Seyi Makinde, Olubadan, sọ̀rọ̀ tuntun lórí àwọn àgùnbánirọ̀ Oyo tí wọ́n jí gbé ní Imo, àlàyé rèé

Gomina Seyi Makinde lapa osi, Olubadan Rashidi Ladoja lapa ọtun, awọn mejeeji wọ aṣọ alawọ aro.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Bi iyanju ṣe n lọ loriṣiriṣi lati gba awọn agunbanirọ ogun (20) to n lọ sinru ilu npinlẹ Imo lati ilu Ibadan, amọ ti wọn bọ sọwọ ajinigbe l'Ọjọbọ to kọja, pada, Gomina Seyi Makinde ati Olubadan Rashidi Ladoja ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Gomina Makinde ṣọ pe ijọba Oyo ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ to yẹ lati ri awọn ọmọ naa gba pada.

Ninu atẹjade ti kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade, fi sita lọjọ Aiku ni Makinde ti ṣalaye pe:

"Ijọba Oyo n ba ijọba Imo sọrọ daadaa lori iṣẹlẹ yii, a si ṣetan lati lo ilana aṣeyọri iṣẹlẹ Oriire"

Gomina Makinde sọ pe gbogbo igba ni ajọsọ n waye laaarin ijọba ipinlẹ Oyo ati ti ipinlẹ Imo lori ọro yii.

O ni awọn tun n ba awọn ẹṣọ alaabo ipinlẹ Oyo ati ti Imo sọrọ pọ pẹlu.

Atẹjade Gomina Makinde tẹsiwaju, pe ijọba Oyo ṣetan lati lo ilana ti wọn lo lasiko ijinigbe ijọba ibilẹ Oriire, ti wọn fi pada ri awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti ajinigbe gbe lọ gba pada lasiko yii.

O ni abajade iwaii iṣẹlẹ naa, eyi ti Adajọ Ọjọgbọn Mojeed Owoade, lewaju, ti wọn jabọ rẹ lọsẹ to kọja yii wulo pupọ ninu ajọsọ to n lọ lọwọ yii.

Makinde sọ pe ijọba ko le tu awọn ilana naa kalẹ fun gbogbo eeyan lati mọ, paapaa nigba to jẹ o le ṣakoba fun bawọn ọmọ naa yoo ṣe gba itusilẹ kia.

Atẹjade naa ran Aarẹ Bola Tinubu leti, pe ọsẹ to kọja yii ni Makinde ṣi n rawọ ẹbẹ sijọba rẹ, lati gba awọn ogoji akẹkọ ti wọn ji gbe lọjọ kan naa ti iṣẹlẹ ijinigbe Esienle ati Yawota waye l'Ogbomoso.

Lakootan, Makinde fi da araalu loju, pe ijọba oun yoo maa ṣiṣẹ lọ pẹlu ijọba Imo, awọn ẹṣọ alaabo ati bẹẹ bẹẹ lọ lati gba awọn agunbanirọ ti wọn ji gbe silẹ pẹlu alaafia ara.

"Ijọba yoo yanju ọrọ yii, o kan awọn naa bo ṣe kan kaluku ni- Olubadan Ladoja"

Ninu ọrọ tiẹ, Olubadan Rashidi Ladoja, sọ pe awọn agunbanirọ naa yoo pada wale, ijọba yoo yanju ọrọ naa, nitori o ka wọn lara bo ṣe ka gbogbo eeyan lara naa ni.

Ọba Ladoja sọrọ yii lasiko ti awọn obi awọn agunbanirọ naa sunkun lọ ọ ba a ni ile rẹ to wa ni Bodija, niluu Ibadan.

Atẹjade ti Akọwe iroyin Olubadan, Adeole Oloko fi sita, ṣalaye pe awọn obi naa kegbajare lọ ba Olubadan, pe ko lo agbara oṣelu pẹlu bo ṣe mọ awọn eeyan pataki, ko ṣaanu awọn, kawọn ọmọ naa le pada wale layọ.

Ọba Ladoja to gbalejo wọn pẹlu Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo; Olugbenga Abimbola, Aseyin tilu Iseyin; Oba Sefiu Oyebola Adeyeri, fi da wọn loju pe ijọba yoo yanju ọrọ yii.

" Ijọba ni yoo yanju ọrọ yii, nitori o kan awọn naa gẹgẹ bo ṣe kan gbogbo eeyan ni. "

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Wọn fi da gbogbo araalu loju pe ijọba kapa iṣẹlẹ naa, wọn si n ṣiṣẹ lori itusilẹ naa gidi.

Ọlọ́pàá ṣàwárí ibi táwọn ajínigbé káwọn Àgùnbánirọ̀ Oyo sí, ohun tó ń dáwọn lọ́wọ́ kọ́ rèé

Awọn ọlọpaa ninu igbo atawọn agunbanirọ to wọ aṣọ funfun ati sokoto khaki

Ẹkọ ti n fi ojuu mimu han fawọn ọlọpaa ipinlẹ Imo lori awọn agunbanirọ ogun (20) ti ajinigbe ji gbe l'Ọjọbọ to kọja pẹlu awọn ero ọkọ mi-in.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Audu Garba Bosso, ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti mọ ibuba awọn ajinigbe naa ninu igbo, nibi ti wọn ko awọn ti wọn ji gbe naa si nipinlẹ Imo.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹta oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni Bosso sọrọ idaniloju naa.

Kọkọrọ kan to ni o n ba eyin aja jẹ ni pe o ṣee ṣe kawọn awọn ajinigbe ọhun ti kẹ ado oloro to le bu gbamu sawọn ibi ti eeyan le gba de ọdọ wọn.

O ni òye foju han pe wọn ti kẹ ohun abugbamu IED to le fa iku sitosi.

"Ẹrọ 'drone' ti fi ibi ti wọn wa han wa ninu igbo''

Ileeṣẹ ọlọpaa ni "ẹrọ 'drone' ti fi ibi ti wọn wa han wa ninu igbo, a maa gbe katakata atawọn ọkọ akọtami lọ sibẹ lati doola awọn ti wọn ji gbe."

Ni itẹsiwaju alaye Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Audu Garba Bosso, o ni nigba tawọn ẹṣọ alaabo dọdẹ awọn ajinigbe naa ninu igbo ni wọn fi ẹrọ drone mọ ibi ti wọn wa.

"A maa pada sinu igbo nigbakigba, ana naa, a wa ninu igbo, a dọdẹ wọn debi kan, a si ri I pe wọn ti fi ado oloro yi ibuba naa."

"A n lọ sibẹ pẹlu awọn ọkọ̀ alagbara bii bulldozer atawọn akọtami, ka fi eyi wo ba a ṣe maa ri awọn to wa lọdọ wọn gba lai jẹ pe wọn farapa."

Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tẹ o ba gbagbe, ayajọ ọjọ ominira Naijiria, ti orilẹede yii pe ọdun mẹrindinlaadọrin ni awọn ajinigbe gbe awọn agunbanrọ to n lọ sinru ilu naa pẹlu awọn ero ọkọ mi-in wọgbo lọ.

Ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni awọn agunbanirọ naa to gbera lati ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, n rin irinajo lọ si Abia ati Akwa Ibom, fun ipagọ.

Ọkọ meji ni wọn gbe, ojiji si ni awọn to ji wọn gbe da wọn lọna loju ọna Owerri-Onitsha, lagbegbe Umunoha, ipinlẹ Imo.

Wọn ko wọn wọgbo lọ, amọ awọn dẹrẹba ọkọ wọn raye sa, awọn ni wọn si fi to awọn agbofinro to wa nitosi leti.

Awọn obi tọrọ naa kan ti ko si idaamu lati Ọjọbọ ti iṣẹlẹ yii ti waye.

Awọn ajinigbe ọhun n beere aadọta miliọnu owo itusilẹ lori ẹni kọọkan awọn ti wọn ji gbe.

Apapọ owo ti wọn n beere naa jẹ N950m.

Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Imo ti kede pe awọn ti ri eeyan mẹwaa doola lara awọn ti wọn ji gbe naa.

Bo tilẹ jẹ pe Alukoro ọlọpaa ibẹ, Henry Okoye, ko le fidi ẹ mulẹ boya lara awọn agunbanirọ naa ni awọn to ni awọn gba silẹ n ṣe.

Igbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ṣáájú àwọn agbófinró ní Imo láti wá àgùnbánirọ̀ 20 àtàwọn èrò mí-ìn tí ajínigbé gbé lọ

Lojuna ati ri awọn agunbanirọ ti iye wọn to ogun (20), atawọn ero ọkọ mi-in tawọn ajinigbe gbe lọ nipinlẹ Imo l'Ọjọbọ ọsẹ yii, Ọga agba ọlọpaa pata lorilẹede Naijiria, Olatunji Disu, ti paṣẹ fun Igbakeji rẹ to wa fun iru iṣẹ bayii, Shehu Nadada, lati lewaju nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada.

Ọga agba ọlọpaa pata paṣẹ naa ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Naijiria, CSP Anietie Iniedu, fi sita lọjọ keji oṣu Kẹwaa ọdun 2026.

Aṣẹ IGP Olatunji naa lo gbe DIG Shehu Nadada pẹlu awọn kọmiṣanna ọlọpaa meji mi-in de Imo, lati dari ọna ti wọn yoo fi ri awọn to wa ni ahamọ ajinigbe naa gba pada.

Gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa naa ṣe ṣalaye, ẹsẹkẹsẹ ti DIG Nadada ti balẹ sipinlẹ Imo lo ti de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Alukoro ọlọpaa Naijiria sọ pe bẹẹ naa ni iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati gba awọn to wa nigbekun ajinigbe naa kalẹ.

O ni DIG Nadada ti ṣagbeyẹwo ilana ti wọn fẹ fi wa awọn eeyan naa ri, ati bi wọn yoo ṣe pin awọn ti yoo ṣiṣẹ naa sibi to yẹ.

O ni eto ti n lọ lori awọn irinṣẹ ti wọn yoo lo pẹlu, ki idari too tun waye lori iṣẹ iwadii naa.

Awọn ti wọn jọ ṣe agbeyẹwo iṣẹlẹ yii bi atẹjade naa ṣe wi ni: Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo; Audu Garba Bosso ati Kọmiṣanna ọlọpaa ijọba apapọ to wa fun iṣẹ bawọnyi; Akpan Anifiok.