Ohun tí ìṣèjọba Tinubu ní í ṣe pẹ̀lú ikú ìyá mi - Amaechi

Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu, Rotimi Amaechi lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbakeji oludije sipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) lọdun 2027, Rotimi Amaechi, ti fi ẹsun kan Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati lọwọ ninu iku mama rẹ.

Amaechi sọ pe eto ọrọ aje ilẹ Naijiria to le koko ni ko jẹ ki oun ri owo lati ra oogun fun mama oun, ko to di pe ọlọjọ de lojiji.

Igbakeji oludije sipo Aarẹ naa to ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Rivers ati minisita feto igbokegbodo ọkọ ni Naijiria lo sọrọ yii lọjọ Ẹti to kọja lasiko to n dahun ibeere nileeṣẹ amohunmaworan Channels.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2026 ti a wa yii ni mama Amaechi, Arabinrin Ezinne Amaechi jade laye lẹni ọdun mọkandinlaadọrun-un (89).

Nigba to n sọrọ, Amaechi sọ pe "Agbekalẹ Tinubu lo pa mama mi. Ki Tinubu too de ori ipo Aarẹ, ṣaka ni ara rẹ da. Lẹyin idibo 2023, o bẹrẹ sii ṣoro fun mi lati ra oogun fun mama mi."

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Amaechi yoo maa bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Tinubu lori bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori, leyi to jẹyọ lati ara yiyọ owo iranwọ ori epo rọbii.

Amaechi sọrọ yii lẹyin ọjọ ti Aarẹ Tinubu sọrọ lasiko ayajọ ominira, eyi to fi n gbe lẹyin agbekalẹ rẹ, to si ni awọn agbekalẹ naa ti ro eto ọrọ aje lagbara.

Siwaju sii ni Amaechi tun tako owo epo to lọ soke, to si loun yoo fi ipo silẹ gẹgẹ bi igbakeji oludije sipo aarẹ, iyẹn bi owo ep oba ja wa silẹ si ẹgbẹta naira.

"To ba di ni ọla, yoo wu mi ki ẹ wa ba mi, mo maa lọ si ile-epo lati ra epo, bi owo ep oba ja wa silẹ si ẹgbẹta naira, emi Chibuike Rotimi Amaechi, maa juwọ silẹ gẹgẹ bi igbakeji oludije sipo aarẹ fun Atiku, lati ṣagbatẹru Tinubu," Amaechi sọ bẹẹ.O loun yoo fi aaye silẹ lati lọ sile epo, lati mọ iye ti wọn n ta jaala epo kaakiri awọn ile-epo.

Bakan naa lo sọ pe eto idibo ọdun 2027 yoo jẹ anfaani fawọn araalu lati yan laaarin iye ati iku.

Amaechi sọ pe "Tinubu lo duro fun iku".

Ìwà àjẹbánu lábẹ́ ìsàkóso Tinubu

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbakeji oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ADC naa tun fi ẹsun kan iṣakoso Aarẹ Tinubu wi pe o kun fun iwa ajẹbanu ju ti iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari toun ti ṣe minisita feto igbokegbodo ọkọ lọ.

Ninu ọrọ rẹ, o jẹ ko di mimọ pe, "Bi ẹ ba ṣagbeyẹwo iṣakoso mejeeji, ẹ maa lero wi pe iwa ajẹbanu ko ṣẹlẹ lasiko ijọba Buhari ni.

"Iwa ajẹbanu labẹ iṣakoso Buhari ko buru to iṣakoso ti a wa ninu rẹ yii. Njẹ ẹ mọ iyatọ bi? Iyatọ to wa nibẹ ni pe, bi ẹ ba ni iwa ijẹkujẹ lọwọ, ẹ maa tọju rẹ. Ṣe ẹ ri awọn wọnyi, wọn ko fi pamọ rara. Ohun to foju han ni."

Bakan naa, nigba to n dahun ibeere boya oun naa kopa ninu iwa ajẹbanu labe iṣakoso Buhari, Amaechi sọ pe oun ko lọwọ ninu iwa ajẹbanu.

"Mo ti sọ ọ lọpọ igba. Igba kan ti Maupe fọrọ wa mi lẹnu wo, to si beere lọwọ mi pe ṣe m oni iwa ajẹbanu? Ti mo si sọ pe rara, mo wa n duro de awọn ti yoo dide lati tako mi pẹlu ẹri," Amaechi sọ bẹẹ.

"Mo maa tun un sọ, ma si tun maa sọ ọ. Nko nii sunmọ iwa ajẹbanu. Nko nii rin ni bebe iwa ajẹbanu."

Amaechi tako Tinubu lórí iṣẹ́ ìdàgbàsókè

Bakan naa ni Amaechi tun sọ pe ki Tinubu tọka si iṣẹ akanṣe kan ṣoṣo ti iṣakoso dawọ le, to si pari rẹ latigba to ti de ori ipo aarẹ lọdun 2023.

O ni iṣakoso naa ko le ri ohunkohun lati tọka si, ati pe ko si afiwe ti wọn le fi iṣakoso Tinubu we ti Buhari toun ti ṣe minister.

"Nnkan kan ṣoṣo ti ẹ le fi da wa lẹbi ti ẹ si naa ṣagbeyẹwo rẹ ni iṣakoso naa ṣe ri, ṣugbọn nipa awọn iṣẹ akanṣe nibi lọhun, ẹ jẹ ki iṣakoso yii tọka si ohun kan ṣoṣo ti wọn ti ṣe, to fi mọ opopona ti mo gbọ pe tiriliọnu mẹtalelọgbọn naira ni wọn fẹẹ fi pari rẹ.

"Ni iru asiko yii labẹ iṣakoso Buhari, a ti pari reluwee Abuja si Kaduna. Ẹ sọ fun wọn pe ki wọn tọka si reluwee kan ṣoṣo ti wọn ti pari."