Alága APC ìpínlẹ̀ Kogi tí agbébọn yìnbọn pa, ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko ti i mọ ibi ti wọn ti wa ti yinbọn pa alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kogi, Ishaq Yunusa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kogi, ASP Saliu Afusat lo fidi iku naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ASP Saliu fi sita lọjọ Ẹti ṣe ṣalaye, Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii ni iṣẹlẹ naa waye.

O ṣalaye pe Ishaq Yunusa ni alaga APC nijọba ibilẹ Dekina, ipinlẹ Kogi, nigba aye rẹ.

Oju ọna marosẹ Itobe–Ochadamu, ijọba ibilẹ Ofu ni wọn si ti yinbọn pa a bo ṣe sọ.

Nnkan bii aago marun -un irọlẹ ọjọ naa ni iṣẹlẹ yii waye, agbegbe kan ti wọn n pe ni Ojuwo Olijo si ni wọn pa Yunusa si.

Awọn to pa a naa ṣa deede ya jade lati inu igbo to wa nitosi, wọn si bẹrẹ si i yinbọn si awọn ọkọ to n lọ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Ọlọpaa sọ pe lẹyin tawọn agbebọn naa lọ tan ni awọn ri ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan loju ọna marosẹ naa, pẹlu awakọ rẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Ishaq Yunusa, to ti ku sinu ọkọ naa.

ASP Saliu fi kun un pe ẹnikeji ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa ni awọn agbebọn gbe wọgbo to wa nitosi ibẹ lọ.

Eyi lo ni igbesẹ ti bẹrẹ lori rẹ, bi wọn yoo ṣe ri ẹni naa gba, tọwọ yoo si tẹ awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun.

Nipa oku Alaga APC tẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa ibẹ sọ pe wọn ti gbe e lọ sileewosan Anyigba, nipinlẹ Kogi kan naa fun ayẹwo.

"A rọ awọn awakọ atawọn olugbe loju ọna yii lati fi oju ṣọri, ki wọn si tete fi ohun ifura ti wọn ba ri to ẹka aabo to yẹ leti.

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa naa wi."