You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iná sọ níléèwòsàn, ọmọ ìkókó mẹ́rìnlá jóná mọ́lé
Awọn ọmọ ikoko ti wọn ṣẹṣẹ bi mẹrinla ni wọn ti jona mọle nigba ti ijamba ina kan sọ ni ile iwosan nla kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Pakistan Institute of Medical Sciences (PIMS) ni ilu Islamabaad, lorilẹede Pakistan.
Agbẹnusọ fun ileewosan naa, Dokita Aneeza Jalil ṣalaye fun BBC News pe awọn ọmọde jojolo naa wa lara awọn ọmọ marundinlogun to wa ninu wọọdu awọn ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ bi ni ile iwosan naa lasiko ti ina naa sọ.
Awọn adoola ẹmi ti ṣalaye pe eeyan mọkandinlogun ni wọn doola ẹmi wọn ninu ijamba ina naa. Mẹwaa ninu wọn jẹ obinrin, ọmọde meje ati ọkunrin meji.
Iroyin to tẹ BBC lọwọ sọ pe awọn alaṣẹ ile iwosan naa n sọ pe inu ẹrọ amuletutu ni ina naa ti kọkọ sọ, eyi ti afẹfẹ igbẹmiro oksijin ti awọn alaarẹ maa n lo nibẹ si tun ran an lọwọ lati fẹju sii.
Ohun ti minisita fun eto ilera lorilẹede Pakistan, Mustafa Kamal sọ ni wi pe awọn ọmọ ikoko to wa ninu wọọdu ti ina naa ti ṣọṣẹ julọ jẹ awọn to wa ninu irinṣẹ ti wọn n gbe awọn ọmọ kogbokogbo si (Incubator) tabi awọn ti wọn n fun ni afẹfẹ igbẹmiro ọksijin.
Gẹgẹbi alaye ti alukoro ileewosan naa ṣe fun ileeṣẹ iroyin The Dawn, dokita kan gan lo doola ẹmi ọmọ ikoko kan ṣoṣo to ye ijamba ina naa.
Nibo ni ina naa ti waye?
Ijamba ina naa bẹ silẹ ni aja kẹta ileewosan ọhun nibi ti wọọdu awọn obinrin atawọn ọmọde wa.
Ileewosan PIMS jẹ ọkan lara awọn ileewosan to tobi ju ni olu ilu orilẹede Pakistan.
Ibusun mẹrindinlọgọjọ lo wa ni ẹka ilera ọmọde ati alaboyun ni ileewosan naa gẹgẹbi alaye ti wọn fi si oju opo ayelujara wọn.
Ọdun 1885 ni wọn da ileewosan naa silẹ. Awọn akọṣẹmọṣẹ to le ni mejidinlaadọta ni wọn n ṣiṣẹ nibẹ.
ẹgbẹfa Ibusun lo wa ninu ileewosan naa fun awọn alaisan ti o si tun jẹ pe awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun marun un ni wọn lagbara lati da lohun.
Ẹkun ati ibanujẹ ọkan gbode ni ayika ileewosan naa
Ni iwaju ile iwosan nla naa, nṣe ni omije ẹkun ati ibanujẹ ọkun gba agbegbe naa kan.
Awọn ọlọpaa n mojuto iloro to wọ ile iwosan naa. Awọn ọkọ panapana naa wa kaakiri, bẹẹni awọn gilaasi ferese gbogbo to fọ naa kaakiri gbogbo ilẹ.
Awọn obi ati ẹbi ti wọn ti padanu awọn ọmọ ikoko wọn n sunkun ni apakan wọọdu nibẹ. Arakunrin kan tilẹ sọ fun BBC News pe ọmọ oun to jẹ ọmọ ọjọ mẹta pẹlu ku ninu ijamba ina naa.
Hivsa Walid wa ninu ile iwosan naapẹlu aburo iyawo rẹ obinrin to ṣẹṣẹ bimọ ki ina naa to bẹrẹ. Yara jẹleosinmi to wa ni ọgangan odikeji yara ti ina naa ti bẹrẹ ni wọn wa nigba ti ina sọ.
O ni nnkan bii agogo mẹfa owurọ ni orilẹede naa ni oun ṣa dede gbọ igbe nal, awọn kọkọ ro pe boya eeyan kan ku ni, ṣugbọn nigba ti wọn ri eefin, ni wọn sare gbe ọmọ ti wọn si sare jade.
Imọ Ijinlẹ DNA ni wọn yoo fi ṣe idanimọ awọn to jona
Awọn ọlọpaa lorilẹede Pakistan ti sọ wi pe awọn ọmọde jojolo to ku ninu ijamba ina naa jona pupọ to bẹẹ gẹẹ to fi jẹ wi pe ayẹwo igbalode DNA ni wọn yoo le fi da kaluku wọn mọ.
Wọn ni lẹyin ti wọn ba ṣe ayẹwo DNA yii tan ni wọn to le gbe oku fun ọkọọkan awọn obi wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣe alaye yii ni idahun si ipe awọn obi pe ki wọn gbe oku awọn ọmọ wọn fun wọn ni kiakia.
Ṣe lootọ ni wọn ti ilẹkun wọọdu awọn ọmọ tuntun yii pa?
Iroyin kan n jade pe boya titipa ni ilẹkun yara wọọdu awọn ọmọ tuntun naa wa to fi mu ki o di iṣoro fun didoola wọn lasiko ti ijamba ina naa ṣẹlẹ.
Amọṣa, ọga agba ilee\wosan naa, Rana Imran Sikander ṣalaye fun BBC pe rara ko ri bẹẹ. O ni kii ṣe titipa ni ilẹkun naa wa, amọ awọn fi awọn ẹṣọ sibẹ lati maa moju too.
O ni igbesẹ yii wa lati le maa daabo bo awn ọmọ ikoko to wa nibẹ ki awọn oniṣẹbi kankan ma raye rapala lọ ji wọn gbe, eleyi to ni irufẹ rẹ ti ṣẹlẹ ri lawọn ileewosan to jẹ ti ijọba lorilẹede naa.
Awọn ti aje iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori gbọdọ foju wina ofin – Aarẹ Pakistan
Aarẹ orilẹede Pakistan, Asif Zardari ti ṣalaye pe gbogbo awọn to ba nniṣe pẹlu ijamba ina naa ni wọn yoo ṣawari wọn ti wọn yoo si fi wọn jofin.
Bakan naa ni o ba awọn ti ọfọ ṣẹ ninu ijamba ina naa daro.
O ni "ibanujẹ ọkan gbaa ti adanu rẹ ko ṣee fẹnusọ" ni iku awọn ọmọ tuntun jojolo yii.