You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo oúnjẹ méjìlá tó ń ran iṣẹ́ ọpọlọ àti ìròrí lọ́wọ́
Pataki ni ounjẹ lara ẹda eeyan, ṣugbọn ki i ṣe ka kan maa jẹun ṣaa lai mọ irufẹ ounjẹ to daa fun ilera ọkan, ara, ọpọlọ atawọn ẹya ara yoku.
Bi ọpọlọ ṣe jẹ kókó ohun ti ẹda fi n huwa, bẹẹ naa lo tun n kopa ninu idari ohun to n ṣẹlẹ ninu ara.
Bakan naa lo jẹ pe ida ogun ninu agbara eeyan ni ọpọlọ n lo, o si ṣe pataki lati jẹ ohun ti yoo mu agbara ati alaafia naa wa.
Wayi, awọn ounjẹ kan wa to wulo pupọ fun ilera ọpọlọ eeyan, to jẹ bi wọn ṣe daa lẹnu ni wọn tun n ran irori ẹda lọwọ.
Eyi ni mejila ninu awọn ounjẹ ati ohun mimu to le mu ọpọlọ ori rẹ maa fi ojoojumọ jiire.
Ẹja Ṣáwá
Ẹja yii dara pupọ fun ilera ọpọlọ, nitori o ni eroja ti a mọ si Fatty acid to maa n mu ọpọlọ ji pepe, o si maa n din irẹwẹsi ọkan ati ki eeyan maa gbagbe nnkan ku.
Bi o ko ba fẹran ẹja yii, o le ri awọn eroja ti yoo ran ọpọlọ rẹ lọwọ dipo rẹ lara ẹwa soya, ẹwa lasan, ati ẹwa alawọ ewe. Amọ iṣẹ tiwọn ko ya bii ti ẹja Ṣawa.
Eso Chia naa daa pẹlu.
2. Ẹyin
Ẹyin ni awọn fitamin bii B6 ati B12. O ni eroja ti a n pe ni folic acid ati choline, eyi to maa n wa ninu pupa inu ẹyin.
Awọn eroja yii n ṣeranwọ fun wiwo kẹmika kan ti a mọ si "homocysteine" lulẹ.
Kẹmika yii maa n pọ si I bi eeyan ba ti n dagba ni, amọ jijẹ ẹyin yoo maa din agbara rẹ ku, yoo si din ki eeyan ni aisan rọparọsẹ tabi gbigbagbe nnkan ku pẹlu.
3. Awọn ẹya ẹpa ọlọkan-o-jọkan
Lara awọn ounjẹ to daa fun ara ati ọpọlọ ni ẹpa wa, bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ẹpa naa lo wa.
Amọ ẹpa ni Fitamin E ninu, eyi to maa n kopa pataki ninu idaboobo ọpọlọ, to si maa n din igbagbe ku.
4 Èso Elégédé
O ni eroja zinc to maa n jẹ ki igbagbe jinna si eeyan, o tun ni Magnesium to maa n din ko maa rẹ eeyan ku.
Fitamin B ati Tryptophan tun wa ninu eso elegede, to n pese eroja serotonin, amaraya gaga.
5. Awọn ounjẹ onihoro
Bii irẹsi alawọ yẹpẹ pupa (brown rice), bii ounjẹ oyinbo ti wọn n pe oat, a maa ran ọpọlọ lọwọ pẹlu eroja glucose to wa ninu wọn.
Glucose yii lo n pese agbara (energy) ti ọpọlọ nilo, o si maa n jẹ ki ara eeyan balẹ, ki eeyan si le foju si ohun to n ṣe.
6. Tíì elewe (Green tea)
Awọn tii elewe ni eroja polyphenols ninu, eyi to le din ki ọpọlọ tete dagba ku.
Mimu kọọpu meji si mẹta tii elewe lojumọ le ran ọ lọwọ ti o ko ni I maa gbagbe nnkan.
7.Kọfi (Coffe)
Eroja caffeine to wa ninu kọfi maa n wọnu ọpọlọ lati inu ẹjẹ, yoo si mu awọn iṣan inu ọpọlọ ji pepe.
8. Tomato
Tomato ni eroja Fitamin C to maa n ran iṣẹ ọpọlọ lọwọ, to si maa n din rirẹ ati ibẹru ku.
Bi eeyan ko ba ni awọn eroja yii lara to, o le jẹ ko rọrun fun eni naa lati ni arun gbigbagbe nnkan ti a mọ si Dementia ati Alzheimer.
9. Broccoli
Broccoli ni eroja Fitamin K to maa n ran ọpọlọ lọwọ, o maa n ran eroja acetylcholine to n ṣiṣẹ iranti lọwọ pẹlu.
Bakan naa ni Cabbage naa ni anfaani yii pẹlu.
10. Ewe Rosemary
Rosemary ni eroja antioxidants to n da aabo bo ọpọlọ lọwọ agba dida. Amọ iṣẹ iwadii kikun ṣi yẹ ni ṣiṣe lori rẹ lati mọ ipa to n ni lara ọpọlọ eeyan.
11. Turmeric
Turmeric ni eroja curcumin ninu,eyi to maa n ran ọgbọn ori ẹda lọwọ, o si maa n ṣiṣẹ pẹlu awọn nnkan to n gbogun ti irẹwẹsi ọkan ati ijaya.
O tun maa n ran awọn nnkan to n mu ara ya gaga lara lọwọ.
12. Ṣokoleeti dudu (Dark chocolate)
Bi eeyan ba n jẹ ṣokoleeti dudu ti a fi koko ṣe deede, o maa n ran bi ẹjẹ ṣe n lọ sinu ọpọlọ lọwọ.
O ni eroja flavanols to maa n da aabo bo ọpọlọ lọwọ, paapaa ọpọlọ awọn agbalagba.
Awọn nnkan mi-in to tun le ran ọpọlọ rẹ lọwọ ni:
Ṣiṣe ere idaraya deede
Yiyago fun siga mimu
Sisun daadaa ati
Jijẹ ounjẹ to kun fun eroja aṣaraloore.