You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá ṣàwárí ilé tí wọ́n ti ń ta ọmọ ní Mowe, tú àwọn olóyún àti ọmọdé sílẹ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ẹka ti Mowe ti ṣawari ile kan ti wọn ni awọn ọmọ ọwọ ni wọn n ta nibẹ, ti awọn oloyun atawọn ọmọde si tun wa nibẹ pẹlu.
Abule Abaren, ni Mowe ni ile naa wa gẹgẹ bi DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe wi ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun.
Ohun to ṣẹlẹ gan-an
Gẹgẹ bi Babaseyi ṣe wi ninu atẹjade rẹ, ikọ kan lo wa nidii eto tita ọmọ ati bi awọn oloyun ṣe wa ninu ile naa pẹlu awọn ọmọde.
Nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ikọ ọlọpaa yabo Abule naa lẹyin ti olobo ta wọn lori ohun to n ṣẹlẹ nibẹ.
Opopona Toluwalase, Abule Abaren ti ko jinna si Gbarinmole, to jẹ awọn agbegbe ti ko si ni gbooro Mowe ni awọn ikọ naa fi ṣe ibuba bi ọlọpaa ṣe sọ.
"Lasiko ti a yabo ibẹ, a ri alaboyun meji gba silẹ, orukọ wọn ni Ilesanmi Foluke, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), ẹni to loyun oṣu meje.
"Ati Ejekwa Melody, ẹni ogun ọdun (20) ti oyun rẹ wa loṣu mẹjọ.
"Awọn ọmọde mẹrin ti wọn jẹ ọkunrin meji ati obinrin meji ni a tun ri ko kuro nile naa."
Alukoro ọlọpaa Ogun ṣalaye pe iwadii tun jẹ kawọn mọ pe obinrin kan, Blessing Bright Effiong; ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26), ṣẹṣẹ bimọ ọkunrin sile iwosan kan lagbegbe Mowe, o si jẹ ọkan lara awọn eeyan to wa nigbekun ikọ yii.
Ogunjọ oṣu Kẹjọ yii lo ni Blessin bimọ.
"Iya to bimọ ni a ri, a ko mọbi ti ọmọ ikoko to bi wa"
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Babaseyi ṣalaye pe Blessing to bimọ lawọn ri nile iwosan to n gba itọju, ibi ti ọmọ ikoko to bi wa ko ye ẹnikan.
O ni eyi lo jẹ kawọn mu nọọsi to n tọju iya, lojuna ati mọ ibi ti wọn gbe ọmọ si.
O fi kun un pe awọn yoo maa fi iṣẹlẹ naa to araalu leti bo ba ṣe n lọ.
Bakan naa ni wọn ti taari iṣẹlẹ yii si ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran, iyẹn ni Olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa ni Eleweeran, l'Abeokuta.
Bi ẹnikẹni ba ni olobo to fẹ ta ọlọpaa lori awọn eeyan ti wọn furasi pe ọwọ wọn ko mọ, awọn nọmba wọnyi ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun fi sode pe ki wọn pe:
0800 000 9111: 09164859299, 09154293464.