom Estate lati ra 'Kunun Aya' wa…Wọn rin irin irinwo mita lọ si odo to wa lẹyin adugbo wa," Baba awọn ọmọ naa sọ bẹẹ.

"Ọmọ kekere ọbinrin lo bẹrẹ sii sunmọ ibi odo naa to ti kun nitori ojo to rọ ṣaaju ọjọ iṣẹlẹ naa.

"Ọmọdebinrin lọ si ayika odo yii lati ṣere, nigba ti awọn yooku ko sunmọ ibẹ lati ṣere…Lojiji ni ẹgbọn rẹ ọkunrin ṣakiyesi pe ọmọ naa ti n ri sinu odo, leyi to jẹ ki awọn yooku sare lọ, lati ṣe iranwọ.

Bo ṣe wọnu odo naa tẹle, lo dii lọwọ mu lati fa a jade, ṣugbọn ti odo naa fa a mọ-ọn lọwọ. Ọọkan ni ọmọ mi obinrin to dagba ju ti n wo wọn.

"Oju ẹsẹ loun naa ti sare lọ, nigba to ri ohun to ṣẹlẹ. Oun naa sare wọnu omi tẹle wọn nigba to rii pe odo naa ti n gbe wọn lọ, ṣugbọn si iyalẹnu, odo naa gbe awọn mẹtẹẹta lọ," Ayaworan-ile Aliyu Abubakar sọ bẹẹ.

Ìgbìyànjú láti dóòlà wọn

Ayaworan-ile Aliyu Abubakar sọ fun BBC pe kete lẹyin ti awọn ọmọ oun ri sinu odo naa, ọkunrin agbalagba kan to wa nitosi lo lọ lati ṣe iranwọ fun wọn.

"Ọkunrin kan wa nitosi to n ṣe ere idaraya lọwọ, oun lo sare lọ sibẹ lati di ọwọ ọmọbinrin mi mu, ṣugbọn gẹgẹ bi agbalagba ti ko le wẹ iwẹ inu odo, niṣe lo juu lọwọ silẹ."

Ṣugbọn o pe awọn eeyan to wa nitosi fun iranwọ nigba to de bẹẹ. Awọn eeyan to wa nibẹ gbiyanju lati wa wọn, ṣugbọn sibẹ, pabo lo ja si.

"Laarọ ọjọ keji, a pe awọn apẹja lati Kuje ati Gwagwalada lati ṣe iranwọ fun wa, ṣugbọn titi di bi agogo marun-un irọlẹ, ni wọn too ri oku ọmọ kekere inu wọn."

Ọjọ meji lẹyin naa, wọn ri oku ọmọbinrin agbalagba inu wọn lagbegbe Payi, to wa niwaju Kwali, ipinlẹ Niger.

"Ṣugbọn fun ọmọkunrin kan yooku, wọn ko tii ri rara lẹyin bi ọjọ meje ti a ti n wa a," baba naa sọ bẹẹ.

"Mary ni aláàbò Kuraani"

Aliyu Abubakar sọ pe ọpọlọpọ ifẹ lo wa laaarin oun ati awọn ọmọ oun.

"Maryama ṣẹṣẹ pada de lati Kano ni, nibi to ti lọ kẹkọọ nipa Kuraani, latigba to si ti pada de la ti n ṣere, ti a n ya aworan.

"Inu wa bajẹ latigba ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ. Nigba ti mo gbọ iroyin iku wọn, mo sunkun gidi. Ṣugbọn Allah to fun wa lawọn ọmọ naa gba wọn lọwọ wa.

"Nigba to fi awọn ọmọ naa ta wa lọrẹ, a ko mọ wọn. Ko sọ fun wa. Oun lo mọ wọn, oun naa lo si mọ idi to fi ṣe bẹẹ.

"A dupẹ gidi lọwọ Ọlọrun fun anfaani to fun wa lati ni awọn ọmọ naa, to si jẹ ka tọju wọn de ibi ti a tọ wọn de ki ọlọjọ too de," Aliyu Abubakar ṣalaye fun BBC.